Rail Transportation: Ẹni tí kò bá ní nọ́mbà ìdánimọ̀ NIN kò le wọ ọkọ̀ ojú irin mọ́- iléeṣé rélùwéè

Ọkọ̀ ojú irin

Oríṣun àwòrán, @NRC

Àkọlé àwòrán, Ọkọ̀ ojú irin

Gbogbo ẹni tó bá fẹ́ wọ ọkọ̀ ojú irin láti fi rin ìrìnàjò gbọ́dọ̀ lọ gba káàdì ìdànimọ̀, kí wọ́n sì ní nọ́mbà NIN nítorí òhun ni wọn yóò máa lò láti fi wọ ọkọ̀ bẹ̀rẹ̀ láti inú oṣù karùn-ún.

Adarí àjọ rélùwéè ní Nàìjíríà, NRC, Fidet Okhiria ní àwọn yóò máa gba NIN àwọn tó bá fẹ́ wọkọ̀ rélùwéè láti inu oṣù karùn-ún lọ lójúnà àti ní àkọ́ọ́lẹ̀ tó péye nípa àwọn èrò.

Okhiria ṣàlàyé wí pé èyí yóò mú àlékún bá ètò ààbò àwọn tó ń wọ ọkọ̀ náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

A ó bẹ̀rẹ̀ nínà Abuja sí Kaduna padà láìpẹ́

Bákan náà ló fi kun wí pé iṣẹ́ àwọn ti ń ṣe ohun gbogbo tó yẹ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ níná Kaduna sí Abuja ní kòpẹ́kòpẹ́.

Bẹ́ẹ̀ náà ló àwọn ti ń pọn kán àtò ààbò fún ọkọ̀ ojú irin àti àwọn tó ń wọ ọkọ̀ náà.

Àkọlé fídíò, Oluyemisi Orisabiyi: Ẹ̀ẹ̀mẹta péré làwọn òṣìṣẹ́ KAI bẹ̀ mí wò, mo kọ̀wé sí wọn lái rí èsì

Lẹ́yìn tí àwọn agbébọn ṣe ìkọlù sí ọkọ̀ rélùwéè ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹta, ọdún 2022 ni àjọ NRC ṣs ìdádúró gbígbé èrò fún ìgbà díẹ̀ ná.

Nínú ìkọlù ọ̀hún ni àwọn agbébọn ti ṣekúpa àwọn ènìyàn tí wọ́n sì tún jí ọ̀pọ̀ èrò gbé lọ.

Okhiria tẹ̀síwájú wí pé àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti yọ àwọn tí agbébọn náà jígbé ní ìgbèkùn láìpẹ́.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Gbẹ̀fẹ́ ní àkókò tí mo lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, àìrì aya mi nìkan ní ìyàtọ̀

Gbogbo ẹni tó bá ṣì ń wá ènìyàn kí wọ́n kàn sí wa

Okhiria wá rọ gbogbo àwọn tó bá ní ènìyàn nínú ọkọ̀ ojú irin tí àwọn agbébọn náà ṣe ìkọlù sí, tí wọn kò sì tíì rí ènìyàn láti kàn sí ilé iṣẹ́ réelùwéè.

Ó ní kí wọ́n pe àwọn nọ́mbà wọ̀nyìí 08033546208, 08060044600, 07066700150.

Bákan náà ló ní àwọn yóò máa fi gbogbo bí ètò bá dé lórí ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ará ìlú létí.

Ó ní ọkọ̀ tí àwọn agbébọn náà bàjẹ́ ni àwọn ti tún ṣe padà.