Lesbianism: Àwọn ará South-Africa yarí 'torí gbọ̀ngàn kọ̀ ìgbéyàwó abo-sábo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ọmọ ilẹ South-Africa kan ti kọ jalẹ lẹyin ti ile igbafẹ kọ lati fun wọn ni gbọngan igbalejo wọn lati fi ṣe iyawo abo si abo.
Ẹgbẹ ile ijọsin kan, Freedom of Religion South Africa ni gidigba ni awọn wa lẹyin ile igbafẹ Beloftebos to kọ jalẹ fun awọn ololufẹ naa lati lo ile igbafẹ wọn.
Awọn ololufẹ naa Megan Watling ati Sasha-Lee Heekes ni ọgbẹ ọkan ni gbọngan naa da silẹ fun awọn.
Ọkan lara awọn obinrin naa ni wi pe awọn ti bere boya awọn lee lo gbọngan naa lati Osu Kẹrin, ọdun to kọja, ti wọn ṣẹṣẹ wa da wọn lohun ni ọṣẹ ọjọ igbeyawo wọn.
Wọn fi lede wi pe oju opo ayelujara gbọngan naa ni wọn ṣẹṣẹ mọ wi pe wọn ko faramọ igbeyawo akọ si akọ tabi abo si abo.
Awọn ti wọn n ṣe atilẹyin fun awọn obinrin meji naa ti bẹrẹ iwe ipẹjọ fun ajọ to n ri si ẹtọ awọn ọmọ ilẹ South Africa lati ri si iṣẹlẹ naa.
Orilẹ-ede South Africa lo kọkọ sọ ni ilẹ adulawọ pe o ba ofin mu ki akọ fẹ akọ tabi ki abo fẹ abo.











