Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni wọ́n ti já ìbálé Esra lábẹ́ àwáwí àyẹ̀wò wúndíá

Àkọlé fídíò, Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni wọ́n ti já àbálé Esra lábẹ́ àwáwí àyẹ̀wò wúndíá

Ninu aworan yii, obinrin kan sọ iriri rẹ lori bi o ṣe la iwa ifipa ṣe ayẹwo funni lọgba ẹwọn labẹ awawi a n ṣe ayẹwo abale funni.

Bi o tilẹ jẹ pe ko si imọ sayẹnsi to gbe e lẹsẹ, o le ni ogun orilẹede ti awọn ayẹwo abale ti wọn n fipa ṣe yii ti n waye gẹgẹ bi ajọ iṣọkan agbaye ṣe sọ.

Ileeṣẹ BBC lede larubawa, BBC Arabic ba Esra, ọkan lara awọn to tii ṣe ẹwọn ri nitori ọrọ oṣelu lorilẹede Egypt sọrọ; o si ṣalaye iriri rẹ nipa ayẹwo ibale afipa ṣe lasiko to fi wa lọgba ẹwọn.

A yi orukọ rẹ pada lati daabo bo.