Contaminated milk: Kà síi nípa ìkìlọ̀ pàtàkì lórí ayédèrú mílíkì tó gba ìgboro kan- NAFDAC

Oríṣun àwòrán, @NAFDAC
NAFDAC se ikilo lori awon ounje ilẹ̀ okeere
Ajọ to n gbogun ti aṣilo oogun ati ounjẹ lorilẹede Naijiria, NAFDAC ti kilọ fun awọn ọmọ Naijiria lati ṣọra fun miliki ati awọn ounjẹ aṣaraloore kan ti wọn ko wa lati ilẹ okeere.
Ni pataki, wọn ni ki araalu yago fawọn ounjẹ yi nitori ileeṣẹ to n peelo awọn ounjẹ yi Continental Mills ti ni ki wọn ko awọn ọja naa kuro lori igba
Die lara won ni Great Value Buttermilk Pancake ati Waffle Mix kuro lori igba nitori awọn nkn to le ṣakoba fun ara ti wọn b ninu wọn lati ilẹ okeere.
- Àkàrà tú sépo fún ayédèrú ọ̀gágun tó fi Khaki lú jìbìtì N266.5m
- "Àwọn ọmọ ogun Russia fipá bá mi lòpọ̀, wọ́n tún pa ọkọ mi"
- Ìjà ńlá bẹ́ sílẹ̀ l‘Eko láàrin igun MC Oluomo àti ẹgbẹ́ awakọ̀ márúwá TOOAN
- Kí ló dé tí ẹnu ń kun ìgbeyàwó Funke Akindele pé ó ti dàrú? Àbọ̀ ìwádìí wa rèé
- Rògbòdìyàn ṣẹlẹ̀ n‘Ibadan, ọwọ́ tẹ jàǹdùkú nílé Olopoeyan pẹ̀lú káàdì ìdámọ̀ ẹgbẹ́ Auxillary
Bawo ni ikilo yii se jade?
Ọga agba ajọ NAFDAC, Arabinrin Moji Adeyeye lo buwọlu iwe ikilọ yii to ni nọmba idanimọ 021/2022.
O si sọ ni ọjọ Aiku pe wọn ti fọn ọja wọnyi kaakiri ni orile-ede Amẹrika nibi tawọn eeyn ti n ra a witiwiti ni ile itaja igbalode Walmart.
Bẹẹ lo fi kun un pe awọn ri ẹrunrun ''cable'' ti wọn fi ko awọn ọja yi ninu wọn.
Kini NAFDAC tun so?
Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn onibara kankan ko ti wa fẹjọ sun pe awọn ri ọja to le pa awọn lara lori igba ati pe ko ti si eeyan kankan ti awọn ọja wọnyi se ipalara fun.
O wa rọ awọn ọlọja,alatunta ati oniworobo to ba fẹ gbe ọja yi wọle pe ki wọn ri wi pe oju lalakan fi sọọri ki wọn si ṣọra fun rira ọja ti wọn ti ko kuro nilẹ yi.
Ajọ NAFDAC tun kesi araalu to se pe ọja yi ba wa lọwọ wọn lati ri pe wọn jawọ nibi lilo tabi tita rẹ.
Wọn ni ki wọn yara ko irufẹ ọja yi lọ si ileeṣẹ NAFDAC to ba wa ni itosi wọn.
- Àwọn agbébọn ṣekúpa alága APC ní ìpínlẹ̀ Osun, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí
- Kí ló dé tí ọkùnrin yìí fi dojúkọ Kìnìún ààyè?
- Èèmọ̀ wọ̀lú! Àwọn agbébọn pa ènìyàn 135 lọ́jọ́ kan ṣoṣo
- Oluwo ṣe àbẹ̀wò sí Aláàfin lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tó gbé ìyàwó tuntun
- Àwọn ọmọ Palestine kọlu ìbòjì Josẹfu ọmọ Jakọbu, wọ́n dáná sun-ún














