Kọmísọ́nnà ètò ìdájọ́ nípìnlẹ̀ Ekiti fi ẹ̀sùn kan àwọn olóṣèlú, àti àwọn Ọba pé wọ́n ń di ìgbógunti ìfípábánilòpọ̀ lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Twitter/olawala fapohunda/kayode fayemi
Agbẹjọro Agba, to tun jẹ kọmisọnna fun eto idajọ, fun ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Olawale Fapohunda, ti fẹsun kan awọn kan ni Ekiti.
O ni awọn 'alagbara eeyan' kan naa n ṣiṣẹ tako igbesẹ ijọba ipinlẹ naa lati fi opin si ifipabanilopọ.
Eyi lo mu ki BBC kan si akọwe iroyin agba fun gomina ipinlẹ Ekiti fun alaye lati yọ kọọkundun ọrọ naa sita.
Ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ, Akọwe Iroyin Agba fun gomina ipinlẹ Ekiti, Yinka Oyebode, sọ pe gbogbo àwọn lọba lọba ni ijọba ń ba ṣe ijiroro.
O ni ijọba ti jẹ ko di mimọ fun wọn pe ẹsẹ ni lati bẹbẹ fun ẹni ti wọn ba fi ẹsun ifipabanilopọ kan.
- Orúkọ Aisha Yesufu náà wọ inú BBC 100 Women tí a fi ń sọri àwọn obìnrin tó pegedé ní 2020
- Nàìjíríà fohùn ránṣẹ́ padà sílé aṣofin UK pé ọ̀rọ̀ EndSars kò sí lẹ́nú wọn láìgbọ́ ìwádìí tán!
- Ọmọbìnrin tó tayọ nínú ìdànwó WAEC ọdún 2019 pẹ̀lú A1 méje ti kú
- Ohun mẹ́wàá pàtàkì nípa Maradona àti ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ẹlẹ́sẹ̀ ayò Diego Costa rèé
- Ganiyat tó fi irin gbígbóná àti àdá ya ara ọmọ àbúrò ọkọ rẹ ti dèrò àgọ́ ọlọ́pàá l' Ogun
Akọwe agba naa ni: "O ti di ẹsẹ bayii labẹ ofin fun ẹnikẹni, boya ẹbi, òbí, aladugbo, tabi olori ilu kankan, lati ba ẹni ti ọwọ tẹ fun ifipabanilopọ."
Ọgbẹni Oyebode ṣalaye pe ofin tuntun naa ko yọ àwọn ẹbí paapaa, to le fẹ ba ẹjọ jẹ, silẹ.
O ni eyi ribẹ nitori pe awọn eeyan kan ti wọn fi ipa ba ọmọ tabi ibatan wọn lopọ ma n lọ si agọ ọlọpaa pe awọn ko ṣe ẹjọ mọ.

Oríṣun àwòrán, @Fayemi
Alaye ti ọpọlọpọ ma n ṣe ni pe awọn ko fẹ ki orukọ ẹbi tabi ti ìlú àwọn ko ba jẹ.
Ọgbẹni sọ pe gbogbo ti ijọba ni gbogbo ẹsun ifipabanilopọ, ti ko si ni faaye gba idasi lati ọdọ ẹnikẹni.
Yatọ si eyi, o fikun pe ibudo ti wa fun ẹnikẹni ti wọn ba fi ipa balopọ nipinlẹ Ekiti, lati lọ fun itọju, idanilẹkọọ ati imọran.
Àwọn olóṣèlú, àti àwọn Ọba n gbàbọ̀dè fún ìpínlẹ̀ Ekiti lórí ọ̀rọ̀ àwọn tó n fi ipá bánilòpọ̀- Kọmísọ́nnà ètò ìdájọ́
Kọmísọ́nnà ètò ìdájọ́ nípìnlẹ̀ Ekiti fi ẹ̀sùn kan àwọn olóṣèlú, àti àwọn Ọba pé wọ́n ń di ìgbógunti ìfípábánilòpọ̀ lọ́wọ́
Agbẹjọro Agba, to tun jẹ kọmisanna fun eto idajọ, fun ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Olawale Fapohunda, ti fẹsun kan awọn kan ni Ekiti.
O ni awọn 'alagbara eeyan' kan naa n ṣiṣẹ tako igbesẹ ijọba ipinlẹ naa lati fi opin si ifipabanilopọ.
Ọlawale fi ẹsun kan pe awọn oloṣelu nla, ati awọn Ọba alaye maa n ṣaaba bẹbẹ pe ki ijọba fi awọn afipabanilopọ ti ọwọ ba tẹ silẹ.
- Ẹ wo ìṣẹ̀lẹ̀ nípa ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ tí wọ́n fi kan D'banj ní sísẹ̀-n-tẹ̀lé
- Ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé àwọn alágbara ló ń fi agbára hàn lórí arábìnrin tó fẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ kan kọmíṣọ́nà Kogi -Agbẹjọ́rò
- Ta ló fipá bá Jennifer lò pọ̀?
- Ìdí rèé tí mo fi ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n fipá bámi lopọ̀ lọ́mọ ọdún méje lọ́gọ́ta ọdún sẹ́yìn-Eli
O ni eyi si n mu ifasẹyin ba igbogun ti iru iwa bẹ ẹ nipinlẹ Ekiti.
Gẹgẹ bi iwe iroyin The Nation ṣe jabọ, ibi ipade apero kan to waye l'Ọjọru, lori Iwa ipa si awọn obinrin, nilu Ado-Ekiti, lo ti sọ ọrọ yii.
Ọgbẹni Fapohunda koro oju si bi iwa ipa si awọn obinrin, paapaa, ifipabanilopọ, ṣe n pọ si nipinlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, The Nation
Kọmiṣonna ni o buru ju ajakalẹ aarun lọ.
O ṣalaye pe ọjọ ti ọwọ ba ti tẹ afipabanilopọ tabi gbe wọn lọ sile ẹjọ, ni awọn ọba, oloṣelu, ati awọn eeyan pataki mii lawujọ, ti ma n bẹ oun lati jawọ ninu ẹsun naa.
"Lọwọlọwọ, olukọ mẹta lo n jẹjọ lọwọ.
Awọn eeyan kan ti ẹ wa, to ma n gbe awọn ọmọde yii lọ si ile itura, lati ba wọn ni ibalopọ."
O wa pada kilọ pe ko gbọdọ si pe ẹnikẹni n ba afipabanilopọ bẹbẹ mọ.
Kọmiṣonna ni "oju n ti wa, nitori bi ifipabanilopọ ṣe ti pọ si.
"Ko si si idi ti ẹnikẹni fi gbọdọ fi ipa ba eeyan lopọ."
Ọdun 2019 ni wọn pada bẹrẹ si ni ṣe amulo ofin ifipabanilopọ nipinlẹ Ekiti.
Yatọ si eyi, ipinlẹ naa tun ti ṣi iwe kan si ori ayelujara nibi to ma n fi aworan ati orukọ awọn afipabanilopọ ti ọwọ ba tẹ nipinlẹ naa.



















