Soun Ogbomosho Controversy: Èmi tí mò ń sọ̀rọ̀ yìí lẹ́tọ̀ sí òyè Soun àmọ...
Bi eeyan ba jẹ oye Soun, bo ba debẹ̀, yoo di olowo, tori ni gbogbo ibi laye, wọn o ki n fi owo jẹ Ọba
Lorii rogbodiyan to n ṣẹlẹ́ nipa tani ipo Soun tọ si tabi tani ko tọ si ni ilu Ogbomoso ti di tọrọ fọn kalẹ bayii.
Koda, ọrọ ti kuro ni eyi tawọn agba n da si nikan, wọn ti n ki ọrọ ile ẹjọ bọ ọ.
BBC Yoruba ba ọkan lara awọn agba ilu, Ọjọgbọn Amos Adekojo sọrọ ninu eyi to ti ṣalaye iye idile oye to wa ati nkan to n ṣẹlẹ gangan lori ipo Ọba ilu naa.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọkan ninu awọn idile to n du ipo naa ni awọn afọbajẹ yọ ọwọ ọmọ wọn lawo lati le fi dije ipo Soun.
"Latorii Soun to gbesẹ̀ láìpẹ́ yii ni: idile Laoye Orumogege idle Bolanta, idle Ojo Aburumaku ni awọn idile Oye ti Ọjọgbọn Amos sọ fun wa.
Ẹwẹ, bi idile kan ṣe ti n tukọ soke ti wọn n fi oju gbaa, ni a ni ka kan si awọn ti ọrọ yii kan gangan ni ilu Ogbomoso.
Ọjọgbọn Amos Adekojo ni latigba ti alaye ti daye, ẹni to ba dagba ju ni wọn maa n fi jẹ Soun amọ awọn igbesẹ to n jade yii ti n yatọ.
"Ninu awọn idile ọhun, awọn ọmọ baba yoo ti sọrọ fori-kori bi idile kan ba n jọba lọwọ pe ki awọn gbaradi".
"Aa gbọpe wọn maa n ta fọọmu fun eeyan lati jẹ Ọba".
Ẹwẹ, agbalagba miran to tilẹ jẹ ọmọ ile oye naa ba BBC Yoruba sọrọ nipa ẹtọ bo ṣe n lọ lọwọ, nkan ti wọn n foju ri ati ibi to de duro.
"Emi tẹẹ n wo ti mo n baa yin sọrọ yii, mo ẹtọ si oye Soun amọ fun idi pataki kan, mo mọ pe agba ti de, mo gbọdọ fi silẹ fun awọn ọmọ".
Baba Garuba Olaoye ṣalaye pe agba lo mu ki awọn ni ki awọn ọmọ awọn kuku lọ gba fọọmu to ba ti wu kii ṣe pe awọn fẹ fi fọọmu pa owo fi jẹun.
Gbogbo ọrọ ija to wa nilẹ ni awọn agbaagba ti BBC bna sọrọ yii ṣalaye lẹkunrẹrẹ.
Baba Garuba wa ke si Gomina Seyi Makinde lati wa ran awọn lọwọ gẹgẹ bo ṣe da si ọrọ ti Olubadan.

