Mí ò le nífẹ̀ẹ́ obìnrin Nàìjíríà kankan mọ lẹ́yìn ti mo ti tọ́ obìnrin òyìnbó wò- Issa

Ọmọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, Issa Sulaimon Panshekara to fẹ ẹ fẹ obinrin oyinbo ọmọ ilẹ America kan, ẹni ọdun mẹrindinlaadọta, Janine Sanchez la fọrọ wa lẹnu wo.
Issa ti sọ fun BBC ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pe oun ko le fẹran ọmọ Naijiria kankan mọ laye oun lẹyin nkan ti oun ti tọwo Òyìnbó ẹni ọdún 46 wá ṣe mọ̀'mí n mọ̀ ọ́ ní Kano pẹ̀lú Isah olólùfẹ́ rẹ̀.
Issa ni: "Otitọ to wa ninu ọrọ yii ni pe awọn obinrin wa ko mọ nkankan nipa ifẹ otitọ rara.
Ninu ki wọn o maa ranju mọ eeyan nkankan, tabi ki wọn o ni erongba ti ko dara.
Ṣugbọn ti obinrin oyinbo ba sọ fun ọ pe oun nifẹ rẹ, ṣe ki n ma tan yin, ati isalẹ ọkan rẹ lo ti wa."
Ọmọkunrin naa to jẹ gẹri-gẹri nigba kan sọ pe ẹru ba oun diẹ lẹyin ti awọn ọlọpaa Sharia, Hisbah, ati ajọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ DSS pe e si ọọfisi wọn.
Ṣugbọn, imọran lasan ni wọn fun oun nitori bi iroyin ṣe n gbe ọrọ rẹ lọtun, ati l'osi.
Oju opo ayelujara Instagram ni awọn ololufẹ mejeeji ti kọkọ pade ni bi ọdun kan sẹyin.
Issa ni: "A pade lẹyin ti mo bẹrẹ si ni 'tẹle e' lori Instagram, to ba si fi aworan kankan si oju opo naa, maa fi ifẹ han si.
Ko pẹ pupọ ni mo ri i pe awọn ọmọ 'yahoo-yahoo' kan n gbiyanju lati lu u ni jibiti, ni mo ba ya a fi ọrọ ranṣẹ si i pe ko ma ṣe da awọn Yahoo boys yẹn l'ohun o, iyẹn lo fa a l'oju mọra.
Eyi lo si fi mọ pe olododo eniyan ni mo jẹ.
"Lati igba yẹn lati bẹrẹ si ni fi ọrọ ranṣẹ si ara wa daada, koda a maa n pe ipe oni fidio. Gbogbo nakn naa lo gbe wa de ibi ti a de l'oni.
Lori pe boya wọn ti jọ sun si inu 'yara kan naa lati igba to ti de si Kano ni ọjọ mẹfa sẹyin; "A o jọ sun si 'yara kan naa o.
Mo maa n duro ti i di alẹ ki n to sọ fun un pe o daarọ.
Koda, awọn eniyan n sọrọ si awọn nkan keekeeke bi ka di mọ ara wa diẹ, ati ka di ara wa lọwọ mu, ka to wa sọ pe ka jọ sun papọ."
Issa sọ pe mọlẹbi oun ti fi ara mọ pe ki oun fẹ Janine, ati wi pe igbeyawo yoo waye ti yoo ba fi di oṣu Kẹta ọdun.
Lẹyin naa si ni oun ati iyawo oun yoo maa lọ si America.
"Lẹyin ti a ba ti ṣe ayẹyẹ igbeyawo wa ninu oṣu Kẹta, ilẹ America ya niyẹn o.
Ibẹ si ni maa ti maa ṣe iṣẹ, pada sileewe, nitori pe ileewe girama ni mo kawe de."
Mo si tun ni igbagbọ pe maa ri ẹgbẹ agbabọọlu ti maa ma gba bọọlu fun."
Ninu ọrọ tiẹ, Jamine sọ pe igba akọkọ niyi ti oun wa si ilẹ Africa, inu oun si dun si bi awọn eniyan ṣe n tọju rẹ.

O sọ pe o dun mọ oun ninu pe Isa ti gba lati fẹ oun.
" Mo ti mọ awọn mọlẹbi Issa to le ni ọgọrun un, inu mi si dun pe gbogbo wọn lo faramọ pe ki a fẹ ara wa.
Ọpọlọpọ wọn ko ti i ri obinrin oyinbo ri, niṣe ni wọn n fi irun ori mi ṣere, ti wọn a tun maa fi ọwọ kan ọwọ mi."
Oyinbo naa to jẹ alase n ṣiṣẹ nile ounjẹ orilẹ-ede Afghanistan kan nilu California, sọ pe oṣu to n bọ ni oun yoo pada si America, ki oun tun to o pada wa ni oṣu Kẹta fun igbeyawo naa.
"Mo n pada lọ ni oṣu to n bọ, maa si pada wa ni oṣu Kẹta fun ayẹyẹ igbeyawo wa, ki emi ati ọkọ mi to maa lọ si America."
Lopin gbogbo ọrọ, Isa sọ pe irinajo ifẹ oun ati Janine jẹ ẹri pe ifẹ otitọ ṣi wa lori ayelujara, ti yoo si dara ti awọn eniyan ba 'gbiyanju aje' wo.
















