Afurasí tó kó òkú ajá, ejò, olóngìnní 183 sínú 'freezer' kó sí pańpẹ́ ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, SSPCA
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ilu Arizona ti mu arakunrin kan ti wọn ba oku awọn ẹranko ninu ẹrọ amunkan tutu taa mọ si freezer ni ile rẹ.
Ninu awọn ẹranko yi la ti ri aja, olongini ati awọn ẹyẹ naa.
Ni meni meji ti wọn ka iye awọn ẹranko wọnyi, ọlọpaa ni mẹtalelọgọsan lawọn ẹranko wọnyi jẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo gbajúmọ̀ amúlùúdùn mẹ́fà tó kú láàrin oṣù márùn-ún
- Ki ló mú bàbá fí ìbínú fọ orí ọmọ rẹ̀ oṣù kan mọlẹ?
- Wo ibi tí ọ̀rọ̀ dé dúró nípa ìjíròrò láàrin ìjọba àtàwọn ajínigbé èrò rélùwéè Kaduna
- Kí lò fa ariwo pe Wasiu Ayinde kó kúrò nílé fún Ropo, aya rẹ̀ torí pé obìnrin náà fọ léti torí obinrin miran?
- Ènìyàn 150 farapa bí ìkọlù tuntun ṣe bẹ̀rẹ̀ ní mọ́ṣáláṣí al-Aqsa
- Ooni Ilé Ife, Adeyeye Ogunwusi ti bí ọmọ míràn?
Arakunrin Michael Patrick Turland, ẹni ọdun mẹtalelogoji jẹwọ pe awọn kan ninu ẹranko yi wa laaye nigba toun sọ wọn sinu freezer.
Ileeṣẹ ọlọpaa ẹka to wa ni Mohave ni awọn ti fi ẹsun iṣekafẹranko onigun mẹrinlelaadọrun kan an.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Anita Mortensen sọ pe niṣe ni awọn aworan tawọn ri nibi iṣẹlẹ yi fọwọkan ni lẹmi.
O sọ fun BBC pe ''gẹgẹ bi ẹni to nifẹ si ẹranko,mo kan n sunkun ni bi mo ṣe n ri aworan naa''
O fikun pe awọn aworan yi buru pupọ debi pe awọn ko le ṣafihan rẹ faraalu.
O ni lọwọ bayii, awọn alaṣẹ n wa iyawo arakunrin Turland, arabinrin Brooklyn Beck.

Oríṣun àwòrán, MOHAVE COUNTY SHERIFF OFFICE
Bawo ni ọwọ ọlọpaa ṣe tẹ afurasi yi?
Yoruba bọ, wọn ni ko si ohun to pamọ labẹ ọrun.
Ọna ti ọwọ ṣe tẹ afurasi naa ni pe araadugbo kan lo ta ọlọpaa lolobo pe oun fi awọn ejo kan sọd arakunrin Turland ko ba oun si wn.
Amọ niṣe lo poora lẹyin oṣu meloo kan ti ko ri awọn ejo naa gba pada.
Arabinrin ti o kesi awọn ọlọpaa yi ni oun gba ipe lati ọdọ baba onile ti Turland ati iyawo rẹ n gbe pe wọn ti ko kuro ninu ile ti wọn n gbe ni Golden Valley.
- Àwọn ọlọ́pàá ti mú ọmọbìnrin tó parọ́ pé wọn jí òun gbé, fi ipá ba òun lòpọ̀
- Ọ̀dọ́ afurasí adigunjalè méjì, Oyewusi àti Anini tú àṣírí bí ìyá wọn ṣe jẹ́ agbodegba wọn
- Òṣìṣẹ́ INEC kàn ku méjì, dì àwáti bí agbébọn ṣe kọlù ibùdó iforukọsilẹ
- Seyi Makinde ti sọ Auxillary di nǹkan míì sígbòrò, ọlọ́pàá gbọdọ̀ mu - Olopoeyan
- Wo ẹ̀rọ ìgbàlódé tí o lé rì sínú ọwọ́ rẹ̀ láti má a san owó ọ̀jà láì lo káàdì ATM
O ni nigba ti onile wa lati wa tun ile naa ṣe lo ba oku awọn ẹranko ninu gareeji to fi mọ awọn ejo rẹ to ko fun Turland.
Nigba tawọn ọlọpaa de, wọn ba oku aja, ijapa,alangba,ejo ,ekute ati ehoro ninu awọn ẹranko to ti di pa sinu freezer.
Lẹyin ọjọ mẹwa, awọn ọlọpaa gburo pe arakunrin Turland ti pada si ile rẹ ti wn si wa lati mu.
Titi di akoko ta fi n ko iroyin yi jọ, awọn ọlọpaa ni awọn ko mọ ohun to mu ki arakunrin naa ko oku awọnẹranko yi si inu freezer.

















