Orlando Julius: Tunde Kelani ní orin olóògbé náà ní òun fi parí sinimá tuntun tí òun ṣe

Tunde Kelani ati Orlando Julius

Oríṣun àwòrán, others

Agba onkọtan sinima, Tunde Kelani ti ṣapejuwe iku oloogbe Orlando Julius gẹgẹ bii nkan to dun oun pupọ.

Kelani salaye pe bii ẹgbọn ni Orlando jẹ fun oun.

Ninu ọrọ to ba BBC sọ lori iku oloogbe, Kelani sọ pe nkan to dun oun nipa iku rẹ ni pe ko duro ri iṣẹ ribiribi ti oun ṣe lori igbelarugẹ orin rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kelani ṣalaye pe "nkan to dun mi nigba ti mo gbọ iku rẹ ni pe fiimu kan ti mo ṣẹṣẹ n pari, orin rẹ Ololufẹ ni a fi pari rẹ

"Emi ati fasiti ilu Delaware ni America la jọ sowọpọ lori iṣẹ naa, debi pe ẹgbẹ akọrin fasiti naa, lo lu awọn oun elo orin si atunṣe orin Orlando.

"Ṣugbọn, iku ko jẹ ko duro gbọ orin naa lati ri ibi giga ti a gbe orin rẹ de."

Àkọlé fídíò, Ṣé ẹ rántí orin - Má ṣe jẹ́jẹ́ ma wà mi lọ?

Wo ìtàn ayé Orlando Julius, akọrin Highlife tó papòdà l'Ọ́jọ́bọ

Gbajugbaja akọrin Highlife nni, Orlando Julius ti dagbere faye pe o digbose.

Julius, tii se ẹni ọdun mọkandinlọgọrin lo tẹri gbasọ ni ọjọbọ, ọjọ Kẹrinla osu kẹrin ọdun 2022.

Mọlẹbi kan si oloogbe naa ti ko fẹ ka darukọ oun lo fi idi iroyin iku oloogbe naa mulẹ fun BBC Yoruba.

Orlando Julius jẹ ọmọbibi ilu Ijebu-jesa nipinlẹ Osun, to si jẹ gbajumọ akọrin lasiko to wa loju ọpọn.

Amin iyasọtọ kan

Ta ni Orlando Julius?

Ọdun 1943 ni wọn bi Julius nilu Ikole, ti baba rẹ si jẹ onisowo plu awọn oyinbo.

Iya Julius si lo kọ ni orin kikọ eyi to mu ko nifẹ lati maa kọrin, to si wa ninu ẹgbẹ akọrin fun ileẹkọ rẹ lọdun 1957.

Iku baba oloogbe naa lo mu ko kuro nileẹkọ lairotẹlẹ, to si gba ilu Ibadan wa lati yan isẹ orin kikọ laayo.

Ilu Ibadan si lo ti dara pọ awọn ẹgbẹ akọrin juju lorisirisi bii Rex Williams, Jazz Romero ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Orlando Julius

Oríṣun àwòrán, Orlando Julius Facebook

Tori mi ni Fela Anikulapo fi nifẹ lati maa fọn Saxophone - Orlando Julius

Ọdun 1960 ni Orlando Julius dara pọ mọ ẹgbẹ akọrin Eddy Okonta to gbajumọ bii isana ẹlẹẹta lasiko naa, ti wọn si dijọ gbe ọpọ awo orin jade nigba naa.

Julius lati ipasẹ ileesẹ wa BBC, gbe awo orin akọkọ rẹ jade eyi to pe akọle rẹ ni Igbeyin Adara ldun 1960 yii kanna.

Gẹgẹ bi oju opo Wikipedia ti salaye, Orlando Junius maa n sere orin ni ile itura Independence nilu Ibadan nibi ti oloogbe Fela Anikulapo Kuti maa n duro si pẹlu.

Orlando maa n gba Fela laaye lati goke wa kọrin pẹlu rẹ, to si ni nitori toun ni Fela fi kọ baa ti n fọn Saxophone.

Amọ awo orin to gbajugbaja julọ, to gbe Orlando Julius jade fun araye ri ni awo orin to pe ni Jaguar Nana, to gbe sita ldun 1965.

Bi awo orin naa si se jẹ itẹwọgba, ni Orlando atawọn ẹgbẹ akọrin rẹ bẹrẹ irinajo orin yika iwọ oorun ilẹ adulawọ, eyi to mu ki irufẹ orin to n kọ tubọ jẹ itẹwọgba..

Lẹyin ogun abẹle Naijiria to pari lọdun 1970, akoba nla ni ogun naa se fun isẹ orin kikọ, eyi to ko irẹwẹsi ba Julius.

Eyi si lo mu ki akọrin juju naa morile ilẹ Yuroopu lati wa isẹ aje lọ amọ ko p to tun fi gba ilẹ Amẹrika lọ lọdun 1973, nibi to papa tẹdo si.

A si le se apejuwe Orlando Julius bii akọrin to jẹ ilumọọka kaakiri agbaye nitori bo se gbajumọ ni Naijiria, lo jẹ isana ẹlẹẹta ni Europe ati Amrika.

A wa n gbadura pe ki Ọlọrun tẹ si afẹfẹ rere.

Àkọlé fídíò, Easter Celebration: Olórí Celestial ní Krìstíẹ́nì kò yẹ kó fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú àjíǹde