Dust storm: Àwọn aráàlú ti dèrò Họsibítù látàrí ìjì eruku lala tó ń sọ ní Iraq

Awọn ọkọ to n rin laarin iji eleruku

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nkan bii ikuuku to nipọn gidi ti awọ rẹ si jẹ awọ olomi ọsan ti mu ayipada ba oju ọjọ kaakiri orilẹede Iraq.

Nibayii, wọn ko jẹ ki awọn ọkọ baalu gbera lati fo ni papakọ ofurufu Baghdad ati Najaf nitori iran riri bai-bai.

Awọn ọkọ to n rin laarin iji eleruku

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Koda, gẹgẹ bi nkan ti awọn awoju ọrun ṣe sọ, ireti wa pe iṣẹlẹ na yoo tẹsiwaju titi di ọjọ Aje

Awọn nkan to n ṣẹlẹ latari ayipada yii naa ni wọn ni yoo tẹsiwaju.

Akodọti kan loju popo ni Bagdad

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iji lile eleruku yii ti n wọpọ ni arin gbungbun Guusu orilẹede naa ti awọn akọṣẹmọṣẹ si da ẹbi rẹ le idapọ oniruuru ayipada oju ọjọ ati ilolkulọ ilẹ ati omi.

Ọlọpaa Iraq

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé fídíò, Èmi nìkan ni ikú Alaafin dùn jù ní gbogbo ayé yìí torí èmi nìkàn ṣoṣo ni mo mọ̀ ǹkan ... - Baba Kekere

Lawọn ibi kọọkan ni Iraq lọjọ Abamẹta, ibi ti awọn eeyan le riran to mọ gaara mọ ko ju mita ẹẹdẹgbẹta lọ.

Awọn ọkọ ati ọkada to n rin laarin iji eleruku

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni oṣu to kọja, oniruuru iji eleruku ni Iraq ni iriri iji eleruku yii to si sọ ọpọ di ero ile iwosan.

Ẹwẹ, ajọ to n ri si imọ nipa awọnsanmọ ni Iraq sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe o ṣeeṣe ki wọn tun ri iru iṣẹlẹ yii sii nitori ọda ati adinku ojo rirọ.

Awọn ọkọ to n rin laarin iji eleruku

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bakan naa ni wọn ni aisi awọn papa oko tutu daadaa lawọn agbegbe lee dakun iṣoro naa.

Koda ajọ to n ri si ọrọ ayika ni isọkan agbaye (UNEP) ti ṣaaju woye pe Iraq lee foju ri ọọdurun iṣẹlẹ eruku riru ninu ọdun kan nigba ti yoo fi di ọdun 2026.

Aworan iha Guusu Najaf latoju ofurufu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé fídíò, Idiroko border open:Àwọn Egun ló yẹ k'Ọ́lọ́pàá máà gba owó ibodè lọ́wọ́ wọn àmọ́...