UK temporary Visa scheme: wò bí o ṣé lè jẹ́ anfààní ìwé ìrìnà tí UK ń gbèrò f'áwọn awakọ̀

Obinrin to n wa tirela

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba ilẹ Gẹẹsi ti kede pe awọn setan lati seto iwe irina fawọn awakọ agbepo ati ounjẹ ẹgbẹrun marun un to ba fẹ siṣẹ fun osu mẹta titi di aisun ọdun Keresimesi.

Wọn ni omi anfaani yi yoo ṣan de ọdọ awọn ẹgbẹrun marun le diẹ mii to ba fẹ ṣiṣẹ ile adiyẹ.

Minisita feto irina, Grant Shapps sọ pe eyi yoo jẹ ki gbogbo eto wa ni ṣẹpẹ de asiko pọpọṣinṣin ọdun to n bọ.

Amọ ileeṣẹ idokoowo ilẹ Gẹẹsi fesi si igbesẹ yii ti wọn si ni o da bii ki ''eeyan kan omi woro kan lati fi pa ina nla to n jo''.

Awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ akẹru sọ pe aba yi ko le ran nkankan nitori ọdun ti wọle tan.

Amọ ṣa awọn akẹgbẹ wọn to n fi baalu ko ẹru ni ohun to da ni igbesẹ yi lọna ati tan iṣoro to de ba mimu ọja de ọdọ awọn to fẹ ra a.

Àkọlé fídíò, 'Mo ti gba kádàrá lórí bí Ọlọrun ṣe dá mi'
Ọwọngogo epo bẹntiroo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Igbaniwọle si iṣẹ yi fawọ́n awakọ ati oṣiṣẹ ile adiẹ yoo bẹrẹ ni oṣu Kẹwaa gẹgẹ bi awọn alaṣẹ ti ṣe sọ.

Awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ afi ẹru ko ọkọ ni ''awọn ileeṣẹ akẹru gbọdọ bẹrẹ si ni fi gbogbo iroyin to yẹ nipa Visa sọwọ bẹrẹ lati ọjọ Aje ki awọn baa le bẹrẹ eto igbanisiṣẹ.''

Ki ni o fa ipenija aisi awakọ nla ti o de ba UK ?

Lọwọ bayi ni ilẹ Gẹẹsi aisi awọn awakọ ọkọ nla ti mu ki awọn eeyan maa to fun epo nile epo ati pe ki wọn si maa tete ri awọn nkan ti wọn ba fẹ ra lasiko.

Ẹgbẹ awọn awakọ nla sọ pe o kere tan ẹgbẹrun lọna ọgọrun awakọ ni awọn ṣafẹku.

O ni wahala Covid-19 ati Brexit lo ṣokunfa airi awọn awakọ nla to de ba awọn yi.

Awọn alaṣẹ ati olori ileeṣẹ ti ni ki araalu ma foya wi pe ọwọngogo epo bẹntiroo ko si ni awọn ileeṣẹ ipọnpo.

Àkọlé fídíò, Romeo and Juliet padà di ìwé Akinola àti Arike ní èdè Yorùbá

Wọn ni ki araalu ma fi ibẹru bojo bẹrẹ si ni ra epo pamọ.

Amọ ṣa aisi awọn awakọ to yi ti mu ki awọn eeyan maa ri ounjẹ,ọja ati epo ra lasiko ti wọn ba fẹ.

Wọn sọ pe niṣe ni pupọ awọn eeyan n beere epo ti awọn ileepo diẹ kan si wa ni titi pa.

Ileeṣẹ BP sọ pe ogun ninu ẹgbẹrun kan le diẹ awọn ileepo awọn lo wa ni titi pa nitori aito awakọ yi kan awọn ibudo awọn bi aadọta si ọgọrun kan.

Ọkọ tirela