Toyosi: Àwọn ọlọ́pàá ti mú ọmọbìnrin tó parọ́ pé àwọn jí òun gbé, fi ipá balòpọ̀

Omotoyosi

Oríṣun àwòrán, @_MISTERIOUSS/TWITTER

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti mu ọmọbinrin kan to parọ lori ayélujára pe, awọn kan ji oun gbe, ti wọn si fi ipa ba oun lopọ.

Owurọ Ọjọbọ ni Omotoyosi kede loju opo Twitter pe awọn eeyan kan ji oun gbe, ti wọn si ji oun gbe.

Koda, o fi adirẹsi ile naa ati nọmba foonu ẹnikan lara awọn ọkunrin to sọ pe o hu iwa naa sori ayélujára.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni kiakia si ni ọpọ ọmọ Naijiria lori Twitter ti bẹrẹ si ni i pe fun didoola rẹ.

Ko si pẹ pupọ ti awọn ọlọpaa fi de ile to fi adirẹsi rẹ sita ni adugbo Yaba, lati dóòlà Toyosi.

Àkọlé fídíò, Easter Celebration: Olórí Celestial ní Krìstíẹ́nì kò yẹ kó fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú àjíǹde

Ṣugbọn lẹyin asiko diẹ, Toyosi fi fido kan sita pe alaafia ni oun wa.

"Alaafia ni mo wa, wọn o ji mi gbe tabi fi ipa ba mi lopọ."

Bakan naa lo sọ pe oun ti wa nile oun bayii, ati pe ki awọn eeyan dẹyin ni pipe awọn nọmba ti oun fi sita.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin sọ lori Twitter ni irọlẹ Ọjọbọ pe Toyosi ti fi ẹsẹ ara rẹ rin wa si agọ ọlọpaa.

Toyosi kii ṣe ajeji ninu ile to fi adirẹsi rẹ sita

Agbẹnusọ ọlọpaa, SP Hundeyin sọ pe iwadii ti awọn ṣe lẹkunrẹrẹ fihan pe ẹni ogun ọdun ni Toyosi Adesegun. Ati pe o ma n lọ si ile naa lati ri awọn ọmọkunrin mẹta kan, Olamilekan Faruk, Ayanfe Ayinde ati Olusola Onipede.

Ni owurọ Ọjọbọ, awọn ọmọkunrin naa ko fẹ ko kuro nile wọn, eyi lo mu ki Toyosi dunkooko pe oun yoo fi sori Twitter ti wọn ko ba jẹ ki oun lọ. Nitori naa lo ṣe parọ lori ayélujára pe wọn ji oun gbe, ti wọn tun balopọ pẹlu ipa.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

ASP Hundeyin sọ pe awọn ọmọkunrin naa yoo fojuhan nile ẹjọ, fun ẹsun pe wọn di lọwọ lọna ti ko ba ofin mu.

Bakan naa lo sọ pe Toyosi funra rẹ yoo jẹjọ fun pe o parọ.