Kwam 1: BBC Yoruba tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ tó ń jà nílẹ̀ pé ààrin Wasiu Ayinde àti aya rẹ̀ tuntun, Ropo ti dàrú

Oríṣun àwòrán, kunlerasheed/Instagram
Lẹnu bii ọjọ melo kan ni iroyin gba ori ayelujara pe gọngọ ti sọ laarin Mayegun ilẹ Yoruba, Oloye Wasiu Ayinde Anifowose Marshal, ti ọpọ eeyan mọ si Kwam 1 ati aya rẹ tuntun, Ropo Emmanuella, ti ọpọ eeyan n pe ni Ọkin.
Oniruuru awọn iroyin lo ti gbe isẹlẹ naa lori ayelujara, ti awọn eeyan si n gba isẹlẹ naa wo, bii ẹni gba igba ọti.
Amọ ọna lati tan imọlẹ si iroyin yii, ka lee wadi ohun gbogbo daju nipa isẹlẹ naa lo mu ki BBC Yoruba se iwadii kinni kinni nipa awọn ọrọ to n jade naa.
- Lẹ́yìn Titi Masha, Kwam 1 gbé ìyàwó tuntun, Emmanuella Ropo l'Abeokuta, bó ṣe lọ rèé
- Taa ni arẹ̀wà obìnrin, Emmanuella Ropo tí ìròyìn n sọ pé òun ni ìyàwò K1 tuntun?
- Wo ipa tí Mayegun yóò ma kó ní ilẹ̀ Yoruba!
- Aláàfin Ọyọ: Ọba tó bá n mú ọtí ní ìta kò yẹ ní ẹni tàá bọ̀wọ̀ fún
- Ìjà pari, FIBAN ati KWAM 1 parí aáwọ̀
- Lẹ́yìn ò rẹyìn, Wasiu Ayinde sọ̀rọ̀ nípa Ayinde Barrister
- Kwam 1 dá àwọn tó ń wọ́ ọ tuurutu nílẹ̀ pé ó jẹ́ gbèsè dollar iṣẹ́ orin kan l'Amẹ́rika
- Ṣé lóòtọ́ ni ìjà ti parí láàrin ìdílé Ayinde Barrister àti Kwam 1?
Yoruba sa ni ọrọ okeere, bi ko ba le ọkan, yoo din ọkan, yọyọ si ni ẹnu ọmọ araye.
Ki ni awọn eeyan n sọ pe o fa aawọ laarin Kwam 1 ati aya rẹ, Ropo?
Iwadii BBC Yoruba tanna wadi hulẹhulẹ ọrọ naa bi o tilẹ pe awọn tọkọtaya ti isẹlẹ naa kan ko ti sọrọ sita nipa ohun tawọn eeyan n sọ pe o waye laarin wọn.
Amọ gẹgẹ bi awọn iwe iroyin ori ayelujara ti wi pẹlu gbajumọ sọrọsọrọ lori itakun agbaye, ESABOD, asemase lo fa sabai isẹlẹ naa.
Gẹgẹ bi ESABOD ti salaye, o ni iroyin ti jade pe Wasiu Ayinde n ni ifẹ ikọkọ pẹlu amugbalẹgbẹ rẹ kan to jẹ obinrin.
O ni akoko ti ọba akọrin Fuji naa n ba obinrin amugbalẹgbẹ rẹ naa lopọ ni iyawo rẹ tuntun, Ropo, ka awọn mejeeji mọ ori ara wọn.
Esabod ni idi ree ti Ropo se gba Wasiu Ayinde leti lati fi han pe ohun to se, ko dara.
Gbajumọ sọrọsọrọ naa ni oun gbọ pe Kwam 1 ti ko kuro nitori isẹlẹ naa, to si dabi ẹnipe aarin awọn tọkọtaya naa ti daru.
Bakan naa lo gba Mayegun ilẹ Yoruba naa nimọran lati sọrase nipa ọrọ olobinrinde nitori ewu wa nibẹ.
Bakan naa ni iroyin miran sọ pe Ropo lọ soju agbo kan ti Wasiu Ayinde ti n sere lode ariya lati da wahala silẹ nibẹ.
Irọ to jinna sootọ ni pe Ropo fọ Kwam 1 leti, aarin wọn ko si daru - Agbẹnusọ Kwam I
Amọ niwọn igba to jẹ pe isọrọ ni igbesi, mayegun ilẹ Yoruba naa ti wa fesi si oniruuru ahesọ ọrọ to n jade nipa rẹ naa.
Agbẹnusọ fun Wasiu Ayinde, Kunle Rasheed, to n gba ẹnu ọga rẹ sọrọ, ti fi ikede kan sita loju opo Instagram rẹ lọjọbọ lori ọrọ to n tan kaakiri naa.
Ikede ọhun ni lootọ ni ọpọ ahesọ iroyin nipa aawọ ti wọn lo n waye laarin Kwam 1 ati aya rẹ ti de si etigbọ awọn, amọ o ni ọrọ naa ko ri bẹẹ.
Atẹjade naa ni "ko si igba kankan ti Mayegun ati aya rẹ, Ropo ja debi pe Ropo n gba ọkọ rẹ naa leti."

Oríṣun àwòrán, kunlerasheed/Instagram
Iroyin naa ba wa lojiji, to si ya wa lẹnu, a ko si lee fi ọwọ yẹpẹrẹ mu iroyin naa rara.
Atẹjade naa wa salaye pe ioyin naa ba wa lojiji, to si ya wa lẹnu, a ko si lee fi ọwọ yẹpẹrẹ mu iroyin naa rara.
"Emmanuella Ropo aya Wasiu Ayinde n se ojuse rẹ bo se tọ, ati bo se yẹ gẹgẹ bi iyawo ile, ti ko si raye pe ko maa tẹle ọkọ rẹ kiri agbo ariya kiri."
Bakan naa ni atẹjade ọhun yan pe ariya kan soso ti tọkọtaya naa dijọ lọ papọ laipẹ yii ni ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọta ọdun eekanlu kan to waye ni agbegbe Ikeja.
Atẹjade naa wa n fi ọwọ gbaya pe ahesọ ọrọ pọnbele ni iroyin pe aarin Kwam 1 ati Ropo ti daru, ko si si ootọ ọrọ kankan ninu rẹ.
Bakan naa ni igun Mayegun wa n kọminu pe o se ni laanu pe akoko ti aawẹ Ramadan n lọ lọwọ ni wọn n gbe irufẹ iroyin ẹlẹjẹ bayii kiri.
O wa rọ awọn eeyan to n sisẹ gbọyi sọyi naa lati ronupiwada, ki wọn si wa oju rere lọrun.



















