"Wasiu Ayinde fi bàtà tẹ̀ mí lórí àti imú mọ́lẹ̀, ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbá mi létí"

Àkọlé fọ́nrán ohùn, "Wasiu Ayinde fi bàtà tẹ̀ mí lórí àti imú mọ́lẹ̀, ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbá mi létí"

Ni owurọ ọjọ Abamẹta ni ariwo gba ilẹ kan pe, ilumọọka akọrin Fuji ati Mayegun ilẹ Yoruba, Wasiu Ayinde Mashall, ti ọpọ eeyan mọ si Kwam 1, gba gbajumọ agbohunsafẹfẹ kan leti loju agbo.

Orukọ ilumọọka agbohunsafẹfẹ naa ni wọn pe ni Wole Sorunke, ti ọpọ eeyan mọ si MC Murphy, ẹni tii se oludari eto gbogbo nileesẹ radio Fresh FM to wa nilu Abeokuta.

Gẹgẹ bi iroyin naa se wi, nibi ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọta ọdun Olu tilu Itori, Ọba Abdulfatai Akorede Akamọ ni isẹlẹ naa ti waye, lasiko ti wọn pe Kwam 1, ko wa kọrin nibẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: