Harry and Meghan: Mí o ṣààdédé gbé ìgbésẹ̀ láti kúrò nílé Ọba

Aworan ọmọọba Harry

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọmọba Harry fi ọrọ yi lede nibi apejẹ kan to kopa nibẹ lọjọ Aiku

Ọmọọba ilẹ Gẹẹsi ti o si tun jẹ "Duke ti Sussex" ti sọ pe igbagbọ loun fi gbe igbẹsẹ lati yẹra kuro nile ọba nitori ko si nkan mii ti oun le ṣe.

Nibi apejẹ kan ti oun ati iyawo rẹ Meghan kopa nibẹ nirọlẹ ọjọ Aiku ni o ti sọ pe o wu awọn lati maa ṣiṣẹ sin yeye Ọba lai gba owo ṣugbọn ''ko le ṣeeṣe''

Eyi ni igba akọkọ ti yoo sọrọ nita gbangba lori ọrọ yii lati igba ti oun ati iyawo rẹ Meghan ti kede pe awọn fẹ yẹra kuro nile ọba.

Ọmọọba naa ni oun ri ayọ ati idunnu ti oun ti n wa pẹlu Meghan ṣugbọn oun fẹ ki o ye awọn eeyan pe awọn ko lọ lai wẹyin wo.

''Ile ni ilẹ Gẹẹsi jẹ fun mi, ko si oun ti yoo si yi i pada''

Aworan ọmọọba Harry ati ọmọ rẹ Archie

Oríṣun àwòrán, PA Media

Àkọlé àwòrán, Harry, iyawo rẹ ati ọmọ rẹ Archie ni Victoria lasiko ọdun Keresimesi to kọja

Harry sọ pe ohun to n ṣẹlẹ n ṣafihan iru bi nkan ko ṣe rọrun fun oun eleyi to mu ki oun fi mọlẹbi oun pamọ lati le gbe igbe aye alaafia.

Nibẹrẹ oṣu yii ni ọmọọba Harry ati Meghan sọ pe awọn fẹ yẹra kuro nipo gẹgẹ bi aṣaaju mọlẹbi ọlọba ilẹ Gẹẹsi tawọn si fẹ́ da duro funra awọn.

Lọjọ Abamẹta ni ikede wa lati aafin Buckingham Palace pe wọn o ni maa lo oye ọlọmọọba wọn mọ ti wọn ko si ni kopa ninu awọn iṣẹ to jọ mọ jíjẹ́ ọmọ ọba.

Wòó nínú àwòrán: ìgbé ayé Harry àti Meghan ṣáájú ìyapa kúrò nílé Ọba

Ọmọọba Harry ati aya rẹ ti a mọ si Duke ati Duchess Sussex lẹyin igbeyawo wọn ni wọn ko ni lo orukọ oye ile ọla to jẹ ile Ọba UK mọ.

Koda, wọn ko ni fọwọ kan owo ilu mọ ni ile Ọba ni Buckingham.

Bakan naa ni wọn pinnu lati da miliọnu meji ati irinwo pọun ile UK ti ile Ọba fi ba wọn tun ile Cottage ti wọn n gbe lẹyin igbeyawo wọn ṣe pada Harry àti Meghan kò ní lo orúkọ oyè wọn mọ́, wọn kò sì lẹ́tọ̀ọ́ sí owó ilú mọ́ ní UK.

Owó ara wọn ni wọn yoo maa na pẹlu ileri lati ma doju ti Ọbabinrin ninu iwa ati iṣe wọn nibikibi ti wọn ba wa.

harry

Oríṣun àwòrán, PA Media

Àkọlé àwòrán, Lódun 2016 ni aafin Kessingtin fi atẹjade sita lati fidiẹ mulẹ pe lootọ ni Ọmọọba Harry ati oṣere binrin Meghan Markle ti n fẹ ara wọn lati oṣu diẹ sẹyin. Toronto ni wọn ti kọkọ fi aworan wọn ti wọn jọ ya papo sita.
harry

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ni kete ti wọn ṣe ikede ipinnu wọn lati fẹ ara wọn titi lae ni Meghan sọ fun BBC pe ọna ara to yanilẹnu, to mu ife dani, to tun dùn leti to wa tuni lara ni Harry gba dẹnu ifẹ kọ oun.
harry

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Losu keji ọdun 2018, ni awọn tọkọtaya naa kopa ninu eto itagbangba pẹlu ẹgbọn rẹ Duke ati Duchess Cambridge. Nibẹ ni Meghan ti darapọ mọ ẹbi alayọ yii lati kopa ninu eto Royal Foundation Charity. Nibi eto yii ni Harry ti ṣe yẹyẹ pe Awọn mẹrẹẹrin a jọ wa pọ laelae ni.
harry

Oríṣun àwòrán, PA

Àkọlé àwòrán, Lọjọ kọkandinlogun, oṣu karun un, ọdun 2018 ni wọn so awọn mejeeji pọ ni Windsor Castle. ero to le ni igba le ni ẹgbẹrun kan ni wọn fiwe pe sibi igbeyawo naa ti wọn si ṣafihan rẹ kaakiri awọn amohunmaworan ni UK. Ori ẹṣin ni tọkọtaya yii gun fi ki awọn ara ilu pe wọn ku aduroti lẹyin igbeyawo naa.
harry

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, O le ni ẹgbẹlẹgbẹ ero to to si oju opopona lati wa ki awọn t\ọkọtaya tuntun ti yoo maa ṣakoso Susex ni UK.
harry

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ile ijọsin St George Chapel ni tọkọtaya Harry ati Meghan ti jẹ ẹjẹ ootọ inu sira wọn titi iku yoo fi ya wọn niwaju Obabinrin ati ero to pọ pẹlu ayọ
Àkọlé fídíò, Wo àwọn ìbejì tó lẹ́ pọ̀ lẹ́yìn àṣeyọrí ìṣẹ́ abẹ dókìtà 70
harry

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Obabinrin Elizabeth, Duke ti Edinburgh ati awọn eekan mi ninu ile Ọba ni gbogbo wọn fi ayọ han nibi eto igbeyawo Harry ati Meghan pe o ṣoju wọn.Inu Ọbabinrin ati ọkọ rẹ dun pupọ lati ri ọmọmọ wọn ko gbe iyawo to wuu wọnu ile ọla loju aye wọn.
harry

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Loṣu kẹfa, ọdun 2018 ni Obabinrin Elizabeth ati Olori Meghan kọkọ jọ fojuhan papọ nita. Awọn mejeeji jọ ṣi Gateway Bridge and Chester's Storyhouse Theatre nilu Ọba. Opọ ni ile Ọba ti t\wọ gab Meghan wọle lẹyin eto yii.
Àkọlé fídíò, Títí d'òní, Bàbá mi dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ ológun kò sí padà wálé - Grandma Biafra
harry

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lasiko ọyẹ ni ilé Ọba ni Kessington fi sita pe Meghan ti fẹraku ati pe wọn ko ni pẹ bi \omọọmọọmọ miran fun Ọbabinrin Elizabeth. Kete leyin ikede yii ni Harry ati Meghan bẹrẹ irinajo akọkọ wọn lọ silẹ okeere. Wọn lọ si Australia, New Zealand, Fiji ati Tonga papọ. Eyi ni ọkan lara awọran ti wọn ya ni Bondi Beach ni Sydney ni \Australia pẹlu awọn ololufẹ wọn.
harry

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lọjọ kẹfa, oṣu karun un, ọdun 2019, ọdun kan lẹyin igbeyawo wọn ni Meghan bi ọmọkunrin lantilanti sinu ile Ọba. Archie Harrison Mountbatten Windsor ni wọn sọ orukọ ọmọ tuntun o. Oun ni ẹni keje si itẹ Ọba ilẹ Gẹẹsi lẹyin Obabinrin elizabeth. Harry fi idunnu rẹ fawọn akọroyin pe iriri naa ti dara ju lati di baba ikoko.
harry

Oríṣun àwòrán, PA Media

Àkọlé àwòrán, Loṣu kẹfa ọdun 2019 ni tọkọtaya yii ni awọn ko ṣe iṣẹ iranlọwọ papọ mọ pẹlu Duke ati Duschess Cambridge to jẹ égbọn Harry ati aya rẹ. Wọn ni awọn fẹ bẹr ti ara awọn lọtọ
Àkọlé fídíò, Super touch: Roller Blader ni mí láti ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn
harry

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Lọdun to kọja ni Archie omọ tuntun ti abi kọkọ rinrin ajo lọ silẹ Adulawọ. Wọn gbe e lọ ki Archbishop Desmond Tutu ni orilẹ-ede South Africa lasiko abẹwo wọn akọkọ gẹgẹ bii ẹbi kan.
harry

Oríṣun àwòrán, PA Media

Àkọlé àwòrán, Omọọba Harry ati ọmọ rẹ Archie ni Canada ti wọn kede lati maa gbe lasiko yii
Àkọlé fídíò, Wo àwọn ìbejì tó lẹ́ pọ̀ lẹ́yìn àṣeyọrí ìṣẹ́ abẹ dókìtà 70
harry

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Aworan yii ni tọkọtaya Harry ati Meghan ya nile wọn ni Canada ṣaaju bibeere fun iyọkuro ninu iṣẹ ile Ọba ni eyit i Ọbabinrin Elizabeth ti tu wọn silẹ bayii pe o dabọ. Ile Ọba ni Haary ati Meghan ko ni maa lo orukọ oye wọn ati pe wọn ko ni maa na ninu owo ile Ọba mọ

Gbogbo aworan yii lo ni awọn to ni wọn bi a ṣe darukọ wọn.