Ganiyat tó fi irin gbígbóná àti àdá ya ara ọmọ àbúrò ọkọ rẹ ti dèrò àgọ́ ọlọ́pàá l' Ogun

Ganiyat

Oríṣun àwòrán, others

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ni iwadii ti bẹrẹ lati fi arabinrin afunrasi naa jofin.

Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ Ganiyat tó ń n fi irin gbigbona ati ada da sẹria fun un.

Ọwọ awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun ti tẹ abilekọ ẹni ogoji ọdun kan to n fi irin gbigbona ati ada da sẹria fun ọmọdekunrin ọmọ ọdun mejila kan.

ArabinrinArabinrin naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Ganiyat Ganiyu dero agọ ọlọpaa ni ọjọ Aje.

Eyi jẹ lẹyin t'awon aladugbo rẹ pariwo sita lọ si agọ ọlọpaa Adatan nilu Abẹokuta pe ọbẹ gbigbona ati ada lo fi n da batani sara ọmọ naa.

Atẹjade kan eyi ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyẹmi ni ọmọdekunrin naa daku lagọ ọlọpaa lasiko ti wọn fi gbe ẹjọ rẹ wa sibẹ.

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́

Atẹjade naa fi kun un pe ọga ọlọpaa to wa lagọ ọlọpaa Adatan lo ko awọn ọtẹlẹmuyẹ lọ si ile obinrin naa ti wọn si fi panpẹ ọba mu.

O ni arabinrin naa ṣalaye fawọn ọlọpaa pe ọmọ aburo ọkọ oun ni ọmọ naa.

Ati pe, ọmọ ọhun si ti n gbe pẹlu oun fun igba pipẹ.

O ni airi owo ẹgbẹrun marun un ti oun fi pamọ sinu ile loun fi fi iya jẹ ọmọ naa nitori pe igbagbọ oun nipe ọmọ naa lo mu u.

Kọmiṣọnna ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun, Edward Awolọwọ Ajogun ti paṣẹ pe ki wọn fa iwadii ọrọ naa si ọwọ awọn ikọ to n ṣe aayan iwa ọdaran sawọn ọmọde (anti-human trafficking and child labour unit).