Eid-el-fitr: Lẹ́yìn tí wọ́n rí òṣùpá, Sultan kéde ọjọ́ Ajé gẹ̀gẹ́ bíi ọjọ́ ọdún ìtúnu àwẹ̀

Muhammad Sa'ad Abubakar

Oríṣun àwòrán, @MaryNoelBerje

Sultan ti ilu Sokoto, to tun jẹ Aarẹ igbimọ to n ri si ọrọ awọn Musulumi ni Naijiria, Muhammad Sa'ad Abubakar, ti kede ọjọ Aje, ọjọ keji, oṣu Karun un, ọdun 2022, gẹgẹ bii ọjọ ọdun itunu awẹ ni Naijiria.

Sultan lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan, eyii ti Ọjọgbọn Sambo Junaidu, to jẹ alaga igibimọ to n ri si ọrọ ẹsin ni Sokoto buwọlu.

O ni igbimọ naa ko ri oṣupa ṣaaju kaakiri Naijiria, o si kede pe ọjọ Aiku ni yoo jẹ ọgbọn ọjọ oṣu Ramadan, iyẹn 1443AH.

Sultan ni oun ti gba iroyin wọn wọle, o si kede ọjọ Aje, ọjọ keji, oṣu Karun un, ọdun 2022 gẹgẹ bii ọjọ kinni Shawwal 1443AH, tii ṣe ọjọ ọdun itunu awẹ.

Lẹyin naa lo ba gbogbo awọn Musulumi ni Naijiria yọ, to si tun gbadura ibukun Ọlọrun fun wọn.

O tun rọ awọn Musulumi lati tẹsiwaju lati maa gbadura fun alaafia ati itẹsiwaju Naijiria.

Àkọlé fídíò, Idiroko border open:Àwọn Egun ló yẹ k'Ọ́lọ́pàá máà gba owó ibodè lọ́wọ́ wọn àmọ́...

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?

Ramadan n tẹ̀síwájú lẹyìn tí oṣù kò fojú hàn ní Nàìjíríà àti Sáúdí

Sultan ti ilu Sokoto

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ibẹrẹ ati opin awẹ Ramadan jẹ nkan ti ọpọ amaa foju sọna si.

Awẹ tọdun yi ti bẹrẹ ṣugbọn o ṣi ku diẹ ti yoo pari nitori awọn alaṣẹ musulumi ni Naijiria ati Saudi lawọn ko ri oṣu tuntun.

Ọsu tuntun yi to jẹ ti oṣu Shawwal ni onka oṣu oju ọrun musulumi lo jẹ atọna pe awẹ Ramadan ti pari.

Àkọlé fídíò, 'Láti kékeré mo ti ní ọjọ́ kan lèmi náà ọ́ kọ́ Mọ́sálásí kékeré bíi àwọn bàbá wa'

Kaakiri loju opo ayelujara lawọn eeyan ti foju sọna de iroyin pe wọn yoo ri oṣu tuntun yi.

Koda igbimọ to gajulọ eleyi to n ṣakoso eto ẹsin Islam ti ni kawọn eeyan bẹrẹ si ni wa oṣu yi ṣaaju asiko yi.

Sultan ilu Sokoto,Alhaji Muhammad Saád Abubakar, to jẹ olori musulumi Naijiria lo fi ikede yi sita gba tẹnu igbimọ to n wa oṣu.

Amọ nigba ti yoo fi di irọlẹ mọ aṣalẹ ọjọ Abamẹta ikede jade pe wọn ko ti ri oṣu tuntun yi.

Aworan ikede oju opo Facebook nipa oṣu tuntun

Oríṣun àwòrán, Facebook/nsciamoonsightingcommittee

Naijiria nikan kọ ni iroyin bayi ti jade.

Lorileede Saudi awọn igbimọ to n wa oṣu tuntun Ramadan nibẹ naa ti sọ pe toun ti bi oju ọjọ ṣe mọlẹ kedere awọn ko ri oṣu tuntun.

Eleyi waye lẹyin ti wọn ran awọn oniṣẹ lati lo irinṣẹ igbalode fi wa oṣu tuntun yi.

Aworan ikede osu tuntun ni Saudi

Oríṣun àwòrán, Haramain Sharifain

Ki wa ni airi oṣu yi tunmọ si fawọn alaawẹ

Ni ilana ẹsin Islaamu bi wọn ba ti wa oṣu Ramadan ti wọn ko ri, ohun to kan ni pe ki wọn ka oṣu Ramdan ko pe ọgbọn.

Loni tii ṣe ọgbọnjọ oṣu Kẹrin to ṣe deede ọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu Ramadan ni wọn wa oṣu ti wọn ko ri.

Aworan irinṣẹ ti wọn fi n wo oṣu oju ọrun

Oríṣun àwòrán, HARAMAIN SHARIFAIN

Ko si ṣiṣe kan ko si aiṣe bayi ju pe ki awọn musulumi gba awẹ pe ọgbọn ki wọn si tunu ni ọjọ kini oṣu tuntun Shawwal.

Eyi tunmọ si pe ọjọ ọdun itunu awẹ ni Naijiria yoo maa jẹ ọjọ Keji oṣu Karun un ọdun 2022 tii ṣe ọjọ Aje.

When be Eid Fitr 2022? Moon no show for Saudi Arabia, Eid go be on Monday May 2

Oríṣun àwòrán, Haramain Sharifain