Merry Home Hotels: Ìjọba gbé ilẹ ìtura tì pa lẹ́yìn tí àwọn oníbárà rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ń pòórá

Merry Home Hotels

Oríṣun àwòrán, Courage Ogbonna

Ijọba ipinlẹ Abia ti gbe agadagodo sẹnu ọna ile itura Merry Home Hotels lẹyin ti onibara ile itura naa kan ku, ti awọn mii si di awati.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ti gbe oku obinrin kan jade nile itura naa, wọn ṣi n wa awọn eeyan mii to lọ sun nibẹ.

Kọmiṣọna fun eto iroyin ni Abia, Eze Chikamnayo lo fidi ọrọ naa mulẹ fun awọn akọroyin.

O ṣalaye pe o ṣe pataki lati ti ile itura ọhun pa lẹyin ti awọn eeyan to n ba ile itura naa dowopọ berẹ si n poora lojiji.

Kọmiṣọna naa ṣalaye pe aipẹ yii ni obinrin kan lọ sile itura naa, pẹlu ọmọ jojolo lọwọ atawọn okunrin meji mii, gẹgẹ bii ẹrọ ayaworan CCTV ṣe ṣafihan rẹ.

O ni awọn okunrin meji naa fi ile tura ọhun silẹ pẹlu ọmọ jojolo naa, amọ obinrin naa ko ba wọn jade.

Lasiko ti awọn oṣisẹ ile itura naa lọ ja ilẹkun yara ti wọn gba, wọn ba oku obinrin naa nibẹ ti wọn ti ge awọn ẹya ara rẹ kan lọ.

Chikamnayo sọ pe ijọba ipinlẹ Abia ti gbọ irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ nile itura ọhun, paapaa lagbegbe ibi ti 'swimming pool' ile itura naa wa.

Àkọlé fídíò, Idiroko border open:Àwọn Egun ló yẹ k'Ọ́lọ́pàá máà gba owó ibodè lọ́wọ́ wọn àmọ́...

O ni ko si ijọba ti yoo la oju rẹ silẹ ki awọn kọlọrọsi kan maa wu iwa ọdaran ni ipinlẹ oun.

Kọmiṣọna naa sọ pe awọn to lọwọ ninu iṣẹlẹ iku oloogbe naa ninu ile itura ọhun ni ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ, ile itura naa yoo si wa ni titi pa lọwọ yii.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn ko ni gba awọn ọdaran laye lati fi ipinlẹ naa ṣe ibuba.

O kilọ fun awọn to ni ile itura lati bojuto irufẹ ile itura bẹẹ, bi bẹẹ kọ awọn yoo maa gbe ile itura to ba tapa si ofin ti pa.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinẹ ọhun ti sọ pe oku obinrin naa ti wa nile igbokupamọsi fun ayẹwo, gbogbo awọn to si lọwọ ninu iku rẹ ko ni lọ lai foju wina ofin.

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'