Sister Kate: Mò ń wọ ìjáàbù kí àwọn okùnrin má bà ṣìnà ìjọba ọ̀run nítorí bẹ̀bẹ̀rẹ́ ìdí mi

Sis Kate

Oríṣun àwòrán, Sis Kate

Ajihinrere obinrin kan, Sister Catherine, ti ọpọ eeyan mọ si Sister kate ti sọrọ lori idi to ṣe n wọ ijaabu bo tilẹ jẹ pe kii ṣe Musulumi.

Obinrin naa sọ pe oun bẹrẹ si n wọ ijaabu nitori awọn aṣọ ti oun maa n wọ tẹlẹ maa n gbe bẹbẹrẹ idi oun sita, o si le dena awọn okunrin lati wọ ijọba ọrun.

Gẹgẹ bii oun to sọ, ọpọ eeyan lo ti maa n sọ fun oun tẹlẹ pe irufẹ awọn aṣọ ti oun maa n wọ ko bojumu gẹgẹ bii ọmọlẹyin Kristi, nitori o maa n gbe ara oun sita, o si le ṣe idena fun okunrin lọdọ Ọlọrun.

Àkọlé fídíò, Idiroko border open:Àwọn Egun ló yẹ k'Ọ́lọ́pàá máà gba owó ibodè lọ́wọ́ wọn àmọ́...

Sister Kate ni ijaabu kii ṣe aṣọ awọn Musulumi gẹgẹ bii ọpọ eeyan ṣe gbagbọ, ṣubọn aṣọ awọn Kristẹni ti awọn Musulumi kan n yalo ni nitori o bojumu.

Ninu fidio kan loju opo Youtube rẹ lo ti fi ọrọ naa lede.

Àkọlé fídíò, Basorun Akinade Ayoola Yusuf: Ìsìnkú Aláàfin Oyo àti Ooni Ile Ife yàtọ̀ nílẹ̀ Oodua

Mi o ki n ṣe Musulumi

Ajihinrere obrinin naa ni "Lati igba ti mo ti n wọ ijaabu ni ọpọ eeeyan ti maa n pe mi ni Musulumi, amọ mi o kii ṣe Musulumi."

"Lakọkọ, ọmọlẹyin Kristi ni mi, mo si ti di atunbi."

"Iwe mimọ sọ ninu iwe Mathew 5:28 pe Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obìnrin kan ní ìwòkuwò, ti bà ṣe panṣágà nínú ọkàn rẹ̀."

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'

Arabinrin naa sọ siwaju si pe ni gbogbo igba ti oun ba n waasu ni awọn okunrin maa wo ibadi oun, eyii ti kii jẹ ki wọn tẹti si ọrọ Ọlọrun ti oun n ba wọn sọ.

O ni lọpọ igba ni awọn okunrin ma n sọ pe ibadi oun n da wọn lọrun.

Sister Kate tẹsiwaju pe "Koda, Ọlọrun ti ba mi sọrọ loju ala mi pe ki n dẹkun ati maa da awọn okunrin lọrun, idi ree ti mo fi n wọ ijaabu."

Lẹyin naa lo gba awọn obinrin to maa n wọ aṣọ ati ṣokoto to maa n ṣi ara wọn silẹ nimọran lati dẹkun ṣiṣe bẹẹ.

Bo tilẹ jẹ pe ko sọ pe ki awọn obinrin maa wọ ijaabu, o ni o yẹ ki wọn maa wọ awọn aṣọ ti yoo bo aṣiri ara wọn.

Àkọlé fídíò, Kò sí ńkan ti ọkùnrin ń ṣe tí obìnrin kò le ṣe- Afusat Adeniyi tó ń tún 'Pumping Machine'