Russia/Ukraine crisis: Àwọn tó ń fún Putin lámọ̀ràn kò sọ òọ́tọ́ pẹ̀lú rẹ̀ lórí ogun Ukraine - Amẹ́ríkà

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Russia, Vladimir Putin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti wòye wí pé àwọn tó ń fún Ààrẹ orílẹ̀ èdè Russia, Vladimir Putin ní ìmọ̀ràn lórí ogun tó ń gbé ti Ukraine kò ṣe òótọ́ pẹ̀lú rẹ̀.

Agbẹnusọ Pentagon, John Kirby ní Mínísítà fétò ààbò Russia kò sọ òótọ́ fún Putin lórí bí àwọn ọmọ ogun Russia ṣe ti ń kùnà lórí ogun náà láti bí oṣù kan sẹ́yìn.

Kirby ní àyẹ̀wò bí ohun gbogbo ṣe ń lọ lórí ogun náà fi hàn wí pé Putin le má mọ̀ wí pé ogun náà yóò parí ṣíṣe ọ̀rọ̀ ìpẹ̀tùsááwọ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Èyí sì ti ń fa inú fo àyà fo láàárín Putin àti àwọn adárí ikọ̀ ọmọ ogun rẹ̀.

"Ohun mìíràn ni wí pé a kò mọ̀ bí àwọn olórí bíi Putin ṣe le gba irú ìròyìn bẹ́ẹ̀, ó lé jẹ́ ìdí nìyìí tí wọn kò fi sọ òótọ́ fun."

Bákan náà ló ní ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé wọ́n ń bẹ̀rù láti sọ fun wí pé ogun náà kò lọ bí ó ṣe fẹ́ àti wí pé ó dàbí pé kò mọ ipa tí gbogbo òfin tí àwọn orílẹ̀ èdè kan fi de Russia yóò kó nínú ètò ọrọ̀ ajé rẹ̀.

Àkọlé fídíò, Abdulfatai Balogun: N kò ríran àmọ́ oníṣòwò Yoghurt ní mí tó ń fi àwìn sàánú fún oníbàárà
Amin iyasọtọ kan

Ìjíròrò láàrin Russia àti Ukraine yóò so èso rere - Ààrẹ Turkey

Ibi ìpàdé àwọn aṣojú Russia àti Ukraine
Àkọlé àwòrán, Ibi ìpàdé àwọn aṣojú Russia àti Ukraine

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Turkey, Recep Tayyip Erdogan ti ní kò yẹ kí aáwọ̀ wáyé láàárín Ààrẹ Zelensky ti Ukraine àti akẹgbẹ́ rẹ̀ ní Russia, Putin nítorí ọ̀rẹ́ ni àwọn méjéèjì.

Erdogan sọ èyí bí ìjíròrò yóò ṣe máa wáyé láàárín àwọn aṣojú orílẹ̀ èdè méjéèjì ní Instabul ní òwúrọ̀ yìí.

Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ pé ìpàdé náà yóò so èso rere, tí àwọn Ààrẹ méjéèjì náà yóò fojú kojú àti pé inú òun yóó dùn láti ṣe agbátẹrù ìpàdé bẹ́ẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bákan náà ló sọ fún àwọn aṣojú Ukraine àti Russia pé lóòótọ́ ní àwọn orílẹ̀ èdè méjéèjì ní àwọn ohun tí ó ń dùn wọ́n lọ́kán tí wọ́n sì ń fẹ́ ṣùgbọ́n ó ní ìpàdé náà mú àbọ̀ rere jáde.

Àkọlé fídíò, Wo ohun tí Professor Peller wí tó kó bá a gẹ́gẹ́ bí ìyàwó rẹ̀, Lady Peller ṣe tú u síta

Àwọn aṣojú Russia àti Ukraine balẹ̀ sí Turkey fún ìjíròrò:

Àwọn aṣojú orílẹ̀ èdè Russia àti Ukraine ti balẹ̀ sí ọ́fíìsì Ààrẹ Erdogan tó wà ní Dolmabahce ní Instabul.

Awọn asoju naa ni wọ́n yóò máa jíròrò lórí bí Russia yóò ṣe dáwọ́ ìkọlù tó ń ṣe sí Ukraine dúró.

Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí àwọn aṣojú orílẹ̀ èdè méjéèjì yóò máa ṣèpàdé ní ojúkojú láti bí ọ̀sẹ̀ méjì ṣùgbọ́n kò dájú pé ìpàdè náà yóò mú àbọ̀ tó ja jáde.

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Turkey, Recep Tayyip Erdogan ní ó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn wí pé ogun tó ń wáyé láàárín àwọn orílẹ̀ èdè méjéèjì ti wọ ọ̀sẹ̀ kẹta báyìí àti pé ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín Turkey àti àwọn orílẹ̀ èdè méjéèjì ló jẹ́ kí òun le dá sí aáwọ̀ náà.

Erdogan ní ọwọ́ àwọn orílẹ̀ èdè méjéèjì ní dídá ọwọ́ ogun náà dúró wà.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Turkey jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀ èdè tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ NATO síbẹ̀ ó ní ìbáṣepọ̀ tó dán mọ́rán pẹ̀lú Russia, ó sì wà lára àwọn orílẹ̀ èdè díẹ̀ tí kò ì tíì fòfin dé Russia lórí ìkọlù tó ń gbé ti Ukraine.

Àkọlé fídíò, Funke-Gbenga Adetuberu: Òjíṣẹ́ Ọlọ́run rèé tó ní ọmọ líle, ó sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí