Funke Akindele Marriage: Ṣé lóòtọ́ ni ìgbeyàwó Funke Akindele ti dẹnukọlẹ̀?

Funke Akindele ati ọkọ rẹ, Abdul Rasheed Bello

Oríṣun àwòrán, funke Akindele/instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lati ọjọ diẹ sẹyin ni awuyewuye ti n lọ lori ayélujára pe, igbeyawo gbajúgbajà oṣerebinrin, Funke Akindele-Bello, ati ọkọ rẹ Abdulraheed Bello (JJC Skillz) ti tuka.

Iroyin naa, ti BBC ko le fi idi rẹ mulẹ, sọ pe Funke fi ẹsun kan ọkọ rẹ pe o n na owo ileeṣẹ ti wọn jọ ni, ni inakuna lai sọ fun oun, eyi to fa ariyanjiyan.

Bakan naa la gbọ pe ọrọ naa ni agbara debi pe Funke le Abdulraheed kuro nile wọn to wa ni Amen Estate, nilu Eko.

Iroyin naa ti ẹ tun sọ pe Ọgbẹni Bello fi oow naa gba ile kan sílú Eko, nibi ti awọn ọmọ rẹ agba yoo ma a de si ti wọn ba wa silu Eko.

Ọdun 2016 ni tọkọtaya naa ṣe igbeyawo wọn nilu London.

Àkọlé fídíò, Abisola Odebode: Ẹ wo àkàndá ẹ̀dá tó ń kọ́ àwọn àgùnbánirọ̀ l‘Osun ní ọ̀dà ṣíṣe lọ́fẹ̀ẹ́

Ọmọ JJC Skillz fi awọn ẹsun gbankọgbi kan Funke Akindele:

Iroyin kan to jade sori ayelujara sọ pe ọkan lara awọn ọmọ JJC tii se ọkọ Funke Akindele, Benito, kọ awọn ọrọ kòbákùngbé nipa iyawo baba rẹ sori ayélujára TikTok.

"O ni Funke kii ṣe iru eeyan ti gbogbo aye ro pe o jẹ.

"O ṣalaye pe ọdun meji gbako ni oun fi gbe nile wọn (ti baba rẹ ati Funkẹ n gbe nilu Eko), to si sọ pe ile ibẹru ati ijaya gba a ni."

O sọ awọn ọrọ yii gẹgẹ bi esi si ọrọ̀ kan ti agbohunsafẹfẹ ori ayélujára kan, Tosin Silverdam fi sita nipa Funke Akindele, wi pe wahala n waye ninu igbeyawo rẹ.

A gbiyanju lati wa ọrọ naa labẹiroyin ọhun lori TikTok, amọ o dabi ẹni pe Benito ti pa a rẹ.

Eyi to ṣe e ṣe ko ribẹ nitori awuyewuye to tẹle ọrọ rẹ.

Ṣugbọn 'sa, adura ti ọpọ awọn ololufẹ tọkọtaya naa n gba fun wọn ni pe ki igbeyawo wọn ma tuka bi iroyin ṣe n sọ.

Ọrọ ti ọmọ ọkọ Funke Akindele kọ si TikTok

Oríṣun àwòrán, _tosinsilverdam

Awọn ami miran to ṣeeṣe ko mu ki aye ma a sọ pe igbeyawo Funke Akindele ti daru:

Ni ọjọ ti JJC Skillz ṣe ọjọ ibi, aworan oriṣi kan naa meji, ni Funke fi ki ku oriire ọjọ ibi.

Bakan naa ni ọrọ to kọ si abẹ aworan naa lori Instagram rẹ ko pọ rara.

Eyi to yatọ patapata si bo sẹ ma n ṣe tẹlẹ.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Ṣaaju asiko yii, ọpọlọpọ aworan JJC, eyi ti wọn jọ ya papọ, ati awọn fídíò loriṣiirṣi (photo shoot) ni Funke fi ma n ki ọkọ rẹ ni ọjọ ibi rẹ.

Bakan naa lo ma n kọ oriṣiriṣi awọn ọrọ ifẹ, adura, ati ikini ki ọkọ rẹ fun ọjọ ibi.

Koda, ọjọ bii meji si mẹta lo ti ma n fọnrere ọjọ ibi ọkọ rẹ tẹlẹ.

Nkan miran ti a tun ṣe akiyesi ni pe lọwọlọwọ, JJC Skillz wa nilu London.

Ilu London lo n gbe ṣaaju igbeyawo rẹ pẹlu Funke, nibi ti awọn ọmọ mẹta to ti kọkọ̀ bi wa.

Àkọlé fídíò, Jimi Solanke: Bí a ṣe bẹ̀rẹ̀ eré òṣùpá láyé àtijọ́ táa mú ìtàn Yorùbá sísọ dé America padà

Wo ohun ti JJC, ọkọ Funke Akindele kọ soju opo Instagram rẹ bo se de London ti aye fi n ni oun ati Funke Akindele ti pinya:

Ninu ọrọ to kọ soju opo ayélujára Instagram rẹ lẹyin to de si ilu London, o ni "ko sibi to da bi ile.

Asiko ti to lati ṣe awọn ayipada ati atunto to l'agbara. Iwaju ni ma a ma lọ, mi o ni rẹyin lailai.

Bo tilẹ jẹ pe tọkọtaya naa ko sọrọ lori boya igbeyawo wọn n la wahala kọja, JJC Skillz fi ọrọ kan sita ni irọlẹ ọjọ Aje.

Ọrọ naa lo kọ si abẹ aworan kan to fi sita.

Ninu aworan naa lo wa pẹlu Funke ati awọn ọmọ wọn to jẹ ibeji.

O kọ akori si abẹ aworan naa pe idile nikan ni apata ti oun mọ to ma n duro pẹ titi.

"Ilu London n dun lọwọ, ṣugbọn aaro ile n sọ mi."

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Ibi yii lo kọ ọrọ naa de to fi darukọ iyawo rẹ pe "Funke Akindele, ifẹ mi, gbadun asiko yii pẹlu awọn ọmọ̀ ọmọ. Maa a ri yin nile laipẹ.

Lẹyin naa lo fi awọn 'hashtags' si pe irọ ni eṣu n pa, ofo ni ọrọ ẹyin, Bello titi lai.

Àkọlé fídíò, Olaiya Igwe ló wá ra epo níbi tí mo ti ń di "nussle" epo mú mo bá bẹ́ mọ́ ọ́, bí ayé mi ṣe yí padà di òṣèré fíìmù rèé

Nkan to yẹ ki o mọ nipa Funke Akindele-Bello:

Oṣu Kẹjọ, ọdun 1977 ni wọn bi Funke Akindele-Bello ni ilu Ikorodu, nipinlẹ Eko.

O kawe gboye ninu imọ ofin ni Fasiti Unilag.

Akindele di gbajumọ osẹre lasiko to kopa ninu ere kan ti ajọ United Nations ṣe onigbọwọ rẹ, 'I need to Know', laarin ọdun 1998 si 2002.

Ọpọlọpọ fiimu lo ti ṣe gẹgẹ bi oṣere Yoruba ati Gẹẹsi.

O si ti gba ami ẹyẹ lọpọlọpọ bakan naa.

JJC Skillz kọ ni ọkọ akọfẹ fun Funke Akindele:

Funke Akindele ati ọkọ rẹ akọkọ, Alhaji Kehinde Oloyede

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Funke Akindele ati ọkọ rẹ akọkọ, Alhaji Kehinde Oloyede

Funke Akindele ṣe igbeyawo rẹ akọkọ pẹlu Alhaji Adeola Kehinde Oloyede (Almaroof), ni oṣu Karun-un, lọdun 2012.

Alagbada fiimu ni Almarrof jẹ.

Funke kọ ni iyawo akọfẹ ọkunrin naa, iyawo rẹ kẹrin ni Funke jẹ.

Wọn tuka ninu oṣe Keje, ọdun 2013.

Ọdun mẹrin lẹyin rẹ lo fẹ JJC Skillz.

Funke, JJC Skillz ati awọn ọmọ rẹ mẹta akọkọ lọjọ igbeyawo wọn nilu London

Oríṣun àwòrán, Neecee bosslady

Àkọlé àwòrán, Funke, JJC Skillz ati awọn ọmọ rẹ mẹta akọkọ lọjọ igbeyawo wọn nilu London

Abdul Rasheed Bello (JJC Skillz)

Ọdun 1977 ni wọn bi Ọgbẹni Bello, nilu Kano. Ṣugbọn o fi orilẹ-ede Naijiria silẹ nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹrinla, lati ma an gbe nilu London.

O di gbajugbaja akọrin takasufe ni lati ọdun 2004, botilẹ jẹ pe o ti n kọrin ṣaaju asiko naa.

Ọdun 204 bakan naa lo gbe awọn orin rẹ akọkọ, atide, jade pẹlu ẹgbẹ akọrin rẹ, 419 Squard.

ṣaaju igbeyawo rẹ pẹlu Funke Akindele, ọmọ mẹta lo ti bi sílú London, lati ọdọ iya mẹta ọtọọtọ.

Yatọ si orin kikọ, o tun jẹ olootu ati oludari fiimu ati orin.

Bakan naa lo kopa ninu gbajúgbajà ere iyawo rẹ, Jenifa's Diary.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: