Elon Musk, Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ SpaceX, Tesla CEO ń bá Bill Gates du ipò ẹni tó lówó jùlọ ṣèkejì lágbayé

Elon

Oríṣun àwòrán, @Musk

Ipin idokoowo Musk niileeṣẹ Tesla to n ṣe ọkọ ẹlẹntiriki l'Amẹrika lo sọ di olowo nla.

Elon Musk ti goke lori atẹ awọn eeyan to lowo ju lagbaye.

Eyi fihan pe ni bi a ṣe n sọrọ yii ọga agba ileeṣẹTesla ati SpaceX naa ti di eeyan to lowojulọ lagbaye pẹlu Bill gate bayii pẹlu bi guruji rẹ ṣe tun rugọgọ sii lọjọ Aje.

Ipin idokoowo ileeṣẹ rẹ to n ṣe ọkọ to n lo ina manamana, electric automaker bu igba jẹ gidigidi.

Eyi lo si mu ki iye ọrọ rẹ ni owo dọla ilẹ Amẹrika o wọ biliọnu mẹtadilaadoje o le ($127.9).

Elon Musk

Oríṣun àwòrán, @Musk

Eyi wa gẹgẹ bi atọna awọn ọlọrọ lagbaye, Bloomberg Billionaires index, ṣe gbe iwadii rẹ kalẹ lori awọn eeyan ẹẹdẹgbẹta to lowo julọ lagbaye.

Fun ọpọlọpọ wakati ni odiwọn ọrọ rẹ gan an fi kọja ti Bill Gates.

Bill Gates ni oludasilẹ ileeṣẹ imọẹro kọmputa Microsoft ti odinwọn ọrọ tirẹ jẹ aadoje biliọnu o din ọdunrun miliọnu dọla, ($127.7)

Iwadi tuntun ti atọna awọn ọlọrọ lagbaye, Bloomberg Billionaires index, gbe jade n fidirẹ mulẹ pe biliọnu mejidinlaadoje biliọnu dọla ($128b) ni odinwọn ọrọ awọn mejeeji bayii.

Elon Musk

Oríṣun àwòrán, @Musk

Ipin idokoowo Musk ni ileesẹ Tesla lo mu ki ọrọ rẹ o ga sii.

Eyi jẹ pẹlu ida ogun ninu ọgọrun ipin idokoowo ileeṣẹ naa to jẹ tirẹ gẹgẹ bi atọna awọn ọlọrọ lagbaye, Bloomberg Billionaires index, se sọ.

Ida okooleleedegbeta ati mẹrin, (524%) ni ipin idokoowo ileeṣẹ Tesla ti fi lọ soke lọdun 2020,

Eyi to mu ki alekun ọ̀rọ̀ Musk o le pẹlu nnkan bii ọgọrun un biliọnu dọla ($100 billion)

Lootọ ọrọ Bill Gates ko ba pọ ju ọrọ rẹ lọ kani ki i ṣe ti itọrẹ aanu ti Bill Gates n ṣe kaakiri agbaye.

Bill Gates ati aya rẹ ṣeleri lọdun diẹ sẹyin lati maa lo ọgọọrọ owo to ba n wọle fun wọn lati fi ṣaanu fun awọn to ba ku diẹ kaato fun lagbaye.

Ọga agba ileeṣẹ Amazon (AMZN), Jeff Bezos ni eeyan to lowo julọ lagbaye bayii pẹlu ọrọ to to biliọnu mejilelọgọsan dọla ($182 billion).

Elon Musk

Oríṣun àwòrán, @Musk

Ta ni Elon Musk?

Orilẹede South Africa ni wọn ti bii, igba to ta oju opo isanwo ori ayelujara, Paypal fun ileeṣẹ eBay lo fi pa owo to le ni ọgọjọ biliọnu dọla ($160m)

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́

Yatọ si ileeṣẹ SpaceX, o lowo ninu idasilẹ ileeṣẹ miran bii Tesla, ileeṣẹ to n ṣe ọkọ to n lo ina ẹlẹntiriki dipo epo rọbi, Hyperloop ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ni odun mọkanla sẹyin ni wọn da ileeṣẹ Tesla silẹ, ki o to wa di gbajugbaja ileeṣe to n ṣe ọkọ ẹlẹntiriki lagbaye lọdun 2019.

Àkọlé fídíò, Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC Yorùbá: Kọ̀ síi nípa iṣẹ́ tí oúnjẹ ń ṣe lára níbí

Ma ro ara rẹ pin ni koko iroyin yii, nitori pe ko si owo lọwọ rẹ lonii ko sọ pe o ko ni di ọlọrọ lọla.

Tẹ ipa mọ iṣẹ ọwọ rẹ lai ṣe ọlẹ.

Eni to ba jale lo ba ọmọ jẹ nilẹ Yoruba.