Russia-Ukraine Crisis: Wo ìdí tí Ààrẹ Russia, Putin fí ní ìkọlù rẹ̀ sí Ukraine yóò fi tẹ̀síwájú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijiroro alaafia ti dẹnukọlẹ tori naa ikọlu Ukraine taa ti n ba bọ lati nkan bi ọsẹ mẹfa yoo tẹsiwaju.
Ọrọ ree lati ẹnu aarẹ Russia,Vladimir Putin to ba araalu sọrọ laipẹ yii.
Amọ oṣiṣẹ orileede Ukraine kan sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe ijiroro n tẹsiwaju botilẹ jẹ wi pe nkan ko rọgbọ.
- "Àwọn ọmọ ogun Russia fipá bá mi lòpọ̀, wọ́n tún pa ọkọ mi"
- Àwọn tó ń fún Putin lámọ̀ràn kò sọ òọ́tọ́ pẹ̀lú rẹ̀ lórí ogun Ukraine - Amẹ́ríkà
- Russia ń kọlu àwọn iléèwé àti iléèwòsàn - Ukraine
- A ṣì lè yanjú ọ̀rọ̀ Ukraine ní ìtùbí-ìnùbí - Russia
- Wo ìdí pàtàkì mẹ́ta tí Russia se kọlu Ukraine
- Ọ̀rọ̀ yóò lẹ́yìn bí China bá ṣerànwọ́ fún Russia lórí ogun Ukraine - Amẹ́ríkà lọgun
Ọrọ ti aarẹ Putin sọ yi ni akọkọ ti yoo fi mẹnu ba ikọlu Russia si Ukriane laarin ọsẹ kan bayii.
Eyi jẹ iyapa si ohun to n ṣẹlẹ nigba ti ikọlu naa kọkọ bẹrẹ to ṣe pe Putin dori kodo bi adan ni to si n wo iṣe ẹyẹ nkan to n lọ.
Lasiko abẹwo rẹ si ileeṣẹ to n risi irinajo si oju sanmọ to wa ni ila oorun Russia pẹlu aarẹ Belarus Aleksandr Lukashenko, ọkan lara awọn wọlewọde rẹ, ni Putin sọ ọrọ yii.
Bẹẹ la gbọ pe o fi abẹwo yii ṣe Iranti ajọdun ọdun kọkanlelọgọta ti Yuri Gagarin di ọkunrin akọkọ ti yoo lọ si oju sanmọ.
Mo fẹ daabo bo awọn to n sọ ede Russia ni Ukraine ni mo fi n se ikọlu sibẹ?
Aarẹ Russia sọ pe ko si nkankan toun le ṣe ju pe ki oun paṣẹ ikọlu si Ukraine, lati le fi daabo bo awọn to n sọ ede Russia ni ila oorun Ukraine.
Ile ijọba Russia ni Kremlin naa sọ pe Ukraine ti daran ipaniyan nipa pipa awọn eeyan to n sọ ede Russia ni agbegbe ila oorun Ukraine amọ ko si aridaju ọrọ yii.
Wọn ni "Bi a ba foju ẹgbẹ kan wo, niṣe la n ṣe iranwọ fawọn eeyan, bi a ba foju mii wo, a kan n gbe igbesẹ lati daabo bo orileede Russia fun ara rẹ ni''
O tẹsiwaju pe ''a ko ni nkankan ta tun le ṣe ju pe ka kogun ja wọn.Igbesẹ to yẹ la gbe.''
O fi kun pe awọn yoo maa fi ẹlẹ tẹsiwaju ikọlu tawọn n ṣe si Ukraine.
Miliọnu mẹwa eeyan lo ti sa kuro ni Ukraine - UN
Ni bayi, Moscow ti ṣiju lọ si ila oorun Ukraine nipa kiko awọn ọmọ ogun kuro ni ariwa ilẹ naa lẹyin ti wọn koju ija lile lọdọ awọn ọmọ ogun Ukraine.
Ajọ UN si ti wa sọ bayi pe miliọnu mẹwaa eeyan lo ti sa kuro nilẹ naa lẹyin ti ikọlu yi bẹrẹ.
Agbẹnusọ fun aarẹ Russia, Dmitry Peskov, lawọn gba pe lootọ lawọn ọmọ ogun wọn koju ifidirẹmi to lamilaka lati igba ti ikọlu naa ti bẹrẹ.
Ati Russia ati Ukraine, ko si eleyi taa le fidi ọrọ mulẹ ni pato iye awọn eeyan to padanu ẹmi wọn ninu ikọlu yi lọdọ wọ́n.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ṣe lóòótọ́ ni pé Osinbajo kìí se ọmọ ẹgbẹ́ APC l‘Eko?
- Ìdí tí Tinubu fi ṣèpàdé pẹ̀láwọn gómìnà APC lẹ́yìn tí Osinbajo kéde lati dupò ààrẹ
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ní pé Osinbajo dalẹ̀ Tinubu pẹ̀lú bó ṣe kéde láti du ipò ààrẹ?
- Tí mo bá di ààrẹ, ìwúrí ni màá jẹ́ fọ́mọ Nàíjíríà - Tunde Bakare
- Mo fẹ́ pokùnso torí ìjákulẹ̀ tí ọ̀gá mi, Yekini Ajileye fún mi, ọpẹ́ tọ́ọ́gì kan... - Abija
- Erin kọlu Amaya Sebastian, àgbà ọ̀jẹ́ ọjọ́gbọ́n nínú isẹ́ ìwádìí kan, ikú ló padà já sí
- Àjọ INEC ní àwọn káàdì ìdìbò kan kò wúlò mọ́ láti fi dìbò lọ́dún 2023
- Ìwúlò Buhari fún Nàíjíríà tí tán, kò búrú tó bá kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ - Ilana Omo Oodua
- Ó ti tán fún Nàìjíríà bí ará Àríwá bá tún di Ààrẹ lọ́dún 2023 - Adebanjo
- Nǹkan márùn-ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa Peter, ọkọ Osinachi, tí wọ́n fi ẹ̀sùn ikú aya rẹ̀ kàn
- Ẹ dákun, ẹ gbà mí, Auxillary ń lépa ẹ̀mí mi - Olopoeyan kọ̀wé sí ọlọ́pàá, DSS
Awọn onwoye ni o ṣeeṣe ki Russia maa ṣe adinku iye awọn to ku lọdọ rẹ nigba ti Ukraine naa si le maa fi kun iye awọn ọmọ Russia ti wọn pa lati fi ṣe moriwu fawọn ikọ ọmọ ogun rẹ.
Awọn olori ilẹ Yuroop naa ni laarin ẹgbẹrun meje si mẹẹdogun ọmọ ogun Russia ni wọ́n ti pa bayi.
Yatọ si eleyi, eto ọrọ aje Russia naa ti mọ riri awọn ijiya lorisirisi tawọn olori agbaye ti fi n jẹ wọn.
Ṣugbọn lọjọ Iṣẹgun to sọrọ, aarẹ Putin ni kii se erongba oun ni pe ki wọn sọ ilẹ rẹ di aladanikanṣe to si ni ko le ṣeeṣe ki wọn pa orileede kan ti saaye ara rẹ lode oni paapa orileede bi Russia.
Awọn iṣẹlẹ miran to n waye:
- Russia mura si igbiyanju rẹ lati gba ibudo ti ọkọ oju omi n balẹ si ni Mariupol.Olori ilu naa sọ pe o kere tan eeyan ẹgbẹrun lọna mọkanlelogun lo ti ku ni ilu naa amọ awọn ti dawọ kika oku duro nitori ija to n waye nibẹ.
- Bẹẹ naa ni ilu yi,awọn ijọba orileede Yuroopu ati awọn ileeṣẹ ilẹ okere kọọkan ni ọkan awọn ko balẹ lori iroyin lilo nkan ija kẹmika oloro lati ọwọ Russia si awọn eeyan Mariupol.
- Awọn ọmọ ogun Ukraine kede pe ọwọ awọn ti tẹ oloselu alatilẹyin Russia to na papa bori ni Viktor Medvedchuk. O ti to ọjọ mẹta to wa ni ahamọ lori ẹsun iditẹmọ ijọba to si ti na papa bora lẹnu igba ti ikọluyi bẹrẹ.
- Bakan naa Gomina Luhansk to wa ni iwọ oorun Ukraine sọ pe o ti to irinwo oku tawọn ti gbe sin ni ilu Severodonetsk lẹgbẹ ibi ti ikọlu ti n gbona.

















