Bandits Attacks: Àwọn aṣòfin àpapọ̀ fọnmú pé ọwọ́ àwọn ológun kò mọ́ lórí ìkọlù agbébọn

ibudo rogbodiyan kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn aṣofin apapọ Naijiria ti beere fun yiyọ olubadamọran abo fun aarẹ Naijiria, Ọgagunfẹ̀yinti Babagana Monguno ati minisita feto abo, ọgagunfẹyinti Bashir Magashi kuro nipo wọn.

Awọn aṣofin ile aṣoju-ṣofin Naijiria tun fẹsun kan awọn agbofinro pe awọn gan n ṣe agbodegba fawọn agbebọn ati awọn ọdaran to n da Naijiria laamu.

Ile asofin apapọ ni awọn agbofinro yii ni ko si jẹ ki gbogbo obitibiti owo ti wọn n ya sọtọ fun kikọju ogun si aabo to mẹhẹ yọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni wọn tun fi ẹsun kan awọn adari ẹka ileeṣẹ abo ati agbofinro gbogbo lorilẹede naa pe awọn pẹlu n jifa ninu bi rọ abo ṣe mẹhẹ nitori owo gọbọi ti wọn n ya sọtọ fun ẹka naa.

Àkọlé fídíò, Female Carpenter: Fatia Garu ní ọ̀pọ̀ èèyàn ni kìí gbàgbọ́ pé obìnrin ló ń ṣiṣẹ́ Káfíńtà

"Ṣe aarẹ ko wa mọ pe nnkan o lọdaadaa fun awọn eeyan orilẹede yii ni?"

Ni ọjọ Aiku nikan, ko din ni aadọrin eeyan tawọn agbebọn yinbọn pa lawọn ileto kan nijọba ibilẹ Kanam ati Wase nipinlẹ Plateau

Ni ọjọ Aje rẹ, eeyan marundinlọgbọn miran ni wọn tun pa nijọba ibilẹ Guma ati Tiortyu nipinlẹ̀ Benue.

Awọn iku ọwọọwọ yii lo mu ki alaga igbimọ̀ tẹẹkoto lori ọrọ ileeṣẹ ọmọogun oju omi, iyẹn Họnọrebu Yusuf Gagdi fi gbe aba kan dide lori awọn isẹlẹ aabo to mẹhẹ yii.

Lati ipasẹ aba naa lo ti jẹ ki gbogbo ile mọ pe ko si eredi fun ijọba ti ko ba mọ ipese abo to peye ati igbayegbadun araalu jẹ ara koko kan gboogi idi ti oun fi wa nipo.

O ni o ṣe ni laanu pe ni Naijiria tawọn agbebọn ti n pa araalu nipakupa yii, "a ni aarẹ. A ni gomina pẹlu.

A ni ile igbimọ aṣofin apapọ, a ni sẹnetọ atawọn aṣojuṣofin gbogbo. Ta gan lo wa ni akoso alaafia ati igbayegbadun ati abo araalu lorilẹede yii? Laini deena pẹnu gbogbo wa la mọ pe aarẹ ni.

"Ṣe aarẹ ko wa mọ pe nnkan o lọ daadaa fun awọn eeyan orilẹede yii ni? Ṣe o n gun gbogbo awọn adari ikọ alaabo gbogbo tọrọ kan pẹlu aisi abo yii ni kẹsẹ?"

Ologun kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ọmọogun lo n fun awọn agbebọn ni aṣọ iṣẹ wọn lati ṣọṣẹ ni Plateau -Igbakeji olori ile

Igbakeji olori ile aṣoju-ṣofin, Họnọrebu Ahmed Wase, to ṣakoso ijoko ile lọjọru fi ẹsun kan pe ileeṣẹ̀ agbofinro gbogbo lo n ṣe agbodegba fawọn agbebọn ati ọdaran gbogbo lorilẹede Naijiria.

Họnọrebu Wase, ti ilu rẹ wa lara awọn agbegbe tawọn agbebọn naa kọlu, ni iye awọn eeyan ti wọn n gbe kiri pe awọn agbebọn naa pa kere si iye awọn eeyan ti wọn pa lọ.

O ni nitori eto isinku alapapọ lawọn eeyan agbegbe naa n ṣe fun ọgọrọ eeyan tawọn agbebọn naa pa nibẹ.

"Ni ileto temi, a ni ṣọja kan to yẹ ko wa ni Zamfara, ti wọn si n fun laaye isinmi ni ṣisẹ n tẹle fun oṣu mẹfa.

Ọwọ tẹ ẹ pe o n fun awọn agbebọn ni aṣọ iṣẹ ologun rẹ, titi di bi mo ṣe n sọrọ yii, ko tii fi oju wina ofin o.

Bi o ba yẹ ko wa lẹnu iṣẹ ni Zamfara, ti ọwọ si wa tẹ ẹ ni Plateau, ta lo n fun un laaye lati kuro loju iṣẹ?

Ki si ni idi ti wọn fi n fun ologun to yẹ ko wa loju ija ni iyọnda oṣu mẹfa?

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Gbẹ̀fẹ́ ní àkókò tí mo lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, àìrì aya mi nìkan ní ìyàtọ̀

BBC Yoruba kan si agbẹnusọ fun ileesẹ ologun lati mọ iha wọn si awọn sun naa amọ o ni oun yoo kan si wa [pada laipẹ lẹyin ti oun ba gbọ ẹkunrẹrẹ ijiroro awọn asofin naa.