Anti Corruption War: Ìjọba bojú àánú wo àwọn gómìnà tẹ́lẹ̀ rí méjì tó ń sẹ̀wọ̀n lọ́wọ́ fẹ́sùn àjẹbánu

Dariye àti Nyame

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àkọlé àwòrán, Dariye àti Nyame

Ìgbìmọ̀ àwọn olórí orílẹ̀eèdè yìí ti bojú àánú wo àwọn ẹlẹ́wọ̀n mọ́kàndínlọ́gọ́jọ.

Lara wọn ni èyí tí àwọn gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Plateau àti Taraba, Joshua Dariye àti Jolly Nyame wà nínú wọn.

Ẹ̀sùn àjẹbánu ni àwọn gómìnà méjéèjì ń ṣe ẹ̀wọ̀n lé lórí.

Ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù kẹrin, níbi ìpàdé ìgbìmọ̀ àwọn olórí orílẹ̀ èdè yìí, èyí tí àwọn Ààrẹ Muhammadu Buhari darí rẹ̀ ni wọ́n ti fẹnukò láti bojú àánú wo àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà.

Gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ Ààrẹ ṣe sọ nítorí ìlera àti ọjọ́ orí ni wọ́n ṣe bojú àánú wo àwọn gómìnà tẹ́lẹ̀ rí méjéèjì.

Kíló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Nyame, ẹni ọdún mẹ́rìndínláàdọ́rin, ló ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Taraba láàárín ọdún 1999 sí ọdún 2007.

O sì ń ṣẹ̀wọ̀n ọdún méjìlá ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje fẹ́sùn ṣíṣe owó ìlú kúmọkùmọ nígbà tó wà nípò.

Nínú oṣù kejì, ọdún 2020 ní ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè yìí fìdìí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé ẹ̀wọ̀n náà tọ́ si.

Àkọlé fídíò, Easter Celebration: Olórí Celestial ní Krìstíẹ́nì kò yẹ kó fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú àjíǹde

Dariye, ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta, tó ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Plateau láàárín ọdún 1999 sí ọdún 2007 náà rí ẹ̀wọ́n he fẹ́sùn pípa bílíọ̀nù méjì náírà tó jẹ́ owó ìlú ní póńpó.

Nígbà tó ń bá sáà rẹ̀ lọ gẹ́gẹ́ aṣòfin tó ń ṣojú ààrin gbùngùn Plateau nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ní Dariye rí ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlá he lọ́dún 2018 ṣùgbọ́n tó parí sáà náà lọ́dún 2019 gẹ́gẹ́ bí.

Ẹ̀wẹ̀ ní ọdún 2021, ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ lábẹ́ ìdarí ìdájọ́ àwọn adájọ́ márùn-ún tí adájọ́ Mary Odili darí dín ẹ̀wọ̀n Dariye kù láti ọdún mẹ́rìnlá sí mẹ́wàá.

Yàtọ̀ sí àwọn gómìnà méjéèjì yìí, adarí iléeṣẹ́ ológun tẹ́lẹ̀ rí tó tún jẹ́ mínísítà lábẹ́ ìjọba ológun Sani Abacha, Tajudeen Olanrewaju, ọ̀gágun Akiyode, Oladipo Jiya àti àwọn ológun kéékèèké tó lọ́wọ́ nínú ìdìtẹ̀gbàjọba ọdún 1990 tí Gideon Orkar ṣaájú rẹ̀ wà lára àwọn tí wọ́n bojú àánú wò.

Àkọlé fídíò, Abisola Odebode: Ẹ wo àkàndá ẹ̀dá tó ń kọ́ àwọn àgùnbánirọ̀ l‘Osun ní ọ̀dà ṣíṣe lọ́fẹ̀ẹ́

Àwọn wo ni ọmọ ìgbìmọ̀ olórí orílẹ̀ èdè?

Ìgbìmọ̀ àwọn olórí orílẹ̀ èdè jẹ́ ẹ̀ka ìjọba Nàìjíríà, tí àwọn gbogbo àwọn tó bá ti jẹ Ààrẹ, olórí orílẹ̀ èdè, àwọn adájọ́ àgbà tẹ́lẹ̀ rí, gbogbo àwọn Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin, gbogbo àwọn gómìnà àti mínísítà fètò ìdájọ́ jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́.

Gẹ́gẹ́ bí ìwé òfin Nàìjíríà ọdún 1999 ṣe làá kalẹ̀, Ààrẹ tó bá wà ní orí oyè ni alága tí igbákejì Ààrẹ sì jẹ́ igbákejì alága.

Ìgbìmọ̀ náà ní agbára láti fún Ààrẹ ní àmọ̀ràn lórí ètò ìkànìyàn, yíyan àwọn ènìyàn sípò ní iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìdìbò, ìgbìmọ̀ ẹ̀ka ètò ìdájọ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.