2023 General Elections: BBC ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwádìí láti mọ̀ bóyá Osinbajo jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ APC Eko tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́

Onírúurú ìròyìn ló ti gba orí ayélujára wí pé igbákejì Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yemi Osinbajo ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), ìpínlẹ̀ Eko sílẹ̀.
Lórí Instagram ni àwọn ènìyàn ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní tan ìròyìn náà ká, kí wọ́n tó máa gbe kiri lórí WhatsApp.
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n ń gbé kiri, wọ́n ní àtẹ̀jáde kan látọwọ́ agbẹnusọ Osinbajo, Laolu Akande ló fi ìkéde náà hàn wí pé Osinbajo ti pàrọ̀ wọ́ọ̀dù tó ti lè dìbò.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìdí tí Tinubu fi ṣèpàdé pẹ̀láwọn gómìnà APC lẹ́yìn tí Osinbajo kéde lati dupò ààrẹ
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ní pé Osinbajo dalẹ̀ Tinubu pẹ̀lú bó ṣe kéde láti du ipò ààrẹ?
- Tí mo bá di ààrẹ, ìwúrí ni màá jẹ́ fọ́mọ Nàíjíríà - Tunde Bakare
- Mo fẹ́ pokùnso torí ìjákulẹ̀ tí ọ̀gá mi, Yekini Ajileye fún mi, ọpẹ́ tọ́ọ́gì kan... - Abija
- Erin kọlu Amaya Sebastian, àgbà ọ̀jẹ́ ọjọ́gbọ́n nínú isẹ́ ìwádìí kan, ikú ló padà já sí
- Àjọ INEC ní àwọn káàdì ìdìbò kan kò wúlò mọ́ láti fi dìbò lọ́dún 2023
- Ìwúlò Buhari fún Nàíjíríà tí tán, kò búrú tó bá kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ - Ilana Omo Oodua
- Ó ti tán fún Nàìjíríà bí ará Àríwá bá tún di Ààrẹ lọ́dún 2023 - Adebanjo
- Nǹkan márùn-ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa Peter, ọkọ Osinachi, tí wọ́n fi ẹ̀sùn ikú aya rẹ̀ kàn
- Ẹ dákun, ẹ gbà mí, Auxillary ń lépa ẹ̀mí mi - Olopoeyan kọ̀wé sí ọlọ́pàá, DSS
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn náà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé ní ọdún 2021 ni Osinbajo tì pàrọ̀ jíjẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ kúrò ní ìpínlẹ̀ Eko lọ sí ìpínlẹ̀ Ogun tó jẹ́ ìlú abínibí rẹ̀.
Àwọn ènìyàn ṣì ń gbé ìròyìn náà kiri bí ẹni pé aáwọ̀ tó ń wáyé láàárín Tinubu àti Osinbajo, nítorí pé ó kéde èròńgbà rẹ̀ láti dupò Ààrẹ lọ́dún 2023, ló mú kó pàrọ̀ ibi tó ti lè dìbò.
Láti ọdún 2021 ni Osinbajo ti pàrọ̀ wọ́ọ̀dù rẹ̀:
Nínú àtẹ̀jáde kan lórí ẹ̀rọ ayélujára ni Osinbajo fi hàn wí pé nígbà tó ń tún orúkọ fi sílẹ̀ fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní wọ́ọ̀dù ìlú abínibí rẹ̀, ìyẹn ní Ikenne, ìpínlẹ̀ Ogun, lo ti gbe igbesẹ naa.
Amọ agbegbe Victoria Garden City, ìpínlẹ̀ Eko ti Osinbajo ń gbé, sì ti dìbò lọ́dún 2019.
Ẹ̀wẹ̀, èèkàn kan nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Ejiofor Agada ní ohun tí Osinbajo ṣe tọ̀nà lábẹ́ òfin ẹgbẹ́ wọn.
Agada ní òun náà ti pàrọ̀ ìjẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òun láti Ojodu, ìpínlẹ̀ Eko sí Unadu ní ìpínlẹ̀ Enugu.
Àti pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ máà ń ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé kò tọ̀nà láti wá láti ìlú kan, kò sí máa dìbò ní ìlú mìíràn.
Osinbajo ní kọmíṣọ́nà fétò ìdájọ́ ní ìpínlẹ̀ Eko, nígbà tí Bola Tinubu jẹ́ gómìnà, tí àwọn méjéèjì sì ti kéde ìpinu wọn láti di Ààrẹ Nàìjíríà.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó jẹ́ olóòtọ́ sí Tinubu ni inú wọn kò dún sí ìkéde Osinbajo yìí.



















