Dog bit Undergraduate's scrotum in Ondo: Ọlọ́paàá Ondo ní akẹ́kọ̀ọ́ fásitì AAUA tí 'Charlie', ajá gé jẹ ní kórópọ̀n ti kúrò nílé ìwòsàn

Oríṣun àwòrán, Sunshinetruthng.com
Ileeṣẹ ọẹọpaa ni ipinlẹ Ondo ti ṣalaye bi ọrọ ṣe jẹ pẹlu aja to di eyi le agbegbe nnkan smọkunrin akẹkọọ kan ni fasiti Adekunle Ajasin, AAUA, to wa nilu Akungba.
Gẹgẹ bi ohun ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ naa, Funmi Ọdunlami sọ, loots ni aja naa ge arakunrin naa jẹ ṣugbọn eyin rẹ kan ha koropọn akẹkọọ naa ni, wọn si ti gbe e lọ si ileewosan o si ti gba itọju.
Aja naa ti wọn ni wọn pe orukọ rẹ ni Charlie ni okiki rẹ kan pe o ti ge apa kan nnkan ọmọkunrin akẹkọ naa jẹ.
- Bí o bá ń fẹnukonu ju iye ìṣẹ́jú ààyá yìí lọ, wo adúrú kòkòrò tí wàá tí ibi ẹnu kò
- 'Bola Tinubu ńbọ̀ ní Nàìjíríà láìpẹ́, àmọ́ kò tíì dé'
- 'Eniola Badmus wọ pátá lọ sí ààfin Oba Elegushi, "ọ̀ín" kí ló burú níbẹ̀?'
- Ọbẹ̀ sọ̀ọ̀! Mọ síi nípa ìwé ìrìnà Visa f'áwọn awakọ̀ tírélà àti òṣìṣẹ́ ilé adìyẹ tí UK ń gbèrò
- Agbẹjọ́rò méjì yọ ẹ̀sẹ́ síra wọn níwájú adájọ ó ku ẹni tí yóò yanjú ọ̀rọ̀
- Wo èrò Afenifere àti Ilana Omo Oduduwa lórí ọ̀rọ̀ Alaafin pé kò s'ọ́nà nínú pínpín Nàìjíríà
Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, akẹkọọ ti ọrọ naa kan fẹ lọ kiọrẹ rẹ kan ni ileegbe awọn akẹkọọ kan ti wọn n pe ni Vanilla Villa ni lasiko ti aja naa fi kọlu.
Alukoro ileewe fasiti naa, Oluwafẹmi Adegbeyeni to fidi iroyin naa mulẹ fawọn akọroyin ni lọgan ti iṣẹlẹ naa ṣẹ ni wọn gbe lọ sileewosan fun itọju
Alukoro ọlọpaa ni apa oke itan akẹkọọ naa ni aja yii bu jẹ, ṣugbọn ipa rẹ lo kan koropọn akẹkọọ naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ni ẹya Pit-bull ni aja naa, Charlie si ni ẹni to nii sọọ.
O fi kun un pe ọdun meji ati oṣu mẹta ni aja naa, akẹkọọ oniwe kẹrin ẹkọ imọ nipa ẹranko, Animal Science kan ti orukọ rẹ n jẹ Abass Ọlagunju lo ni aja naa.
O ni Sadiq Ọpẹyẹmi ni orukọ akẹkọọ ti aja naa doju ija kọ ati pe Sadiq n sare lọ pade Abass to ni aja naa ni aja naa fi buu so to si gee jẹ.
Alukoro Ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo naa ni eyin aja naa ha koropọn akẹkọọ naa.














