Alaafin: Tí kò bá sí ìbàlẹ̀ ọkàn fún mi láàfin Oba Oyo, mi ò ní dúró síbẹ̀- ayaba Aanu Adenike Adeyemi

Oríṣun àwòrán, Instagram/queen_aanu
Aláàfin fi mí lọ́kàn balẹ̀, gbogbo ohun tí mo fẹ́ ló ń ṣe fún mi- Olori Aanuoluwapo
Akunlẹyan ladayeba, ori lẹlẹjọ. Ayaba Alaafin Oyo, Aanuoluwapo Adenike Adeyemi ṣi aṣọ loju eegun ọrọ nigba naa ti o ba BBC Yoruba sọrọ.
Ayaba Aanuoluwapo ni oun ko kabamọ lọna kankan pe Iku Baba Yeye ni oun fi ṣe ade ori oun.
O ni ori ko mọ ibi ti o n gbe eṣẹ ree, Olori Aanuoluwapo sọ pe Eleduwa nikan lo mọ nipa irin ẹda laye.
- Mi ò gbọdọ̀ má ní ìyá, kí n tún má gbádùn nílé ọkọ ni mo ṣe fẹ́ Alaafin- Olori Aanu
- Alaafin bi ibeji l‘ẹẹmeji lọsẹ kansoso
- Olorì Anu Adeyemi ń ṣe ọjọ ìbí, ẹ gbọ́ ǹkan tò sọ sí Kábíyésì
- Funke Akindele fún mi lówó tí mo fi gba ilé, kò ra ilé fún mi o - Ajirebi
- Kí ló mú Obasanjo ti ilẹ̀kùn mọ́ ẹbí, òṣìṣẹ́, ojúlùmọ̀ ní ibi òkú àna rẹ̀?
O ni lọpọ igba eeyan lero tiẹ ki Ọlọrun ni ero to yatọ fun eeyan.
Olori Aanuoluwapo ṣalaye lootọọ ni Alaafin jinna si oun tefetefe lọjọ ori, amọ o ni o ṣeeṣe ki ọdọmọbinrin fẹ ọdọkunrin ẹgbe ki o wa ṣẹlẹ pe ọdọkunrin naa ko pẹ to fi jẹ Ọlọrun nipe.
Ayaba Alaafin ni oun ko ni iya mọ, nitori oun ko tun ni fẹ fẹ ọkọ ti ọkan oun ko ni balẹ.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
O ni ọkan oun balẹ lọdọ Alaafin ati wi pe gbogbo ohun ti oun n fẹ ni Alaafin n ṣe fun oun.
Olori Aanuoluwapo ni ti ko ba rii bẹẹ ni, oun ko ni duro ti Alaafin gẹgẹ ọkan lara awọn ayaba laafin Oyo.
''Awawi asan nikan lawọn eeyan maa n gbe kiri nipa wa, amọ ni ti temi, igbesẹ mi lati fẹ Alaafin tẹmi lọrun dọba,'' Ayaba Aanuoluwapo lo sọ bẹẹ.












