Abeokuta car theft: Wòlíì Olubọla ni wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó jí ọkọ̀ ọmọ ijọ̀ lọ ní Abeokuta

oko ti won ji wa lo

Ọ̀rọ̀ n bọ̀rọ̀ bọ̀ lori ọkọ ayọkele ọmọ ijo Celestial kan ni Abeokuta ti Wolii dawati pẹlu ọkọ rẹ.

Kayeefi nla patapata ni ọrọ ọkunrin kan lori bi wọn ṣe fẹsun kan an wi pe o ji mọto onimọto gbe salọ, ti ko si tii sẹni to le sọ pato ibi to wa titi di asiko yii.

Okunrin naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Olubọla Fakrogha ṣi n jẹ titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii,

Kini ohun ti BBC fidiẹ mulẹ pe o ṣẹlẹ gangan?

BBC Yoruba gbọ pe Olubọla ni olori ijọ Sẹlẹ, iyẹn Celestial Church of Christ 'Gbogbo Aiye Parish' to wa niluu Abẹokuta, ti wọn si lo ti pẹ ninu ijọ naa.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe lọjọ Aje, ọsẹ yii ni Olubọla pe ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Ọmọkayọde Adekọya lori foonu wi pe oun riran nla kan to banilẹru si i.

Ati pe oun fẹẹ ṣe awọn eto kan fun un, ti yoo jẹ ko bọ ninu iṣoro to n dojukọ lọwọlọwọ, ti awọn mejeeji si fi ipade si ọjọ kẹji, to jẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee.

Àkọlé fídíò, Basorun Akinade Ayoola Yusuf: Ìsìnkú Aláàfin Oyo àti Ooni Ile Ife yàtọ̀ nílẹ̀ Oodua

Bawo ni wọn ṣe jọ jẹ si ara wọn?

Ijọ Sẹlẹ lawọn mejeeji jọ n lọ, bo tilẹ jẹ ọtọọtọ ni ẹka ijọ wọn, ti wọn si ti mọ ara wọn tipẹtipẹ.

Agbegbe Adatan ni Adekọya ti lọ fi mọto gbe Olubọla lọjọ naa, ti wọn si jọ lọ si odo kan to wa lagbegbe Agbelọba si Akin-Olugbade niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.

Nibẹ ni wọn ti lọ wẹ iwẹ iṣẹgun. Bi wọn ṣe debẹ la gbọ pe Olubọla f'ọgbọn gba kọkọrọ mọto ọhun, iyẹn Toyota Corolla ti nọmba idanimọ rẹ jẹ EKY 498 GP lọwọ wi pe ko ma ba a jabọ sodo.

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'

Nigba wo ni ọrọ wa ba ẹyin yọ?

Igba ti wọn ni Adekọya wẹ tan, lo pada lati lọ sibi ti mọto wa, ṣugbọn to jẹ iyalẹnu wi pe mọto ati Wolii naa ti poora.

Wọn tiẹ ni Adekọya kọkọ ro pe ṣe lo fi mọto naa lọ ran nnkan, ṣugbọn lẹyin wakati meji ti ko ri i, lo to fibinu kuro nibẹ.

oko ti won ji wa lo

Kini o tun wa ṣẹlẹ?

BBC Yoruba tun gbọ pe tilẹ ọjọ naa fi ṣu ni wọn fi pe nọmba foonu Adekọya mejeeji to wa ninu mọto naa, ati nọmba Olubọla, ṣugbọn ti ko gbe e.

Ọjọ keji ni wọn to ṣẹṣẹ lọ fi to ileeṣẹ ọlọpaa ti ẹkun Ibara niluu Abẹokuta leti, ti a si gbọ pe latigba naa ni iwadii ti bẹrẹ.

Wọn ni igba ti Olubọla yoo kọkọ gbe foonu, ṣe lo sọ pe agbegbe Apẹtẹ loun wa niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, nibi ti mọto naa bajẹ si.

Ati pe toun ba ti tun un ṣe tan, oun yoo gbe e pada fun ẹni to ni i, ṣugbọn ti wọn ko ti i ri titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.

oko ti won ji wa lo

Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?

Nigba Adekọya n ṣalaye ọrọ naa fun BBC Yoruba, Ọgbẹni Adekọya to ni mọto naa sọ pe oun ko ti i gbadun ara oun latigba tiṣẹlẹ naa ti waye, nitori pe ẹfọri nla lo n jẹ f'oun.

O ni: "O ti pẹ ti a ti jọ mọra, bẹẹ lo si ti pẹ ti a ti jọ sọrọ gbẹyin.

Mi o mọ ibi to n gbe, ṣọọṣi to n lọ ni mo ti mọ ọn.

Ṣa deede lo pe mi lọjọ Ajẹ, wi pe oun ri awọn iṣipaya kan si mi, wi pe ka pade lọjọ keji. O ni ki n wa pade oun lati lọ ṣe iṣẹ itusilẹ fun mi.

"Lotitọ ni mo n la awọn iṣoro kan kọja, gẹgẹ bi ọmọ ijọ Sẹlẹ ti emi naa jẹ, igbagbọ wa ni pe ẹnikẹni ni Ọlọrun le ran lati jiṣẹ bayii fun wa.

Àkọlé fídíò, Easter Celebration: Olórí Celestial ní Krìstíẹ́nì kò yẹ kó fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú àjíǹde

"Nigba ti a de odo, mo gbe mọto mi sẹgbẹ kan, mo ko awọn foonu mi mejeeji sinu mọto, mo si tilẹkun mọ ọn.

Bi mo ṣe fẹẹ wọnu odo naa lo sọ pe ki n mu kọkọrọ mọto mi wa, ko ma ba a jabọ s'odo. Mi o ro o lẹẹmeji ki n to mu kọkọrọ naa fun un. Mi o mọ pe o ni iṣẹ buruku to fẹẹ ṣe.

"Bi mo ṣe wẹ tan, ti mo pada sibi ti mo gbe mọto si, ni mi o ba mọto.

Mo kọkọ ro pe boya o lọ ran nnkan ni, ṣugbọn lẹyin wakati meji ti mi o ri, ni mo kuro nibẹ, ti mo si lọ si ṣọọṣi ti mo ti mọ ọn ri.

Igba ti mo debẹ ni wọn sọ fun mi pe o ti le ni ọsẹ meji ti wọn ti tilẹkun ṣọọṣi naa pa.

Àkọlé fídíò, Alfa Sule: Ọmọdé tí mò kọ́ ní lẹ́sìnì ló fún mi ní ìmísí àgbékalẹ̀ eré oníjó

Se Wolii ti da ọkọ pada bayii tabi bẹ́ẹ̀kọ́?

Adekola salaye fun akoroyin BBC pe: "Igba ti a ko ri, la bẹrẹ sii fi fọto rẹ, ati nnkan to ṣe ranṣẹ kaakiri ori ayelujara.

Igba to ri nnkan ti a ṣe yii, lo ṣẹṣẹ pe wi pe kii ṣe pe ṣe loun ji mọto naa gbe, bi ko ṣe pe oun kan ya a lo lasan ni.

O si bẹbẹ pe oun maa da a pada lọjọ naa. Mi o ri mọ, ṣe lo pa foonu rẹ. Foonu mi mejeeji lo wa ninu mọto.

Àkọlé fídíò, Wọ́n jí pè mi láàrọ̀ pé ọmọ mi bímọ, ó dákú àmọ́ bí mo ṣe débẹ̀, àt'òkú ọmọ mi, àt'òkú

Kini wolii da pada bayii?

Ọjọ Ẹti, ana ni ẹnikan pe wa wi pe ka ṣe suuru pẹlu ẹ nitori pe o maa gbe mọto naa pada wa.

A ko ri, bẹẹ ni gbogbo foonu rẹ ko lọ. Igba to di irọlẹ ni ẹnikan pe mi wi pe mo ni mẹseeji ti wọn fi ranṣẹ si mi, nigba ti mo debẹ, lo jẹ pe ọkan lara awọn foonu mi, pọọsi ati kọkọrọ ile mi lo fi ranṣẹ.

Àkọlé fídíò, Alaafin Oyo's burial: Oba Lamidi Adeymi darapọ̀ mọ́ àwọn àgbà ìṣáájú, ọ̀pọ̀ ń dárò Kábíèsí

"Foonu mi to wa lọwọ ẹ ni mo fi n ṣiṣẹ aje, kaadi ATM mi pẹlu ọpọlọpọ iwe ti mo fi n ṣiṣẹ lo wa ninu mọto mi.

Nnkan ko lọ deede nitori pe gbogbo awọn to le ran mi lọwọ ni ẹrọ ibanisọrọ wọn wa lori foonu to gbe salọ.

Àkọlé fídíò, Ọdún 20 ni ìran ti jáde pé kí n di ààrẹ!'Wàláhì láàrín ọdún kan péré tí mo bá dé Aso Rock, ẹ wo ǹkan tí ...'

Kini Ijo Celestial ti ṣe si ọrọ yii?

"Ijọ Sẹlẹ naa ti dide fun iranlọwọ lori bi wọn ṣe maa ri i.

Ṣe lo n sọrọ bi ẹni pe oun ya mọto naa ni, ṣugbọn to jẹ pe irọ lo n pa. Lotitọ mo nigbagbọ pe mo maa ri mọto mi gba pada."

Agbenusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi nigba to n sọrọ, jẹ ko ye wa pe oun yoo ṣe iwadii rẹ lati mọ nipa ẹ daadaa.