Teenage Armed Robbers: Àwọn ọ̀dọ́ adigunjalè ní gbogbo nǹkán táwọn bá jí gbé, àwọn ìyá àwọn làwọn ń ko fún

Oríṣun àwòrán, Amotekun Ondo
Ìkọ alaabo Amọtẹkun n'ipinlẹ Ondo ti kede pe àwọn ri afurasi ọdaràn mọkandinlogun mu kaakiri ipinlẹ naa.
Ninu awọn afurasi ti ọwọ tẹ yi ni ọdọkunrin meji kan wa, Timilehin ẹni ọdún méjìlá ati Sunday ẹni ọdun mẹrindinlogun.
Inagijẹ Timilehin a máa jẹ Anini nigba ti wọn sì n pe Sunday ni apejẹ Oyewusi.
Bakan naa ni ọwọ Amotekun tun tẹ afurasi ọdọ mii ti o jẹ ẹni ogun ọdun, ti orukọ rẹ n jẹ Odeyemi Ayodele, ti wọn tun n pe ni Osunbo
Bi a ko ba gbagbe inagijẹ wọn yií jẹ orúkọ awọn ogbologbo adigunjale tí ìjọba fẹyin wọn ti agba lasiko ìjọba ologun.
- Wo ìtàn ayé gbajúmọ̀ adigunjalè méje nílẹ̀ Yorùbá tí ìjọba dá sẹ̀ríà fún
- Ìtàn ayé Shina Rambo, adigunjalè tó fi ahọ́n èèyàn 100 mu ẹ̀kọ́, fi oyún 27 gún ọṣẹ
- Adigunjalè kọlu Kemi Afolabi, wọ́n fi àdá ṣá òun àti awakọ̀ rẹ̀
- Àwọn ọlọ́ṣà sùn lọ nínú ọkọ̀ tí wọ́n jí, lọ́wọ́ agbófinró bá tẹ̀ wọ́n
- Ọwọ́ sìkún ọlọ́pàá tẹ Bolanle afurasí adigunjalè làyájọ́ òmìnira Nàìjíríà
- 'Pẹ̀lú ìbànújẹ́ lá fi sìn ọkọ, ẹ̀gbọ́n àti alájọṣiṣẹ́pọ̀ Dauda, ọlọ́pàá tó bá ìdigunjalè Iree lọ'
- Ojú ẹni t'ọlọ́pàá ló wà lẹ́yìn ìdigunjalẹ̀ Báńkì Abuja rèé
Ni adugbo Ijare to wa ni ijọba ibilẹ Ifedore ni ipinlẹ Ondo, ni ọwọ ti tẹ Timilehin, Sunday ati Ayodele lori ẹsun idigunjale.
Lasiko to n se afihan awọn afurasi yi, ọgá Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ni awọn mẹta wọn yi jẹ ogbologbo ninu idigunjale.
Bawo ni ọwọ se tọ Oyenusi, Anini ati Osunbo:
Asaaju Amotekun ni Ondo salaye pe ọwọ tun tẹ awọn afurasi mẹrindinlogun miran lori ẹsun bi ifipabanilopo, ijinigbe, olè jija ati fifi ẹran jẹ n'ita lọnà aitọ.
Adeyeye ni " Ṣé ẹ ri ọkan ninu awọn ọdọkunrin yii, Oyenusi, l'ọdun to kọja ni wọn mú ti wọn sì gbé lọ si ibùdó iyipada.
Amọ nitori ọjọ ori rẹ to kere ,wọn padà fi sílẹ"
Wọn mu iya rẹ naa nitori o jẹwọ fún wa pé ìyá rẹ lo máa mú oogun wa, ki ọwọ ma ba a lè tẹ oun ati ki awọn agbofinro ma le rii mu.
Iya yii naa maa n bawon pin ninu nkan ti won ba ji gbé"
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí lò fa ariwo pe Wasiu Ayinde kó kúrò nílé fún Ropo, aya rẹ̀ torí pé obìnrin náà fọ léti torí obinrin miran?
- Ooni Ilé Ife, Adeyeye Ogunwusi ti bí ọmọ míràn?
- Òṣìṣẹ́ INEC kàn ku méjì, dì àwáti bí agbébọn ṣe kọlù ibùdó iforukọsilẹ
- Seyi Makinde ti sọ Auxillary di nǹkan míì sígbòrò, ọlọ́pàá gbọdọ̀ mu - Olopoeyan
- Wo ẹ̀rọ ìgbàlódé tí o lé rì sínú ọwọ́ rẹ̀ láti má a san owó ọ̀jà láì lo káàdì ATM
- Ó ṣe! Baálẹ̀ abúlé pàdánù ọmọ 5 sínú ìjàmbá ọkọ̀ oju omi tó mú ẹ̀mí 28 lọ
- Ẹni tí kò bá ní nọ́mbà ìdánimọ̀ NIN kò le wọ ọkọ̀ ojú irin mọ́- iléeṣé rélùwéè
- Àwọn afurasí mẹ́rìndínlógún kó sí àhámọ́ EFCC fẹ́sùn jìbìtì lórí ayélujára
- Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn, obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò jẹ́ Aláàfin, ẹni tó pààrọ̀ nǹkan obìnrin sí ti ọkùnrin
- A rí àwọn fọ́tò tó fihàn pé ọkọ Osinachi ní ìyàwó míràn sí ìkọ̀kọ̀ - Mínísítà fọ́rọ̀ obìnrin
Olori ikọ Amotekun wa tẹsiwaju pe lọtẹ yii, awọn yóò kọ ìwé sí ẹka eto idajo lori ohun tó yẹ kawọn ṣe.
Sugbon o ni lórí àwọn ìyá tó n gbe lẹhin wọn" a máa pe wọn lẹjọ ni"
Ninu awọn nkan ti wọn rí gba lọwọ awọn afurasi yii ni ibọn, ọta, foonu ati owo.
Adeyeye sọ pé àwọn afurasí yii ti jẹwọ, ti wọn yóò sì kó wọn lọ sile ẹjọ laipẹ.
Oyelusi lo kọ ọmọ mi ni ikọkukọ:
Nigba to n ba àwọn akọroyin sọrọ iya Timilehin, Iyabo sọ pé Sunday ti inagijẹ rẹ n jẹ Oyenusi lo kọ ọmọ oun ni ikọkukọ.
"Mi o ṣe asejẹ kankan fún. Mo kan mu lọ sí ilé ìjósìn nibi ti pasitọ ti fún mi ni ọsẹ.
Mo gbe lọ si odo nibi ti mo lọ bá wẹ ẹmi idigunjale kuro lara rẹ ni"
Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Ondo ti ṣe iranwọ ẹbùn alupupu ọgbọn fún ileesẹ alaabo Amọtẹkun.
Lasiko to n fesi lori ẹbùn yi ọgá ìkọ Amọtẹkun sọ pe iranlọwọ yi yóò fún ọ jẹ ki awọn le koju iwa ọdaran ati lati le fi daabo bo araalu bo ṣe yẹ.

Àwọn afurasí mẹ́rìndínlógún kó sí àhámọ́ EFCC fẹ́sùn jìbìtì lórí ayélujára

Oríṣun àwòrán, EFCC
Àjọ tó ń gbógun ti ìwà àjẹbánu ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà, EFCC, tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Enugu ní àwọn ti fi páńpẹ́ òfin gbé àwọn afurasí kan.
Awon naa ni ọ́wọ́ tẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oníjìbìtì orí ayélujára mẹ́rìndínlógún ní agbègbè Monarch, New Haven Extension àti ilé ìtura Castle Majestic tó wà ní òpópónà Ogui.
Àtẹ̀jáde tó wà ní orí ayélujára àjọ EFCC ní ọwọ́ tẹ àwọn afurasí náà lẹ́yìn tí ìwádìí ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé àwọn afurasí náà lọ́wọ́ nínú lílu àwọn ènìyàn ní jìbìtì lórí ayélujára.
Àtẹ̀jáde ọ̀hún tó jáde láti ẹ̀ka ìròyìn EFCC ní ìwádìí àwọn ló fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé ní ilé ìtura Castle Majestic ni àwọn afurasí náà ti ń hu ìwà láabi wọn èyí ló sì mú àwọn lọ gbọn ilé ìtura náà yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́.
- Seyi Makinde ti sọ Auxillary di nǹkan míì sígbòrò, ọlọ́pàá gbọdọ̀ mu - Olopoeyan
- Wo ẹ̀rọ ìgbàlódé tí o lé rì sínú ọwọ́ rẹ̀ láti má a san owó ọ̀jà láì lo káàdì ATM
- Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn, obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò jẹ́ Aláàfin, ẹni tó pààrọ̀ nǹkan obìnrin sí ti ọkùnrin
- Wo ìdí mẹ́ta tí káàdì ìdìbò rẹ̀ kò fi ní wúlò mọ́
- Ìkọlù sí Ukraine kò ní dópin àyàfi tó bá ṣe ohun tí mo fẹ́ - Putin
- Àṣírí ayédèrú ológun méjìlá tó ń gbégi dínà ní Ajah ati agbègbè míì tú sọ́wọ́ iléeṣẹ́ ológun
- A rí àwọn fọ́tò tó fihàn pé ọkọ Osinachi ní ìyàwó míràn sí ìkọ̀kọ̀ - Mínísítà fọ́rọ̀ obìnrin
- Ọwọ́ àwọn ológun kò mọ́ lórí ìkọlù agbébọn ní Nàìjíríà - Àwọn aṣòfin àpapọ̀ fọnmú
Àwọn afurasí parọ́ wí pé akẹ́kọ̀ọ́ ni àwọn
Ó fi kun wí pé nígbà tí àwọn yóò fi de ilé ìtura náà ní àwọn bá àwọn afurasí ọ̀hún tí wọ́n pe ara wọn ní ọmọ ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ Nàìjíríà, NANS àti ọmọ ẹgbẹ́ Ohaneze Ndigbo.
Wọ́n ní àwọn adarí ẹgbẹ́ NANS àti Ohaneze Ndigbo lóòótọ́ nawọ́ sí àwọn tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ wọn kí àwọn tó kó àwọn tó jẹ́ kàǹda nínú ìrẹ̀sì.
Àwọn afurasí tí wọ́n nawọ́ gán ni Agbo Paschal, Anthony Ogbu Uzochukwu, Ejiofor, Uchenna Ejiofor Chikora, Ezihe Victor, Nnaji Onyedikachi Christian, Eke Ike, Ogbodo Arinze, Ogbodo Ebube, Ogbu Chinedu, Ossai Chinedu àti Udey Ifeanyi.
Lára àwọn ohun tí wọ́n rí gbà lọ́wọ́ àwọn afurasí náà ni ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Lexus ES 350, ìwé ètò ìrìnnà, fóònù, ẹ̀rọ kọ̀mpútà alágbèká àti àwọn nǹkan míìràn.
EFCC ní ni kété tí àwọn bá ti parí ìwádìí ní àwọn yóò gbé àwọn afurasí náà lọ sí ilé ẹjọ́.
- Èmi ni mo kájúẹ láti di Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà – Tinubu
- Ṣe lóòótọ́ ni pé Osinbajo kìí se ọmọ ẹgbẹ́ APC l‘Eko?
- Erin kọlu Amaya Sebastian, àgbà ọ̀jẹ́ ọjọ́gbọ́n nínú isẹ́ ìwádìí kan, ikú ló padà já sí
- ''Àti ọmọ ọdún mẹ́fà ni mo tí ń fa Cocaine, bí mo ṣe fipá bá Tosin lòpọ̀ rè é, tí mo sì pa á''
- Ìwúlò Buhari fún Nàíjíríà tí tán, kò búrú tó bá kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ - Ilana Omo Oodua





















