Ìbẹta, Oba Lamidi Adeyemi, Alaafin Oyo pé ọdún méjìlá; nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa wọn nìyíì

Alaafin, Ayaba Folashade ati ibẹta rẹ

Oríṣun àwòrán, Ayaba folashade/instagram

Ọjọbọ, ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2020, ni ibẹta to wa ninu gbogbo ọmọ ti Alaafin ilu Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi Kẹta bi, pe ọdun mejila.

Ọpọ eeyan ni ko mọ pe Alaafin bi ibẹta, nitori pe ibeji ati ẹyọ kan lo wọpọ ju ninu awọn ọmọ ti baba n bi.

Eyi si maa n jẹ iyalẹnu fun ọpọlọpọ pe bawo ni Ọba Adeyemi ṣe n ṣe e, ati pe kini aṣiri ibeji rẹ.

Ọdun 2008 ni iroyin kọkọ gbale-gboko nipa apọnbeporẹ olori naa, lasiko to bi ibẹta lanti-lanti ni ọọdẹ Alaafin.

Iru eyi ko ṣẹlẹ ri ni aafin naa, nitori pe ibeji tabi ọmọ ẹyọ kan ni awọn olori maa n bi latẹyinwa.

Olori naa sọ pe, lẹyin ọdun kẹta ti oun di iyawo alaafin, l'oun to ri ọmọ bi, to si jẹ ibẹta.

O sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu iwe iroyin abẹle kan pe asiko ti oun jẹ akẹkọọ nileewe olukọni Emmanuel Alayande College of Education, ni oun bẹrẹ irinajo ifẹ pẹlu Alaafin.

Ayaba Folashade ati ibẹta rẹ

Oríṣun àwòrán, Ayaba folashade/instagram

Koda, ninu oṣu Kẹsan-an, ọdun 2020, ni wọn kọ ọ ṣori ayelujara Instagram Alaafin fun'ra rẹ pe lẹyin ti iṣẹda yọnda ibẹta fun un gẹgẹ bi akọbi ọmọ, o ti di ọkan lara awọn ayaba ti ẹsẹ wọn mulẹ patapata ninu aafin.

"O si le di iya Ọba ni ọjọ kan."

"Lẹyin Alaafin Atiba, to jẹ Alaafin akọkọ to bi ibẹta, Ayaba Aishat lo tun ni ọla bọ si ọdọ rẹ, lati jẹ ẹni to tun ṣe aṣeyọri naa.

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́

Gbogbo igba ni Olori Folashade mAa n yangan lori ayelujara pe, oun nikan ni olori to bi ibẹta fun Alaafin.

Ati pe o ṣe e ṣe ko jẹ oun nikan lo bi iru ọmọ bẸẹ ninu itan awọn ọba nilẹ Yoruba.

Nitori naa si ni ko sẹ le pa idunnu ati ayọ rẹ mọra, bi awọn ọmọ naa ṣe pe ọdun mejila loke eepẹ, ati ninu aafin baba wọn.

Alaafin ati ibẹta rẹ

Oríṣun àwòrán, Ayaba folashade/instagram

Ninu ọrọ to kọ si ori ayelujara ibaraẹnidọrẹ Instagram rẹ, Olori Folashade ṣapejuwe ibẹta ọmọ naa, gẹgẹ bi "akanṣe iyanu Ọlọrun; ibẹta kan ṣoṣo to ti i jẹ ti Adeyemi Kẹta".

Gẹgẹ bi oun ti Olori Folashade sọ, bi ibẹta ṣe ni ilọpo wahala ni ti tọju, bẹẹ naa ni wọn tun jẹ ilọpo idunnu.

O ni amuyẹ mejeeji ni awọn ibẹta oun ni.

Yatọ si eyi, niṣe ni awọn ọmọ naa jọ ara wọn bi ìmumu, to si maA n ṣoro nigba mii lati da wọn mọ yatọ.

"Amọ, eyi ko jẹ iṣoro rara, nitori pe inu rere kan naa ni ẹyin mẹtẹẹta ni."

Ayaba Folashade ati ibẹta rẹ

Oríṣun àwòrán, Ayaba folashade/instagram

Ko tan sibẹ o, Olori Folashade tun ni, ni kete ti Ẹlẹda yọnda awọn ọmọ naa fun oun, ni oun ti di obinrin ti kii sọ ireti nu.

"Ẹyin lẹ fun mi ni orukọ ọlọla."

Bakan naa lo sọ pe pẹlu ibẹta ti oun bi, ọkan oun ti fẹ ẹ balẹ.

Àkọlé fídíò, Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC Yorùbá: Kọ̀ síi nípa iṣẹ́ tí oúnjẹ ń ṣe lára níbí