Orthodox Christians Epiphany: Àwọn krìstíẹ́ní yìí n wẹ̀ nínú omi tútù fún àjọyọ̀ ìrìbọmi Jesu

Awọn olujọsin kaakiri Russia ati Ila oorun Yuroopu ti n 'jare ọyẹ' pẹlu bi wn ṣe n wẹ ninu odo ti omi rẹ ni yìnyín, fun ajọyọ ifihan Jesu (Epiphany).

Ọkan pataki ni lara awọn ọjọ isinmi ninu kalẹnda awọn kristiẹni igbagbọ atijọ.

Ajọyọ naa to maa n waye ni ọjọkọkandinlogun, oṣu Kinni, maa n wa fun iranti iribọmi Jesu, ninu odo Jọdaani.

Presentational white space
Alufaa kan n ṣe eto iyasọtọ fun olujọsin kan.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Lati ṣe ajọyọ ọjọ naa, ọpọlọpọ awọn Kristiẹni igbagbọ atijọ (orthodox) maa n ri ara a wọn sinu iho omi tutu.

Wọn le ki ara wọn sinu omi lẹẹmẹta lati bu ọla fun Mẹta-lọkan.

Alufaa ijọ igbagbọ atijọ kan n ya omi si mimọ ni Svyatoye lẹyin odi ilu Moscow ni Russia.

Oríṣun àwòrán, AFP

Igbagbọ wọn ni pe aṣa naa maa n mu ilera pipe wa fun awọn olujọsin, to si tun maa n wẹ ẹṣẹ wọn danu.

Ninu aworan oke yii, alufaa ijọ igbagbọ atijọ kan n ya omi si mimọ ni Svyatoye, to wa ni ẹyin odi olu ilu orilẹ-ede Russia, Moscow.

Àkọlé fídíò, Wo bi awọn alamojuto eto ṣe n pese iho yìnyín silẹ fun ajọyọ naa

Awọn olujọsin gbagbọ wi pe gbogbo omi maa n di mimọ ni ayajọ ifihan Jesu (Epiphany).

Awọn kan ti lẹ ro pe omi to tutu daadaa pẹlu yìnyín ni anfaani fun ilera.

Presentational white space
Ọkunrin kan n wẹ ninu odo adagun kan.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn onigbagbọ ijọ atijọ n bẹ sinu omi tutu oniyinyin ninu odo Sava, ni Belgrade.

Oríṣun àwòrán, AFP

Awọn olujọsin ijọ igbagbọ atijọ n bẹ sinu omi tutu oníyìnyín odo Sava nilu Belgrade.

Obinrin kan wọ inu omi lasiko ajọyọ ifihan Jesu ni Omsk

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ninu aworan yii, obinrin kan n wọ inu omi nilu Omsk, l'orilẹ-ede Russia, nibi ti otutu ti n gba yayaaya lasiko yii.

Russia Ẹlẹwọn kan n ki ara rẹ bọ odo nilu Omsk.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn to n ṣọ ẹlẹwọn n wo bi ẹlẹwọn kan ṣe n ri ara rẹ bọ omi ni ọgba ẹwọn alagbara kan to wa ni Omsk.

Awọn onigbagbọ ijọ atijọ ni Serbia n ya aworan

Oríṣun àwòrán, AFP

Awọn olujọsin korajọpọ lati ya aworan lẹyin ti wọn ti luwẹ tan ninu odo Sava, to wa ni ilu Belgrade.

Gbogbo aworan ti a lo lo ni orisun to ti wa.

Àkọlé fídíò, Super touch: Roller Blader ni mí láti ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn