Idiroko border open: Àwọn Ègùn ló yẹ k'Ọ́lọ́pàá máà gba owó ibodè lọ́wọ́ wọn àmọ́...
Lẹyin o le ni ọdun meji ti ijọba ti ti awọn ibode Najiria pa latari iṣi wọle awọn ọja ilẹ okeere ti wọn n ṣe lọna aitọ, wọn ti wa pada ṣi awọn ẹnu ibode ọhun amọ...
Awọn ibode naa ni Idroko (ipinlẹ Ogun); Ibode Jibiya ni Katsina; Ibode Kamba ni Kebbi ati Ibode Ikom ni Cross River.
Bi aṣẹ yii ti jade ti wọ́n si ti ṣi gbogbo wọn pada, BBC Yoruba lọ si adugbo ọkan lara awọn ibode naa eyi to wa ni ipinlẹ Ogun amọ ọrọ taa gbọ lẹnu awọn olugbe ibẹ kọja afẹnusọ.
Lara awọn nkan ti wọn maa n gba ọna ẹburu awọn ibode yii ko wọle ni irẹsi ti wọn ti yọrọ, awọn nkan jijẹ ti inu ẹrọ amunututu bii ẹran ati bẹẹ lọ, awọn ọkọ ayọkẹlẹ Tokunbo, oogun ti ko ni iwe aṣẹ, awọn nkan ijagun kekeke atawọn nkan ọgbin ni wọn ko wọ inu Naijiria ti ijọba ṣe gbe ote le gbogbo ẹ.
Ki lawọn olugbe ati oṣiṣẹ ibode Idiroko sọ?
Nigba ti BBC awọn Olugbe Idiroko atawọn to n ṣiṣẹ nibẹ,ọkan lara wọn, Alhaji Tajudeen ni awọn o kuku ni iṣẹ mii ju ohun ti wọn mọ wọn lọ amọ latigba ti wọn ti ti awọn ẹnu ibode ọhun.
“Ipa buruku lo ko kii ṣe rere o, awọn eeyan ku pupọ pupọ, ẹlomii wa nileewosan”.
O ṣalaye pe lara awọn ti wọn fi panpẹ ofin mu ti ẹru rẹ wa ṣi wa ninu mọto, o ni ẹru naa jẹra sibẹ ni ati pe arun rọpa rọsẹ lo pada ṣekupa arakunrin naa.
Ẹlomiran kẹnu bọ ọ̀rọ̀ o ni: “bi wọn ko ba ti le ṣi ileepo to wa ni tosi ibode naa, ki ijọba tabi oloṣelu ma reti ibo kankan lọdọ awọ”.

