Sleeping with Dog Video: Bá ajá tàbí ẹranko mìíràn ló pọ̀ kò sí fí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlá jura

Opin ọsẹ taa wa yi opin ọsẹ alara gbayida ni. Ko si syin bi iroyin kan ṣe gbode kaakiri oju opo ayelujara to mu kawọn eeyan maa sọrọ nipa ibalopọ pẹlu ẹranko.
Iroyin yi jẹyọ nigba tawọn fọnran fidio kan bẹr si ni foju han nibi tawọn obinrin kan ti n ni ibalopọ pẹlu aja.
BBC ko ribi fidi awọn fidio yi mulẹ ṣugbọn ibi taa gba wọ inu awuyewuye yi ko ṣẹyin fidio mii ti arabinrin kan ti ni ko si ohun to buru boun ba ba aja ni iblaopọ.
- À ń wá àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ajá, ẹ kàn sí wa tí ẹ bá mọ̀ wọ́n - ọlọ́pàá Naijiria
- Owó ńlá ti fẹ́ ṣe mí léṣe ní London o! Ẹ wá wo bí mo ṣe ń jayé orí mi bíi skódà - Portable
- Wo ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ fún àgbà nọ́ọ̀sì tó ta ọmọ ọdún mẹ́fà ní N200,000
- Ilé ẹjọ jú akọwe kọotù tẹ́lẹ̀ri sẹwọ̀n ọdun márùn
- Fídíò ìbálòpọ̀ tó lu jáde nípa olórin Tiwa Savage, èsì ọlọ́rọ̀ gangan rèé
- Wò ó ọ̀nà láti mú ara rẹ dé ibi tó ga jùlọ nínú ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìlànà Tantra
Fọnran fidio yi to wa loju opo ayelujara TikTok ṣafihan arabirin naa torukọ apejẹ rẹ ni TikTok n jẹ @she.vanesa.
Fido naa ti ko pe iṣẹju kan la ri bi arabinrin yi ko ṣe bikita to si n sọ pe ''aja ni mo basun mi o pa eeyan''
Ko darukọ ara rẹ, bẹ si ni ko fi ẹri kankan han pe oun ni ibalopọ pẹlu aja ju ọrọ to n sọ ninu fidio naa.
O ni ohun ko ko arun kankan nibi ibalopọ yi ati pe ki awọn eeyan sinmi ẹjọ nitori ''mo n gbadun owo naa''
O darukọ miliọnu kan le ẹgbẹrun lọna irinwo Naira to si n beere boya awọn to n sọrọ ti ri iru owo yi ri.
Ki ni ofin orileede Naijiria sọ nipa ibalopọ pẹlu ẹranko
Awuyewuye lori ọrọ yi pin si ọna to pọ.
Ninu rẹ la ti ri awọn to n sọ pe eemọ nla ni iru iṣẹlẹ yi jẹ ati pe o tọka si pe isalẹ ọrọ lẹgbin lawujọ taa wa yi.
Lọdọ awọn miran eleyi to jẹ ohun to kan wa ni iriwisi lori nkan ti ofin orileede Naijiria sọ nipa ibalopọ pẹlu ẹranko.
A kan si iwe ofin Naijiria labẹ abala to sọrọ nipa iwa to tako ijẹọmọluabi,(Offences against morality)
Gbagada gbagada lo wa labẹ isọri okoolenigba din mẹfa,214,eyi to sọr nipa ẹsọ to lodi si iṣẹdamọniyan.
Ohun ti ofin naa si sọ ni pe: ''ẹnikẹni to ba ni ibalopọ ni itako iṣẹdamọniyan pẹlu ẹranko tabi to gba ọkunrin laaye lati ni ibalopọ pẹlu ọkunrin tabi obinrin mi ni itako iṣẹda rẹ,o ti dẹṣẹ ni yẹn''
Ijiya ti ofin yi la kalẹ gẹgẹ bo ṣe wa labẹ ofin yi si ni ẹwọn ọdun mẹrinla.
Bakan naa ni ofin yi sọ pe ẹnikẹni to ba n gbero lati hu iru iwa yi, ẹwọn ọdun meje ni yoo fi gbara.
Koda iwe ofin ni awọn agbofinro le mu iru eeyan bẹẹ lalae ni iwe ipẹjọ taa mọ si warrant lede oloyinbo.
Igbesẹ wo lawọn agbofinro gbe lori iṣẹlẹ yi?
Titi di igba ta fi n se akojọpọ iroyin yi, a ko ti gburo eyikeyi ẹka agbofinro ijọba ko dasi ọrọ naa.
Ni eyti tii jẹ ootọ, a ko le fidi ibi ti fọnran fidio naa ti wa boya ni Naijiria nibi yi ni tabi ni ilẹ okeere.
Amọ bi nkan ti ṣe ri ati bi ofin ti ṣe laa kalẹ yi, ihuwasi nini ibalopọ pẹlu ẹranko ni Naijiria lodi si ofin Naijiria.




















