Fatai Rolling Dollar: Baba 70 jayé kọjá 70 kó tó dágbére fáyé pé ó dìgbóṣe!

Oríṣun àwòrán, Google
Fatai Rolling Dollar: Baba 70 jayé kọjá 70 kó tó dágbére
Wọn kere si Number, Ori wa a dara, Saworo, Eko Akete, Baba Wa, To ba fe mo Dollar, Aduke, Feso Jaiye, Iyawo Ma pa mi...
Melo la fe ka leyin adipele.
A o lee fọwọ kọ gbogbo orin ti oloogbe ilumọọka olorin ọmọ Yoruba, Olayiwola Fatai Olagunju, Fatai Rolling Dollar tí ọpọlọpọ si mọ si Baba 70 kọ.
Wo igba ewe Fatai Rolling Doller:
Gẹgẹ bi ọmọ idile oye, wọn bi i lọdun 1927 si idile Oloye Olagunju ni Ede, ipinlẹ Oṣun.
Lọdọ awọn akẹgbẹ rẹ akẹkọọ lo ti ri alajẹ orukọ to n jẹ, nigba naa lọhun o ṣi jẹ bii ọmọ ọdun mẹsan an pere.
Eyi waye tori bo ṣe ni iwa ko ṣa a ma a ko owo shile meji ti baba rẹ maa n fun un gẹgẹ bii owo ti yoo fi ra nkan awọn aburo rẹ meji nigba ti baba wọn ba ti ṣe iṣẹ lọ si Ghana gẹgẹ bii awakọ.

Oríṣun àwòrán, Google
Owó Shile meji yii pọ ju oun ti awọn ẹlẹgbẹ rẹ maa n ni lọwọ nigba yẹn torinaa ni wọn ṣe kuku fi jẹ oye ẹni ti yoo maa yi owo ẹyọ onidẹ lasiko ti wọn ba fẹ gba eree bọọlu.
Nibo ni Fatai Rolling doller kawe de?
Ko lee lọ ileewe mọ lọdun 1944 nigba ti baba rẹ ku, lo ba bẹrẹ si ni kọ iṣẹ mọkaliiki.
Fatai Rolling Dollar gba ọna ojú omi sa lọ pelu ọkọ ojú omi kan nigba to wa lọmọ ọdun mokandinlogun.
Eyi to mu ki iya rẹ ni ki wọn ti i mọ ile ẹ̀kọ́ṣe kan nitori iwa ipanle rẹ.
Nibẹ lo ti kọ iṣẹ ọwọ tuntun nípa orin kiko sugbọn nigba to sú u, o pinnu láti bẹ̀rẹ̀ isẹ orin kíkọ.
Bawo ni Fatai Rolling Doller ṣe bẹrẹ iṣe orin gangan?
Bo ṣe bẹ̀rẹ̀ gẹgẹ bii alu ohun eelo orin ninu gbajugbaja ẹgbẹ́ olorin "Kokomba bands" ni 1940s niyii.
Nigba ti aṣọ Kokomba bands ko wọ igba mọ, lo ba bẹrẹ si ni lu ìlù "Agidigbo".

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kini o ṣẹlẹ si Rolling Doller ni ilu Eko?
Lẹyin ìgbà díẹ̀ to ṣe laalaa nilu Eko, o ri isẹ lati maa lu Agidigbo pẹlu ẹgbẹ́ "Willie Payne band" lẹ́yìn eyi to darapọ mọ ẹgbẹ́ akọrin "JO Araba band" lọdun 1953.
Ogo rẹ bá bẹ̀rẹ̀ si nii tán, o bẹ̀rẹ̀ si ni ṣeré orin lori itage fún iléese Nigeria Broadcasting Corporation.
Amosa, pupọ owó tó bá wọlé nígbà náà lọhun, ọwọ oga orin lo máa ń lọ táwọn ọmọṣe elegbe kan máa ń rí taataata.
Ìhà ti Fatai yara kọ sí eyi ni pe o bẹ̀rẹ̀ si kọ ara rẹ bí wọn ṣe ń lu ohun eèlò orin "gìtá" eyi to bẹ̀rẹ̀ lọdun 1955 pẹlu gita tí kii lo batiri tabi iná ayafi afẹ́fẹ́.
Bawo ni ẹgbẹ Fatai Rolling Doller ṣe bẹrẹ?
Fẹrẹẹ, nigba to fi di ọdun 1957, o ti da ẹgbẹ́ "Fatai Rolling Dollar & African Rhythm Band" silẹ.
Ko si pẹ rara lẹyin eyi, wọn ti bẹ̀rẹ̀ si ni ṣe àwo orín fun ilé isẹ Philips West Africa Record ti wọn si ti fi orúkọ ẹgbẹ́ rẹ silẹ láti ṣeré lọjọ òmìnira orílẹ̀èdè Naijiria lọdun 1960.
Lara awọn àgbà olorin to tun jẹ gbajugbaja to darapo mọ ẹgbẹ́ orin Fatai Rolling Dollar lọdun 1958 ni Ebenezer Obey, to di ọkan gbòógì lára àwọn Irawọ olorin Juju ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Obey padà fi ẹgbẹ́ Fatai silẹ pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ́ mẹfa míì lọdun 1963. Fatai Rolling Dollar, Ọmọ ìdílé oyè tó gbé igbá ori
Fatai Rolling Dollar: Baba 70 kú nígbà tó ku ọdún kan kó pé 70.
Wọn kere si Number, Ori wa a dara, Saworo, Eko Akete, Baba Wa, Toba fe mo Dollar, Aduke, Feso Jaiye, Iyawo Ma pa mi...
Meloo la fe ka leyin adipele. A o lee fọwọ kọ gbogbo orin ti oloogbe ilumọọka olorin ọmọ Yoruba, Olayiwola Fatai Olagunju, Fatai Rolling Dollar tí ọpọlọpọ si mọ si Baba 70 kọ.
Gẹgẹ bi ọmọ idile oye, wọn bi i lọdun 1927 si idile Oloye Olagunju ni Ede, ipinlẹ Oṣun.
Lọdọ awọn akẹgbẹ rẹ akẹkọọ lo ti ri alajẹ orukọ to n jẹ, nigba naa lọhun o ṣi jẹ bii ọmọ ọdun mẹsan an pere.
Eyi waye tori bo ṣe ni iwa ko ṣaa maa ko owo shile meji ti baba rẹ maa n fun gẹgẹ bii owo ti yoo fi ra nkan awọn aburo rẹ meji nigba ti baba wọn ba ti ṣe iṣẹ lọ si Ghana gẹgẹ bii awakọ.

Oríṣun àwòrán, Google
Owó Shile meji yii pọ ju oun ti awọn ẹlẹgbẹ rẹ maa n ni lọwọ nigba yẹn torinaa ni wọn ṣe kuku fi jẹ oye ẹni ti yoo maa yi owo ẹyọ onidẹ lasiko ti wọn ba fẹ gba eree bọọlu.
Ko lee lọ ileewe mọ lọdun 1944 nigba ti baba rẹ ku, lo ba bẹrẹ si ni kọ iṣẹ mọkaliiki.
Fatai Rolling Dollar gba ọna ojú omi sa lọ pelu ọkọ ojú omi kan nigba to wa lọmọ ọdun mokandinlogun eyi to mu ki iya rẹ ni ki wọn ti i mọ ile ẹ̀kọ́ṣe kan nitori iwa ipanle rẹ.
Nibẹ lo ti kọ iṣẹ ọwọ tuntun nípa orin kiko sugbọn nigba to sú u, o pinnu láti bẹ̀rẹ̀ isẹ orin kíkọ.
Bo ṣe bẹ̀rẹ̀ gẹgẹ bii alu ohun eelo orin ninu gbajugbaja ẹgbẹ́ olorin "Kokomba bands" ni 1940s niyii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nigba ti aṣọ Kokomba bands ko wọ igba mọ, lo ba bẹrẹ si ni lu ìlù "Agidigbo".
Lẹyin ìgbà díẹ̀ to ṣe laalaa nilu Eko, o ri isẹ lati maa lu Agidigbo pẹlu ẹgbẹ́ "Willie Payne band" lẹ́yìn eyi to darapọ mọ ẹgbẹ́ akọrin "JO Araba band" lọdun 1953.
Ogo bá bẹ̀rẹ̀ si nii tán, o bẹ̀rẹ̀ si ni ṣeré orin lori itage fún iléese Nigeria Broadcasting Corporation,
Amosa, pupọ owó tó bá wọlé nígbà náà lọhun, ọwọ oga orin lo máa ń lọ táwọn ọmọṣe elegbe kan máa ń rí taatata.
Ìhà ti Fatai yara kọ sí eyi ni pe o bẹ̀rẹ̀ si kọ ara rẹ bí wọn ṣe ń lu ohun èlò orin "jita" eyi to bẹ̀rẹ̀ lọdun 1955 pẹlu jita tí kii lo batiri tabi iná ayafi afẹ́fẹ́.
Fatai Rolling Dollar pẹlu ohun ti gbogbo eeyan fi mọ ọ jẹ gbajugbaja olorin to ma n ta jita pọ mọ orin kíkọ ó sì tun jẹ ó onímọ̀ nípa duuru ibilẹ Yoruba to ń jẹ Agidigbo.
Oun ni aye mọ ni agba ọjẹ ninu awọn orin ibilẹ ilẹ̀ Afirika (African Folk Music) ti wọn si tun mọ ọ ní ọkan ninu awọn ọba orin igbalode ni Iwọ-Oorun Afirika.
O ti kọrin débi ti oun ati ẹgbẹ orin to wa nigba naa kọ orin awọn ẹlẹmu orílẹ̀èdè Ghana si ilu highlife ti ilẹ Yoruba eyi si jẹ ẹkọ nla fáwọn ọmọ lẹyin rẹ.

Oríṣun àwòrán, Google
Fẹrẹẹ, nigba to fi di ọdun 1957, o ti da ẹgbẹ́ "Fatai Rolling Dollar & African Rhythm Band" silẹ.
Ko si pẹ rẹ, wọn ti bẹ̀rẹ̀ si ni ṣe àwo orí fun ilé isẹ Philips West Africa Record ti wọn si ti fi orúkọ ẹgbẹ́ rẹ silẹ láti ṣeré lọjọ òmìnira orílẹ̀èdè Naijiria lọdun 1960.
Lara awọn àgbà olorin to tun jẹ gbajugbaja to darapo mọ ẹgbẹ́ orin Fatai Rolling Dollar lọdun 1958 ni Ebenezer Obey, to di ọkan gbòógì lára àwọn Irawọ olorin Juju ni Naijiria.
Obey padà fi ẹgbẹ́ Fatai silẹ pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ́ mẹfa míì lọdun 1963.
Ṣùgbọ́n ẹgbẹ́ orin yìí sì ń tà wàrà wàrà títíi 1960s kanlẹ̀ amọ ti yoo fi di ipari 60s, awọn ẹ̀yà orin Juju míì tó ń jáde bẹ̀rẹ̀ si ni bo irawọ rẹ mọ́lẹ̀ nitorinaa láti rí jẹ,
O bẹ̀rẹ̀ si nii ṣòwò yiya awọn eeyan ni awọn irinṣẹ rẹ lágbègbè Moshalashi lẹgbẹ Fela Kuti Kalakuta Republic ni ilu Eko.
Ajalu inu aye Fatai Rolling doller:
Lọdun 1977, ajalu kan kọlu Fatai, o pàdánù gbogbo irinṣe to fi ń ṣòwò si ọwọ àwọn adigunjale.
Bí owó rẹ ṣe dojude, o ko lọ si ile fulaati kékeré kan, ibi gan ni àwọn iya kekeke tí bẹ̀rẹ̀ si ni gorii ńlá to gbe e sanlẹ.
Lẹyin ajalu gbogbo ohun to pàdánù, Rolling Dollar to ni ọmọ mẹẹdogun láti ọwọ obinrin mẹrin tun foju sọkún marun ninu awọn ọmọ rẹ to fi mọ àwọn iya wọn nitori ìṣẹ́ àti àìsàn.

Oríṣun àwòrán, Google
Lo ba n rọ lu oniruuru isẹ lati lee bọ ilé sugbọn lọdun 2002, gbajugbaja olorin àti adari orin Steve Rhodes, ṣàwárí rẹ o si wu u jade pada eyi to mu un bẹ̀rẹ̀ si ni ṣíṣe pẹlu Tony Allen.
Àwọn àwo orin to ṣe jáde ko to jade laye ni Fatai Rolling Dollar Returns lọdun 2010 ati Better Life ni 2011.
Nigba to ṣàìsàn láwọn ọdun yii, isẹ ti kuro ninu ọrọ rẹ to bẹẹ to fi n rìnrìn àjò lọ orílẹ̀èdè Amẹrika fun itọju. Igba naa ni wọn sagbejade aisan to ń ṣe e gẹgẹ bii aisan jẹjẹrẹ ọna ọfun.
Baa ba n sọ̀rọ̀ awọn agba olorin ni Naijiria, ara ọ̀tọ̀ ni Fatai Rolling Dollar tori ọna to ń gba kọrin tiẹ̀ yatọ gedegbe.
Kii janpata lati ta jita rẹ bo ba n kọrin lọwọ.
Ṣe ni yóò maa yọ fẹẹrẹ lọwọ rẹ bí ẹni ń fi nkan ṣeré .

Oríṣun àwòrán, Google
Èyí sì ti mu ki ọpọlọpọ wárí fun un koda tohun ti oríṣiríṣi ayẹsi àti ami ẹyẹ to ti gba lagbaye.
Lara awọn to mọ riri isẹ orin Fatai Rolling Dollar ni ile isẹ ìròyìn BBC nigba ti gbajugbaja olorin míì, Ade Bantu sọ nípa rẹ lori eto kan pe, kii ṣe pe Fatai padanu ẹ̀bùn rẹ kankan.
Ati pe, o ṣi n da awọn eniyan lara ya lori itage leyin to si ti le lọgọrin ọdun nigba naa.
Koda, aarẹ Naijiria tẹlẹ, Goodluck Jonathan gbagbọ ni tiẹ̀ pe alafo ti iku Rolling Dollar ṣi silẹ yoo nira fun ẹnikẹni lati dí. Ko si parọ

Oríṣun àwòrán, Google
Njẹ a tíì ri ẹni to ń kọrin bii tirẹ di oni?
Oun fúnra rẹ ti ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu akọroyin Will Rose ti BBC ni Naijiria, ilé isẹ iroyin AFP.
"Olórin gidi gbọdọ mọ bi wọn ṣe ń lo ohun eelo orin kan".
Fatai lórí eto naa ni o n rí òun lara bi awọn olorin kan to ya ọlẹ tí wọn a kan maa wa owo ọ̀fẹ́ kiri...
Kini o tun wa ṣẹlẹ si Fatai Rolling Doller lẹyin igba naa?
Igbe aye olóògbé Pa Fatai Rolling Dollar dabii igba teeyan n wo sinima ni.
Iyẹni, sinima eeyan ti iya jẹ titi titi ko to je eeyan laye ti ọrọ̀ rẹ tun wa poora to yi i sinu isẹ ki Ẹlẹda to faaye gba a padà nítorí fun bii ọdun mẹẹdọgbọn ni ko fi si ninu isẹ orin to bẹẹ.
Ẹwẹ, orin ti ọpọlọpọ pada fi n ranti rẹ ju naa ni eyi to kọ ko to ku, "Wọn Kere si Number" eleyii to fi ta sáwọn èwe to ba fẹ máa ruga si agba.
Kini a le sọ nipa iku Fatai Rolling Doller?
Nigba to dagbere faye, awọn iwe iroyin Naijiria kan ni lẹyin ọjọ mẹwaa lori akete aisan lo dakẹ ni ile iwosan Marritol Hospital, Surulere, Eko.
Wọn sin in ni ọjọ kẹtàlá, oṣù kẹfà, ọdun 2013 nile rẹ to wa ni Ikorodu, Eko.
Iwadii fihan pe nigba to ku, Fatai Rolling Dollar ko niwe ẹri ọjọ ti wọn bi i sugbọn pẹlu isiro ọpọlọpọ eeyan, "Baba 70" jẹ ẹni ọdun mẹrindinlaadọrun un ko to dagbere fàyè.





















