2023 Presidency: Adelé alága APC l'Eko ní àdéhùn wà láàrín Buhari àti Tinubu lórí ìdíje ipò ààrẹ lọ́dún 2023

Oríṣun àwòrán, Facebook/Asiwaju Bola Tinubu
Adele alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko, ọgbẹni Tunde Balogun ti ṣalaye pe aarẹ Muhammadu Buhari, Asiwaju Bola Tinubu atawọn eekan mii ninu ẹgbẹ jọ ṣe adehun lọdun 2014 pe apa iwọ oorun Gusu ni oludije fun ipo aarẹ lọdun 2023 yoo ti wa.
Ọgbẹni Balogun sọ pe ko ni boju mu ti ẹgbẹ APC ba kọ eti ikun si adehun yii.
Awọn kan ti n sọ pe awọn ogunna gbongbo ọmọ ẹgbẹ APC kan ti n gbimọ lati gba ipo adari ẹgbẹ naa ati lati bẹrẹ iṣẹ lori idibo gbogbogbo ọdun 2023.
- Èyí ni bí gómìnà Babajide SanwoOlu ti ìpínlẹ̀ Eko ṣe kó COVID-19
- Iléeṣẹ́ epo rọ̀bì ná ₦116m lórí báírò, ìwé ìkọ̀wé, àwọn aṣòfin fìka hánu
- Igbo Olodumare rèé, níbi tí Ìgbín ti tóbi ju Ìjàpá lọ
- Àádọ́ta Náírà tí báńkì ń yọ nínú owó ìpamọ́ oníbàárà kò tọ̀nà - Iléejọ́
- Agbébọn tún gbẹ̀mí àgbẹ̀ míì lọ́nà oko lágbègbè Ibarapa
- 'Ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n bọ́ mi sí ìhòhò, ó ki ìka rẹ̀ bọ ìdí mi látẹ̀yìn'
Ẹwẹ, igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu APC, NEC labẹ adari aarẹ Buhari ṣe afiku akoko ti igbimọ amuṣẹya ti Mai Mala Buni ṣagbatẹru pẹlu oṣu mẹfa sii.
Bakan naa ni igbimọ NEC buwọlu agbekalẹ igbimọ alaṣẹ to ti di tutuka tẹlẹ.
Amọ, ohun ti alaga APC ipinlẹ Eko n sọ ni pe ki awọn agbaagba to da ẹgbẹ oṣelu APC silẹ ma gbagbe adehun ọdun 2014.
''Mo mọ pe eniyan iyi lawọn aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, adehun kan ti wọn ni lo mu ki Buhari ṣoju ẹgbẹ naa ninu ibo aarẹ ọdun 2015 ati ọdun 2019,'' Ọgbẹni Balogun lo sọ bẹẹ.
O ni ṣiṣe nkan mii yatọ si adehun ọdun 2014 ko ni ṣenu 're fun ẹgbẹ APC.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Asiwaju Bola Tinubu
''Igbimọ fidihẹ to ajọ NEC ṣe agbekalẹ rẹ ko si ninu ofin ẹgbẹ oṣelu APC, ṣugbọn ọmọ ojulowo ọmọ ẹgbẹ ni mi, n ko ni fẹ tako ẹgbẹ,'' Balogun lo sọ bẹẹ.
O ni awọn kan n ja fita fita nitori ti ara wọn lati rii wi pe wọn ba ẹgbẹ oṣelu APC jẹ.
Balogun sọ pe ko si ohun to buru nibẹ ti ẹgbẹ ba gbaruku ti Tinubu nitori o jẹ ọkan lara agba oṣelu nilẹ Afirika.
Ẹwẹ, Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ to jẹ minisita akanṣe iṣẹ ati ilegbe bayii, Babatunde Fashola naa sọ laipẹ yii pe o ṣe pataki ki APC ranti adehun ọdun 2014.












