Ọmọwe Lekan Are jáde láyé lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínláàdarún

Lekan Arẹ

Oríṣun àwòrán, others

Alagba Lalekan Ayọkunnu ti ọpọ mọ si Lekan Arẹ ti jade laye

Ẹni ọdun mẹrindinlaadọrun ni Ọmọwe Arẹ ko to di ara ilẹ ni ọsan Satide, ọjọ kejidinlogun, ọdun 2020 lẹyin aisan ranpẹ nileewosan nla UCH ni Ibadan.

Eekan ọmọ ilu Ibadan ni oloogbe Arẹ. O si di ipo nlanla mu lawujọ ninu eyi ti ipo ọmọ igbimọ adari ileeṣẹ iwe iroyin Punch wa.

Bakan naa ni o jẹ oludari agba fun ileeṣẹ Kakanfo Inn ati oko nla ti Lekan Arẹ farms.

Àkọlé fídíò, O leè má mọ̀ bóyá o ní àrùn HIV/AIDS o! Wo àwárí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ yìí

Nigba aye rẹ, pataki laarin awọn onimọ ijinlẹ nipa eto ọgbin ni alagba Arẹ.

Ni ọdun 1933 ni wọn bi oloogbe Ọmọwe Lalekan Arẹ.

Titi di igba to wọ kaa ilẹ sun, Lalekan Arẹ ni Laguna Bọbajiroro ilu Ibadan

Àkọlé fídíò, Bakare Mubarak: ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ dúró sí ẹgbẹ́ mí tójú si máa n tì mí