Postpartum vaginal steaming: Njẹ anfààní wà nínú fífi omi gbóná jó ojú ara lẹ́yìn ìbímọ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin ti obinrin ba bimọ tan, ibeere nla ti ọpọ a maa beere ni pe se ile ọmọ obinrin ti iyipada ti de ba, njẹ o le sun ki pada si bo se wa tẹlẹ?
Gbogbo obinrin ni eleyi maa n sẹlẹ si nitori bi eledua ti se sẹda ara wa nuu ni.
Ni idahun si ibeere yi, lootọ a maa sun pada sipo.
Amọ arabinrin Veronica Azeru sọ pe o ni awọn nkan ti eeyan le se ti yoo mu ki ara obinrin paapa ile ọmọ pada si bo se wa tẹlẹ lẹyin to ba bimọ tan.
Olugbẹbi yi ni lootọ lawọn nkan maa n sẹlẹ si awọn to ba pade inira lasiko igbẹbi tori naa si lawọn fi n se itọju fun wọn eyi to yatọ.
Lara nkan ti wọn maa n se fawọn obinrin to sẹsẹ bimọ tan ni pe wọn a maa ni ki wọn joko lori omi gbigbona ki wọn baa le gba ooru gnbigbona yi si abẹ wọn.
Bakan naa wọn a maa ni ki wọn mu ọbẹ alata,pepper soup lawọn agbegbe kan ni Naijiria.
Azeru sọ pe"Irinaj o ni oyun jẹ bẹẹ lo si maa n tẹsiwaju pẹlu itọju lẹyin ibimọ.Nkan to kan yatọ ni pe asiko ti onikaluku maa n lo yatọ si ara wọn''
Anfaani lilo omi gbigbona
Lẹyin ibimọ, ọpọ obinrin a maa ri inira.
Sugbọn irora yi a maa yatọ laarin awọn to bimọ lalae se isẹ abẹ ati awọn to se isẹ abẹ.
Monica Azeru to n sisẹ olugbẹbi ni Port Harcourt, sọ pe idi ree tawọn fi n seto itọju olomigbona.
''Omi to lọwọrọ yi maa n mu ki awọn nkankan to ba si sẹku lara obinrin jade lọwọ ẹrọ''.
O ni lootọ lawọn oogun oyinbo to le se isẹ yi wa sugbọn awọn obinrin nifẹ si ilana olomi gbona yi.
''Ilana yi maa n jẹ ki ẹjẹ jade daada.A maa jẹ ki ara bọ sipo pada kiakia.''
"Omi to lọwọrọ ati pepper soup lẹyin ibimọ maa n jẹ ki ile ọmọ sunki ti a si tun maa fọ ara abiyamọ''
Oogun lilo dara ṣa?
Dokita Rosemary Ogu,onimọ itọju aboyun sọ pe o dara ki alaboyun gba imọran lọdọ awọn onimọ.
O tun fero ọkan rẹ han lori bi awọn obinrin se le sesi ko kokoro aifojuri ti wọn ko ba seto itọju omi gbona daada.
Ọjọgbọn Ogu ni : " Bi wọn ba lo omi gbona lẹyin ẹbi ni nkan bi ogun si ọgbọn isẹju ko buru sugbọn ko yẹ ki omi naa gbona ju.''
Lori wiwọ ikun abiyamọ o ni''A gba awọn obinrin ni imọran ki wọn jawọ nidi fifi omi gbona wọ ikun saaju ati lẹyin ibimọ,isesi ti ko dara to ni o si yẹ ki wọn jawọ nibẹ''
Onimọ yi tun gba awọn obinrin ni imọran lati ma se maa lọ si ọdọ awọn agbẹbi abẹle nitori ofin orileede Naijiria ko faaye gba wọn.
"Nkan ti wọn n se lodi si ofin isẹ wọn si ti sokunfa iku ọpọ obinrin''
"Wọn kii se akọsẹmọsẹ bẹẹ wọn ko gbẹkọ nipa itọju alaboyun ni pataki bi nkan ba fẹ yiwọ''

















