Alaafin of Oyo dead: 'Aláàfin ti rí ikú rẹ̀ ṣáájú ọjọ́ tó wàjà, ó sọ̀rọ̀ sílẹ̀ kó tó kú'

Oríṣun àwòrán, others
Alaafin Adeyemi III ti mọ nipa iku rẹ, ṣaaju ọjọ to ku.
Ẹnikan to jẹ ara awọn oṣiṣẹ ni aafin Oyo lo sọ eyi pe, Alaafin sọ fun ara ile rẹ ni ọsẹ meji sẹyin pe, oun ri baba oun loju ala.
O si sọ pe ki oun ma a bọ, nitori pe eyi toun ṣe laye ti to.
Arabinrin naa to sọ ọrọ yii fun BBC Yoruba ninu ifọrọwanilẹnuwo l'aafin sọ pe "ibẹru gba ọkan gbogbo wa nigba to sọrọ yii fun wa."
- Nínú àwòràn, wo ìgbà ayé Aláafin Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi kẹta tó lọ bá àwọn Baba Ńlá rẹ̀
- Wo Alàáfin 43 tó jẹ́ láti ìgbà ìwásẹ̀ ṣáajú Lamide Adeyemi tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wàjà
- Aláàfin àti Ọba ilẹ̀ Yorùbá márùn-ún mìí tó wàjà láàrin oṣù márùn-ùn péré
- Wo ohun tó yẹ kóo mọ̀ nípa ìgbésí ayé Ọba Ajagungbade Ogbomosho tó wàjà
Arabinrin naa ti ko sọ orukọ rẹ fun akọroyin sọ pe Alaafin Atanda, lọ ọ ba awọn baba rẹ ṣere ni, kii ṣe pe o ku.
"Ibi ti ẹru Alaafin Atanda ti ba mi ni pe ọjọ Jakuta, to jẹ ọjọ Sango, ni Alaafin papoda."
"Ọdọ lo wa nigba to jọba, o si lo ipo ninu ọla, alaafia, ati ẹmi gigun."
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Orumọju ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin, ni Alaafin Olayiwola Atanda Adeyemi III gbesẹ, lẹyin aisan ranpẹ.
Wọn si ti sin oku rẹ si Baara nilu Oyo, nibi to jẹ ilẹ isinku fun awọn alaafin.
Alẹ ọjọ Abamẹta si oru ọjọ Aiku, ni isinku naa waye, lẹyin ti awọn Onisango ṣe oro ati etutu fun ninu gbọngan aafin.
Ṣaaju eto isinku naa, awọn alaafa kirun si lara ni ọsan nilana ẹsin Islam.
Bakan naa, ni awọn oloro kede konile-o-gbele fun araalu, bẹrẹ lati aago mẹjọ alẹ.













