Paracetamol arrested in Ogun: Bí Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ogun ṣe fi òfin mú Paracetamol tó jẹ́ olórí ẹgbẹ́ òkùnkùn

Paracetamol

Oríṣun àwòrán, NPF

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fi ṣikun ofun mu ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ti wọn sọ pe o n da agbegbe Abeokuta ati ijọba ibilẹ Ifo laamu.

Afurasi naa, Rotimi Adebiyi, ti ọpọ eeyan mọ si "Paracetamol" ni awọn ọlọpaa ti n wa tẹlẹ ṣaaju asiko yii.

Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ naa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi fi ṣọwọ si awọn akọroyin, o ni ipa ti Paracetamol ko ninu awọn laasigbo to waye nipinlẹ Ogun ti fa iku awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to jẹ alatako rẹ.

Àkọlé fídíò, Ó gbé owó fún mi, ó tún ra fóònù ńlá fún mi - Bàbá Onílù Ibadan sọ bó ṣe pàde Àgùnbánirọ̀ tó dáa lọ́lá

O ni "O ti pẹ ti a ti n wa Paracetamol, lori ipa to ko ninu awọn rogbodiyan laarin ẹgbẹ okunkun rẹ, ati ẹgbẹ okunku mi."

"Afurasi ọhun, to jẹ olori ẹgbẹ Eiye, maa wa lati ibuba rẹ niluu Ifo lati ṣọṣẹ niluu Abeokuta, ti yoo tun yọ kẹlẹ pada Ifo ki ọwọ wa to tẹ ni ibuba rẹ."

Oyeyemi sọ siwaju si pe lẹyin ti awọn eeyan fi to awọn leti nipa ibi ti afurasi naa n farapamọ si ni awọn akọmọṣẹ ikọ ọtẹlẹmuyẹ ṣabẹwo sibẹ loru ọganjọ ki ọwọ to tẹ.

Àkọlé fídíò, Èmi nìkan ni ikú Alaafin dùn jù ní gbogbo ayé yìí torí èmi nìkàn ṣoṣo ni mo mọ̀ ǹkan ... - Baba Kekere

O ni "Lẹyin ti awọn ọlọpaa ṣe ofintoto ibi to n lugọ si ni a kọlu agbegbe naa ni nnkan bii aago kan abọ oru lọjọ Satide, ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2022, ti a si fi ṣikun ofin mu."

Lara awọn ohun ija oloro ti wọn ka mọ afurasi naa lọwọ ni ibọn ilewọ kan, ọta ibọn, ada, igbo atawọn oogun abẹnu gọngọ.

Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankole ti paṣẹ ki awọn agbofinro ṣe iwadii ni kikun nipa afurasi naa ko le tete foju bale ẹjọ.

Àkọlé fídíò, Idiroko border open:Àwọn Egun ló yẹ k'Ọ́lọ́pàá máà gba owó ibodè lọ́wọ́ wọn àmọ́...