INEC Voters Registration in Imo: Wo aburú tàwọn agbébọn ṣé ní Ihitte Uboma

Oríṣun àwòrán, Screen shot
Awọn janduku agbebọn to n da họwu họwu silẹ ni ilẹ Igbo lorilede Naijiria ti pa oṣiṣẹ àjọ eleto idibo INEC kan ni ilu Ihitte ni ijọba ibilẹ Uboma ni Imo.
Arakunrin kan to orukọ rẹ n je Nwokorie Anthony, oṣiṣẹ INEC ni awọn agbebọn yi seku pa gẹgẹ bí àjọ naa ṣe wi.
Ileesẹ olopaa Imo kontinfesi sí ọrọ yi amọ INEC ni awọn ti so iṣẹ rọ níbẹ fún ìgbà yi naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí lò fa ariwo pe Wasiu Ayinde kó kúrò nílé fún Ropo, aya rẹ̀ torí pé obìnrin náà fọ léti torí obinrin miran?
- Ooni Ilé Ife, Adeyeye Ogunwusi ti bí ọmọ míràn?
- Seyi Makinde ti sọ Auxillary di nǹkan míì sígbòrò, ọlọ́pàá gbọdọ̀ mu - Olopoeyan
- Wo ẹ̀rọ ìgbàlódé tí o lé rì sínú ọwọ́ rẹ̀ láti má a san owó ọ̀jà láì lo káàdì ATM
- Ó ṣe! Baálẹ̀ abúlé pàdánù ọmọ 5 sínú ìjàmbá ọkọ̀ oju omi tó mú ẹ̀mí 28 lọ
- Ẹni tí kò bá ní nọ́mbà ìdánimọ̀ NIN kò le wọ ọkọ̀ ojú irin mọ́- iléeṣé rélùwéè
- Àwọn afurasí mẹ́rìndínlógún kó sí àhámọ́ EFCC fẹ́sùn jìbìtì lórí ayélujára
- Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn, obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò jẹ́ Aláàfin, ẹni tó pààrọ̀ nǹkan obìnrin sí ti ọkùnrin
- A rí àwọn fọ́tò tó fihàn pé ọkọ Osinachi ní ìyàwó míràn sí ìkọ̀kọ̀ - Mínísítà fọ́rọ̀ obìnrin
INEC sí ti kéde idaduro iṣẹ lẹyin ikọlu to waye ni ọfisi wọn tó wà ni Anambra, Enugu ati Imo.
Ki lo ṣẹlẹ gaan ni Ihitte:
Fónrán fidio kan tó gbòde la ti ri tàwọn afurasi ọmọ ikọ Ipob ti n da ọfisi iforukọsilẹ àjọ eleto idibo INEC ru.
INEC ni iṣẹlẹ yi waye ni ibùdó iforukọsilẹ igbadegba awọn kan to n lọ lọwọ bayi.
Wọn sọ pé ni ibùdó idibo "Nkwo Ihitte (PU 004) to wa ni wọọdu Amakohia Ward (RA 02) to wa ni ijọba ibilẹ Ihitte Uboma lo yi ṣẹlẹ.
Fidio naa ti ọkan ninu awọn agbebọn yi ya ṣafihan bí wọn ṣe n da eto to n lọ lọwọ ru.
Wọn ní k'awọn eeyan daya delẹ to fi mọ awọn obìnrin ati ọmọde.
Bẹẹ sì ni ẹni tó n ya fidio naa n pariwo:
"ki lo ṣe ti ẹ kii gbọ ọrọ.A sọ fún yín pé idibo ko ni waye ti ẹ sí n forukọ awọn èèyàn sílẹ?"
"Ki ẹ bàa lè ní ominira la fi n já ṣugbọn ẹ kii gb'ọrọ"
Awọn agbebọn to kù sì bẹrẹ sí ní yin ibọn bi wọn ṣe n ya fidio ọhun.
A rí bí wọn ṣe yìnbọn lú awọn eeyan kan to dubulẹ.
Ọkan ninu awọn ti wọn yin nibọn yi jẹ oṣiṣẹ àjọ INEC, Nwokorie Anthony.
A tun ri awọn ti ẹjẹ wa lara wọn ninu fidio yi.A ko ri aridaju iye eeyan ti wọn yìnbọn lu.

Ki lajọ INEC sọ:
Festus Okoye, to jẹ oludari ipolongo INEC sọ pe iroyin iṣẹlẹ naa tẹ awọn lọwọ ni Ọjọbọ.
O ni "INEC Ti wọgile eto iforukọsilẹ to n waye nilu Ihitte ni ijoba ibilẹ Uboma ni ipinlẹ Imo "
Okoye sọ pé yatọ sí oṣiṣẹ awọn ti wọn yìnbọn pá, awọn si n wa oṣiṣẹ meji miiran.
Oga àjọ naa ni agbegbe ọhun(REC) ọjọgbọn Emeka Ezeonu ni ọfisi INEC ni ipinlẹ naa n sapa lati ṣawari awọn oṣiṣẹ meji to farakasa iṣẹlẹ naa.
Ipob ati awọn 'unknown gunmen' ni ilẹ Igbo ko ṣẹṣẹ máa ṣe ọsẹ
Ìjọba Naijiria to fòfin de ikọ IPob leyin tí wọn kéde wọn gẹgẹ bí agbesunmọmi nitori b'awọn agbebọn ṣe n daamu alaafia ilu lagbegbe naa.
Ikọ náà tí ọpọ a máa juwe bi agbebọn ti wọn kò mọ ti da wàhálà ti kii se5 kekere silẹ paapa laarin ọdun 2020 sí 2021.
Wọn n tẹsiwaju pẹlu ikọlù wọn ní ọdun 2022.
Ìkọ naa sọ pe awon n já fún iyasọtọ ilẹ Igbo kuro lara Naijiria ni.
Ni oṣù kọkànlá 2021 wọn fi ìkìlọ sita pe idibo Gomina ni ipinlẹ Anambra ko ni waye.
Nise ni ijọba Naijiria ko àwọn ọmọ ogun lọ síbẹ láti dáàbò bo àwọn oludibo ki ibo naa to waye.
2023 ti n bọ lọnà ti Naijira sì fẹ ṣe idibo mii.
Ipob ti sọ ninu fidio pe awon ko fẹ idibo kankan ni agbegbe awọn.


















