Adebola Ademilua: Àìrísẹ́ ṣè lẹ́yìn ìwé kíkà ló sọ mi dí ìyá onírú, mo dúpẹ́ tèmi

Àkọlé fídíò, Adebola Ademilua: Àìrísẹ́ ṣè lẹ́yìn ìwé kíkà ló sọ mi dí ìyá onírú, mo dúpẹ́ tèmi
Oniru

Àwọn ọ̀rẹ́ mi kọ́kọ́ sá fún mi nígbà ti mo bẹ̀rẹ̀ irú títà ṣùgbọ́n mo ti di ààyò ọ̀rẹ́ báyìí- Adebola

Mo gba iwe ẹri America ati UK yatọ si ti Naijiria ṣugbọn idi iru ṣiṣe ni mo pari ẹ si nitori pe ko si iṣẹ ni igboro.

Adebola Ademilua ni akẹkọgboye imọ ijinlẹ sayẹnsi to sọ iru ṣiṣe di iṣẹ oojọ rẹ to fi n pa owo wọle.

O ni oun lọ kọ iṣẹ iru ṣiṣe ni Ekiti nigba ti ko si iṣẹ lẹyin ti oun jade ile ẹkọ ni.

Lọdun 2016 ni Adebola, iya Adigun oniru bẹrẹ iṣẹ yii ṣugbọn o dupẹ pe oun ti di ẹni to n ko iru ranṣẹ si awọn ilu oyinbo bayii.

Koda, o ni oṣiṣẹ to to mejila to n ba oun ṣiṣẹ iru bayii.

Iru

Iṣẹ idọti ni Adebola pe iṣẹ iru ṣise ati pe o tun mu wahala pupọ dani ti eeyan ba fẹ ṣe iru naa daadaa.

O sọ nipa ipenija omi, ati awọn nkan miran ti oju rẹ ri lẹnu iṣẹ naa.

O ni ọjọ mẹrin gbako ni iṣẹ naa maa n gba wọn ko to di odindin.

Adebola Oniru

Adebola Ademilua gba awọn ọdọ nimọran lati wa iṣẹ ara wọn ṣe .

O ni: Ẹ ma duro de ijọba Naijiria ki o to dawọle nkan lati maa ṣe.

O tun gba wọn niyanju pe pẹlu adura ati iforiti, ohun gbogbo ni ṣiṣẹ fun ẹda.