Alaafin Oyo: Wo ohun tí o kò mọ̀ nípa Morenikeji Lasisi, olórí ẹrú tó ti bá Aláàfin mẹ́ta ṣiṣẹ́

Morenikeji Lasisi olori gbogbo eru ni afin oba Oyo ti sin Oba meta.
O ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí ẹrú láti ọdún 1945 títí di àkókò yìí
Lasisi ti sìn fún ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin.
- 'Aláàfin ti rí ikú rẹ̀ ṣáájú ọjọ́ tó wàjà, ó sọ̀rọ̀ sílẹ̀ kó tó kú'
- Wo àwọn òrékelẹ́wà tí yóò ṣe opó lẹ́yìn Aláàfin Oba Adeyemi tó papòdà
- Ẹ yé fi ìpapòdà àwọn lọ́balọ́ba ìpínlẹ̀ Oyo kọmi lọ́rùn - Gómìnà Seyi Makinde
- "Kòríkòsùn lèmi àti Alaafin ṣùgbọ́n kété táwọn kan kẹ́ẹ́fín pé èmi láàyò ni gbogbo nǹkan dojúrú." Badirat Ajoke, olorì tẹ́lẹ̀ kẹ́dùn Alaafin
- Wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn olòrì Alaafin Adeyemi àtàwọn tó bá fẹ́ fẹ́ wọn
- Mo ti gbà báyìí pé ohun gbogbo tó n dán kọ́ ni wúrà - Olori Badirat Adeyemi
Kini a mọ́ nipa Lasisi Morenikeji?
Ohun ti BBC ri kojọ nipa Lasisi ni pe baba agba yii ti lè ni ẹni ọgọ́fà ọdún bo tilè jẹ wí pé a ko tii le fidi ọjọ ori rẹ ni pato mulẹ lasiko ti a n kọ iroyin yii.
Sugbon Lasisi ni wọn n pe ni Baba Kekere laafin Oyo.
Awọn Alaafin wo ni Lasisi ti ba ṣisẹ ni Aafin Oyo?
Baba Kekere Aafin Oyo ni ọpọ maa n pe Lasisi Morenikeji.
O ti ba Oba Adeniran Adeyemi keji ṣiṣẹ laarin ọdun 1945 si ọdun 1956
Bakan naa ni Lasisi ba Oba Gbadegeshin Ladigbolu keji ṣiṣẹ laarin ọdun 1956 si ọdun 1968 sise.
Leyin naa lo tun jẹ olori gbogbo ẹru ni aafin ni asiko Oba Lamidi Adeyemi keta laarin ọdun 1970 si ọdun 2022.
- Wo awọn iroyin manigbagbe to waye ni ọsẹ yii
- Àwọn jàǹdùkú sọ àjọ̀dún Amole di 'ọdún olè jíjà' nílùú Akure
- Àwọn oúnjẹ ilẹ̀ Yorùbá ní à ń kọ nínú Akọ́mọlédè àti Àṣà lónìí
- Mọ̀ sí i nípa Oba Yesufu Asanike, Olubadan tí kìí fi ọ̀rọ̀ sí abẹ́ ahọ́n sọ kódà níwájú sọ́jà
- Ṣé ìwọ mọ ìtàn Ibadan àti ìgbín mẹ́rin? ipá wo ni Abuké àti Àfín kó nínú ìtàn Ibadan?
- Wo àwọn ǹkan tí o kò mọ̀ nípa Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò tó wàjà

Iru iwa wo ni Lasisi ni l'Aafin Oyo?
Lasisi Baba Kekere ni ọpọ ni aafin Oyo sapejuwe gẹgẹ bi oniwa tutu eeyan
Opọ sọ pe onirẹle ti awọn olugbe aafin maa n finu tan ni Lasisi jẹ.
Ati pe nitori pe kii ṣe ẹni to tobi tabi sanra, ọpọ kii tete mọ nipa rẹ ni eyi to mu orukọ inagijẹ Baba Kekere fun un.
Wọn ni Baba kekere kii binu nitori pe o gab pe, agba ti ko binu ni ọmọ rẹ n pọ.
Wọn ni pe ko si ẹni to le sọ ọjọ ori Lasisi ni pato ṣugbọn ọpọlọ rẹ kun fun imó itan aafin ati awọn ori ade gbogbo ni Oyo.
Iwadii BBC fihan pe Lasisi ti le ni ọgọrun un ọdun.
























