Akomolede ati Asa lori BBC: Olùkọ́ Kikelomo Ogunboye tan ìmọ́lẹ̀ sí ìwà olè ọ̀gá ọlọ́pàá Audu gẹ́gẹ́ bí àwòkọ́ṣe àsìkò yìí

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa lori BBC: Olùkọ́ Kikelomo Ogunboye tan ìmalẹ̀ sí ìwà olè ọ̀gá ọlọ́pàá

Iwa ibajẹ to sọdo ni Naijiria ni Oladejo Okediji fi sakawe itan inu iwe arosọ litireṣọ toni.

Aja lo lẹru ni iwe Akagbadun ti a n ka loni lori eto Akomolede ati Asa lori BBC Yoruba.

Eto yii jẹ eyi ti BBC n ṣe pẹlu ajọṣepọ ẹgbẹ onimọ Yoruba, iyẹn YSAN ati apapọ ẹgbẹ akomolede ati Aṣa ni Naijiria.

Ipinlẹ Ondo ni olukọ wa toni ti n ṣiṣẹ ni ile ẹkọ St Monica Girls Grammar School, Ondo.

Wá kọ́ síi nípa bí àwọn gbọ́mọgbọ́mọ ṣe ń ṣiṣẹ́ láti ọwọ́ Lapade àti Tafa

Akomolede Kikelomo Ogunboye Ondo

Arabinrin Kikelomo Ogunboye onimọ nipa ede ati aṣa Yoruba dar pupọ lori eto toni.

Akọṣẹmọṣẹ Ogunboye sọ itan iwe naa ni kukuru pẹlu ipa ti awọn ẹda itan bii Lapade, Tafa Igiripa, Olopaa Audu Kareem, Gbekude, Angelina, Tola, Gbekuta, Dele, Taiwo, Jakumọ, Kola Tiamiyu ati bẹẹ bẹẹ lọ ko ninu iwe naa.

Aja lo leru

Oríṣun àwòrán, @Atawe

Awọn ẹkọ ti iwe naa kọ wa naa ni ki a fopin si iwa ijinigbe, ole jija, igbo mimu, igbo gbingbin ati tita ati bẹẹ bẹe lọ.

O tun kọ wa pe ki gbogbo awọn oṣiṣẹ to jẹ agbofinro ni ootọ inu lai ṣegbe bii olo