Sokoto Canoe Mishap: Baálẹ̀ abúlé pàdánù ọmọ 5 sínú ìjàmbá ọkọ̀ oju omi tó mú ẹ̀mí 28 lọ

Ọkọ oju omi to danu

Oríṣun àwòrán, Reuters

Kò dín ní ènìyàn méjìdínlọ́gbọ̀n tó pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàmbá ọkọ̀ oju omi ní ìlú Gidan-Magana, ìjọba ìbílẹ̀ Shagari, ìpínlẹ̀ Sokoto.

Baálẹ̀ ìlú Gidan-Magana, Mohammed Auwalu ní lọ́jọ́rú, ọjọ́ kẹtàlá, oṣù kẹrin, ọdún 2022 ni ọkọ̀ ojú omi náà rì nígbà tó ń gbèrò láti sọdá sí ìlú òdìkejì tó ń jẹ́ Badiyawa.

Auwalu ní ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi náà wáyé nígbà tí ọkọ̀ ọ̀hún forí sọ igi kan nínú omi tó sì dànù.

Ènìyàn mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ló wà nínú ọkọ̀ náà èyí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn jẹ́ obìnrin àti ọmọdé.

Ó ṣàlàyé pé ènìyàn mẹ́fà ni wọ́n rí yọ láàyè tó sì jẹ́ wí pé òkú àwọn méjìdínlọ́gbọ̀n yòókù ni wọ́n rí yọ nínú omi náà.

Auwalu ní ọmọ òun márùn-ún ló wà nínú àwọn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà lọ.

Bákan náà ló ṣàlàyé wí pé àwọn ti sin àwọn tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn.

Àkọlé fídíò, Female Carpenter: Fatia Garu ní ọ̀pọ̀ èèyàn ni kìí gbàgbọ́ pé obìnrin ló ń ṣiṣẹ́ Káfíńtà