Baba Kekere Alaafin Oyo: Morenikeji Lasisi sọ àwọn àṣírí nípa ìbáṣepọ òun àtàwọn Alaafin Oyo tó sìn gẹ́gẹ́ bí ẹrú
"Àtijẹ, àtimu mi, titi de bi owo nina ati aṣọ, Alaafin ko fi wọn mi, koda oju mi mejeji yii ti fọ, oun lo n gbe mi lọ Dokita to la mi loju".
Laipẹ yii ni iroyin wu aworan eeyan kan ti ẹnikẹni ko wa ni gbogbo igba ti Alaafin Oba Lamidi fi wa lori oye jade.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ko fi bẹẹ si ara ita to mọ talo n jẹ Baba Kekere l'Aafin Oyo ati ipo rẹ amọ kete ti Baba Alaafin papoda ti wọn si ṣe isinku rẹ ni okiki orukọ Baba yii bẹrẹ si ni tan nigba ti awọn iroyin kan lọ wu aworan baba ọhun jade pe ki awọn eeyan wa wo baba arugbo kan to ṣi wa laye l'Aafin Oyo toju rẹ si ti ri ọpọlọpọ iṣejọba ninu Aafin ọhun.

Lara iroyin taa gbọ ni pe Baba Kekere ọhun ti ri Alaafin mẹta ọtọọtọ to jẹ.
BBC Yoruba de Aafin Oyo lati gbe iwadii jade lori oriṣiriṣi awuyewuye nipa baba yii ati pe ṣe lootọ ni pe aworan yii tilẹ jẹ ootọ ti Baba ọhun ṣi wa laye?
Bẹẹ ni eeyan to n jẹ Baba Kekere wa o si wa laaye l'Aafin Oyo

Oríṣun àwòrán, Spashfm
Morenikeji Lasisi olori gbogbo eru ni afin oba Oyo ti sin Oba meta. Sugbon Lasisi ni wọn n pe ni Baba Kekere laafin Oyo.
Nigba ti BBC de ọdọ Baba Kekere, baba agbalagba naa kẹnu bọ ọrọ lori ribiribi ti Alaafin Oba Lamidi ti ṣe.
"Kii ṣe ẹẹmẹta, ẹẹmẹrin ni Kabiyesi ti gbe mi lọ Dokita fun itọju oju mi ti mo ti padanu, ti n gbe mi lọ ti n gbe mi bọ".

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Morenikeji Lasisi ni olori gbogbo ẹru ni ilu Oyo to si ti ba Alaafin mẹta ọtọọtọ ṣiṣẹ.
O sọ fun BBC Yoruba pe oun o le sọ pato iye igba ti oun ti lo tori ko si akọsilẹ laye atijọ.
"Nigba aye Ọba akọkọ, ko si akọsilẹ, ẹlẹẹkeji ko si akọsilẹ, ẹlẹẹkẹta yii ni akọsilẹ wa".



