Port Harcourt dumped babies: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá rí òkú ọmọ ọjọ́ kan he lórí ààtàn ní Port Harcourt

ikoko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá palẹ̀ òkú ọmọ ọjọ́ kan mọ́ lẹ́yìn t́i wọ́n jùú sórí ààtàn.

Ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Mile 1 Diobu, ni Port Harcourt, iyẹn ni ipinlẹ Rivers ti palẹ oku ọmọ ọjọ kan mọ, eyii ti ẹnikan gba ju si ile idalẹsi ni opopona Ikwerre.

Awọn eeyan to n gbe lagbegbe naa lo ke gbajare sita, lẹyin ti wọn dede ri ọmọ tuntun jojolo lori aatan ni nnkan bii aago mẹsan an aṣalẹ Ọjọru.

Nigba to n ba BBC sọrọ, Prince Wiro, lati ajọ Centre For Basic Rights And Accountability Campaign sọ pe, ọmọ ọhun ṣi wa laaye nigba ti oun foju gan ni rẹ, ṣugbọn o ti gbẹmi mi nigba ti awọn ọlọpaa yoo de ibẹ.

Wiro ni iwa to butu jai ni ẹni to ju ọmọ naa nu swa, paapaa lasiko ti ọpọ awọn lọkọ-laya kan ko ri ọmọ gbe jo.

O ni yatọ si pe iwa ọhun jẹ ohun to buru jai, o tun jẹ ohun to lodi si ẹtọ awọn ọmọ wẹwẹ labẹ ofin.

Wiro sọ pe "a maa n gba awọm ọdọbirin nimọran pe ki wọn maa lo oogun to le dena oyun."

Àkọlé fídíò, "A gbúdọ̀ wẹ̀ ọmọ tuntun pẹ̀lú epo pupa, kàìnkàìn ìbílẹ̀ àti ọṣẹ dúdú'

Wiro ni: "Ṣugbọn ti oyun ba de, a maa n sọ fun wọn ki ẉon kan si Welfare, ileeṣẹ FIDA, tabi ile awọn ọmọ alaini iya to wa ni Port Harcourt kaka ki wọn sọ odidi ọmọ nu sori aatan."

O tẹsiwaju pe ọpọ lo n wa ọmọ ti wọn ko ri to bẹẹ ti awọn kan fi n ra ọmọ lọna aitọ.

Wiro pari ọrọ rẹ pe "idi ree ti a fi n bẹ awọn ọdọ wọnyii ki wọn ye sọ ọmọ nu mọ."

Ọsẹ mẹta sẹyin ni awọn to n tu ọkọ ṣe ri oku ọmọ okunrin jojolo kan ti wọn ju sori aatan ni adugbo Elechi, ni agbegbe Diobu yii kan naa.

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́