Ukraine Conflict: Obìnrin kan ní ọmọ ogun Russia fipá bá òun lòpọ̀, tí wọ́n tún pa ọkọ òun

Arabinrin Anna sọ fun BBC pe awọn ọmọ ogun Russia tun pa ọkọ oun

Lootọ ni awọn ọmọ ogun Russia ti kuro ni awọn ilu to yi olu ilu orilẹ-ede Ukraine, Kyiv, ka. Ṣugbọn ọpọlọpọ ọgbẹ́ ati ibanujẹ ọkan ni wọn fi silẹ nibẹ. BBC gbọ ọrọ lẹnu awọn obirin ti awọn ọmọ ogun Russia fi ipa balopọ.

Ọkan lara awọn obinrin to baa BBC sọrọ, sọ pe ni ọjọ keje, oṣu Kẹta, ni awọn ọmọ ogun ilẹ okeere kan fi ipa wọ inu ile ti oun ati ọkọ oun n gbe.

A fi orukọ bo obinrin yii ni aṣiri, ṣugbọn ao pe ni Anna.

"Pẹlu ibọn to si mu mi lọ si ile kan to wa nitosi. Nibẹ si lo ti fi ipa bamilopọ lẹyin to ni ki n bọ aṣọ.

O ni ti mo ba kọ lati ṣe bẹẹ, oun yoo yinbọn pa mi."

Àkọlé fídíò, Láti sẹ́ńtúrì kẹrìnlá ni ìfaǹfà ti ń wáyé láàárín Russia àti Ukraine

Anna ṣapejuwe ẹni to fi ipa balopọ pe ọdọmọkunrin ni, to si jẹ ajijagbara Chenchen to n ba Russia jagun.

Nibi ti ọmọkunrin naa ti n fi ipa ba Anna lopọ, ni awọn sọja mẹrin miran wọle ba wọn. Awọn wọnyii ti awọn naa jẹ ọmọ ogun Russia dóòlà Anna, ti wọn si mu ọmọkunrin naa lọ.

Oku ọkọ rẹ ni Anna ba, nigba to pada sile. Wọn ti yinbọn mọ ni inu. Lẹyin ọjọ meji ni ọkọ rẹ ku, nitori pe ogun naa ko jẹ ki wọn o le gbe lọ sileewosan.

Iboji yii ni Anna sin oku ọkọ rẹ si ni ẹyinkule ile wọn
Àkọlé àwòrán, Iboji yii ni Anna sin oku ọkọ rẹ si ni ẹyinkule ile wọn

Ni ile miran ti ko jina si ile Anna, awọn aladugbo sọ pe ọkunrin to fi ipa ba Anna lo pọ, tun ṣe bẹẹ fun obinrin to n gbe inu ile naa, to si tun pa a .

Niṣe lo mu oun naa kuro ninu ile rẹ, to si balopọ ninu ile kan ti awọ̀n to ni ti sa kuro nigba ti ogun Russia bẹrẹ.

Aladugbo kan, Oksana, sọ fun BBC pe awọn ọmọ ogun Russia sọ fun oun pe niṣe ni ọkunrin naa ge gogongo obinrin ọhun lẹyin to balopọ tan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọga ọlọpaa ni agbegbe Kyiv, Andrii Nebytov, sọ fun BBC pe yatọ si iṣẹlẹ meji akọkọ, awọn tun n ṣe iwadii bi awọn ọmọ ogun Russia kan ṣe pa ọkunirn kan nitori o gbiyanju lati daabo bo iyawo rẹ.

Wọn si fi ipa ba iyawo rẹ lopọ fun igba mẹrin lẹyin iku rẹ, ninu ile naa lai naani ọmọ rẹ.

Lẹyin naa ni wọn dana sun ile wọn.

Inu yaara yii ni wọn ti ba oku obinrin naa. Ti awọn ọmọ ogun Russia si kọ akọsilẹ ibi ti wọn sin oku rẹ si, soju dígí to wa nibẹ.
Àkọlé àwòrán, Inu yaara yii ni wọn ti ba oku obinrin naa. Ti awọn ọmọ ogun Russia si kọ akọsilẹ ibi ti wọn sin oku rẹ si, soju dígí to wa nibẹ.

Olori ajọ ajafẹtọ ọmọniyan ni Ukraine, Lyudmyla Denisova sọ pe awọn ọdọbinrin ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹrinla si mẹrinlelogun, ni awọn ọmọ ogun Russia tun balopọ pẹlu ipa, ninu ile kan ti awọn obinrin naa fi ara pamọ si nilu Bucha. Mẹsan-an lara wọn ti loyun bayii.

O ni awọn ifipabanilopọ miran tun waye, ṣugbọn ti awọn ko ni akọsilẹ fun.

Ṣugbọn ṣa, Arabinrin Denisova sọ pe Ukraine n fẹ ki ajọ United Nations gbe igbimọ pataki kalẹ, ti yoo foju aarẹ Russia, Vladimir Putin wina igbẹjọ fun awọn ẹsun yii.

Àkọlé fídíò, Abisola Odebode: Ẹ wo àkàndá ẹ̀dá tó ń kọ́ àwọn àgùnbánirọ̀ l‘Osun ní ọ̀dà ṣíṣe lọ́fẹ̀ẹ́