₦50 Duty Stamp: Iléẹjọ́ korò ojú sí CBN bó ṣe ń yọ owó táwọn báńkì olókoòwò fi pamọ́ sọ́dọ̀ rẹ̀

Awọn onibara banki

Oríṣun àwòrán, @cenbank

Ileẹjọ giga ilu Asaba ti kede pe ko tọna rara kawọn banki maa yọ aadọta naira lori iwe ifowopamọ ti onibara kọọkan ba kọ tabi fi ransẹ lati ori foonu wọn.

Adajọ Nnamdi Dimgba to gbe ẹjọ naa kalẹ ni aadọta naira ti wọn pe ni Stamp Duty naa jẹ owo kotọ ti onibara banki kọskan to ba fẹ fi owo pamọ n san.

Adajọ Dimgba lo kede bẹẹ lori ẹjọ kan to waye laarin olokoowo kan, Rupert Irikefe ati banki apapọ ilẹ wa, CBN pẹlu banki olokoowo Zenith ati agbẹjọro agba ni Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Irikefe lo tọ ile ẹjọ naa wa pe ko kede pe banki CBN ko lẹtọ lati maa yọ lara owo ti banki Zenith ba fi pamọ sọdọ rẹ tabi gba aadọta naira lori ẹgbẹrun kan naira bii owo sitanpu.

Banki apapọ ilẹ wa CBN

Oríṣun àwòrán, @cenbank

O ni ileẹjọ kotẹmilọrun ti kọkọ gbe idajọ kalẹ saaju pe owo naa ko tọna, to si jẹ iwa aibọwọ fun ofin fawọn banki naa lati tẹsiwaju maa yọ ninu owo toun ba fi pamọ sọdọ wọn.

Bẹẹ si ni gbogbo ẹbẹ ti banki CBN se lati mu ki ile ẹjọ wọgile igbẹjọ naa lo ja si pabo, ti adajọ si tun koro oju si ọwọ tawọn ileesẹ ijọba fi maa n mu idajọ ileẹjọ.