Ẹ̀yin ẹ máà wò ó, ó ṣeéṣe kí APC túká lẹ́yìn ìṣèjọ́ba Buhari!

Oríṣun àwòrán, @kfayemi
Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi ni o ṣeeṣe ki a ma ko firi iwalaaye ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nigba ti saa aarẹ Buhari yoo fi pari.
Fayemi sọ eyi gẹgẹ bi esi si iroyin kan to n tan ka pe awọn ọmọ ẹgbẹ kan fẹ yọ Adams Oshiomole loye gẹgẹ bii alaga APC.
O ni ọrọ ti ko to nkan to ṣẹlẹ laarin awọn gomina kan ati Oshiomole ni wọn n sọ di babara.
Bi ẹ ko ba gbagbe ninu oṣu kẹrinla ọdun to kọja, awọn igun kan ninu ẹgbẹ naa to wa lẹyin gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki jawe lọ simi nile fun Oshiomole eyi ti wọn pohun pọ ṣe.
Ẹwẹ, Fayemi ni awọn gomina kan yii naa wulo fun bi Oshiomole ṣe di alaga, wọn kan n fẹ ibọwọ tiwọn ni gẹgẹ bi adari ẹgbẹ ki wọn si maa gba ọrọ wọn yẹwo.
"Mo lero wi pe a n tẹsiwaju o ṣugbọn bayii kọ lo ṣe yẹ ko ri. Ẹ o ri i pe ijọba gan ko ja iyan rẹ". Fayemi sọ bẹẹ.
O ni " a n gbe ẹsẹ meji siwaju, mẹwaa sẹyin. Mo lero wi pe awa funra wa ni iṣẹ lati ṣe lati mọ bi a ṣe nilo nkan wọnyi si.
Nigba to n sọrọ lori ifilọlẹ ikọ Amọtẹkun o ni ohun taa nilo ni Amotekun jẹ lati fi kun akitiyan awọn ọlọpaa to ti wa latọjọ yii.
"Koda bi ọlọpaa ba ṣa gbogbo ipa wọn, a ṣi n ni ipenija. Eyi si lo fa sababi pe a nilo aabo abẹle."
Fayemi ni oun to yẹ ka maa sọrọ rẹ ni bi a ṣe lee ri i daju pe awọn ikọ alaabo n ṣe iṣẹ wọ laarin alakalẹ ijọba awa ara wa.
- Ìríwísí àwọn aráàlú bí EFCC ṣe kó afurasí ọmọ yahoo 49 ní Ibadan
- Ọmọ ọdún mẹ́wàá ń jẹ ìrora lẹ́yìn tí ọ̀gá tì í sínú iná àrò búrẹ́dì
- Ọmọ ọdún márùn-ún, àgbà mẹ́rin ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀pá bẹntiróò tó gbiná ní Abule Egba lọ - LASEMA
- Lalong, Tambuwal, Ganduje ni ilé ẹjọ́ gíga jùlọ kéde bíi gómìnà ìpínlẹ̀ wọn














